Thunder strike on Jaipur tower: Bí àrá ṣe sán pa èèyan 16 tó ń ya "Selfie" rèé

Oríṣun àwòrán, NurPhoto
Ara nla to lagbara ti ko sẹni to mọ ibi to ti wọ́ wa ti san pa awọn ọpọlọpọ eeyan ni ilu Jaipur lọjọ isinmi ọsẹ
Awọn to fo ṣanlẹ ku yii korajọ lati ya fọto ara wọn ti oloyinbo n pe ni "Selfie" lode oni eyo to tumọ si wipe ki eeyan kọ oju foonu sira eeyan lati ya a.
Pabanbari ni pe inu ojo ni wọn yan lati ya selfie naa koda wọn tun ko ara wọn jọ lori oke tente ile gogoro kan to jẹ ibi igbafẹ pataki ni Jaipur, orilede India.
Bakan naa ni iroyin tun kan ọpọ awọn mii naa ku lasiko ti ara san ni ipinlẹ Uttar Pradesh ati Madhya Pradesh.
Eeyan to to ẹgbrun meji ni itan sọ pe ara maa n san pa ni India lọdọọdun gẹgẹ bu akọsilẹ.
Ọga Ọlọpaa kan sọ fun awọn oniroyin pe ọpọ ninu awọn to ku lori oke tente ile iṣọ giga naa lo jẹ ọdọ.
Awọn mẹtadinlọgbọn lo kora wọn jọ sori oke ile ọhun nigba ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ ti iroyin si ni awọn kan dede fo bọ silẹ latoke giga nigba ti wọn gburo ara.
Ni ipinlẹ Uttar Pradesh, iroyin o kere tan eeyan mọkanlelogoji ti ọpọ wọn jẹ obinrin ati ọmọde lo fo ṣanlẹ ku tori ara to san.
Jẹjẹ lawọn ọkunrin meji kan n gbatẹgun lab igi kan, loju ẹsẹ ni wọn ku nigba ti ara naa kọ ṣàrà ni ilu Firozabad. Awọn mii naa ku lawọn igun ilu naa mii.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn akọṣẹmọṣẹ ni idi ti iye awn to ku ṣe pọju ni ipinlẹ mejeji ni pe ọpọ eeyan nib lo n ṣiṣẹ nita yala ni ẹka ọgbin tabi awọn to n kọ ile.
Minisita agba ti kede owo gba ma binu fun awọn idile to ni eeyan lara awọn to ku.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Wọ́n o wa tii ri nkankan ni India ni ti ojo rirọ tori pe igba ti ojo maa n ṣe hii hii ju ni laarin oṣu kẹfa si ikẹsan eyi ti ko si tii kasẹ nilẹ.
Akọsilẹ ni iha ipinlẹ southern state of Andhra Pradesh fihan pe ara 36,749 lo lee san laarin wakati mẹtala.
Awọn akọṣẹmọṣẹ si ni o maa n wọpọ lawọn agbegbe ti ewe ibora igi wọn ko nipọ eyi to si n ṣi awọn eniyan si ewu ki ara maa san pa wọn.
Ki ni o le sare ṣe lasiko ti ara ba n san?
- Wa abo ninu ile nla kan tabi inu ọkọ
- Sa kuro lawọn ibi to ṣe gbawuya to ṣi silẹ
- Bi o ko ba ribi sa pamọ si, sọ ara di kukuru patapata ti yoo kere to bẹẹ bi ohun ti ko ṣee ri daadaa boya nipa bibẹrẹ, pipa ẹsẹ rẹ mejeeji pọ, ọwọ rẹ mejeji lori orokun rẹ ki o si ki ori rẹ rẹ bọnu.
- Ma ṣe sa pamọ si abẹ igi giga gogoro tabi igi to da duro sibi kan.
- Too ba wa lori omi, wa ọna lọ si ebute nibi to ṣe gbangba kiakia
- 'Ẹ wòó, ẹ máa retí ìdájọ́ àwọn olùwọ́de Yoruba Nation 49 tó wà láhàmọ́ Ọlọ́pàá ní ọjọ́ ...'
- Wo "ẹ̀lẹ̀ super" tí Balogun Super Eagles, Ahmed Musa fẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìyàwó kẹta
- Ẹ fọkàn balẹ̀, Wakili ò gbèrò láti ṣe ìkọlù sí Igangan àti Ibarapa lọ́jọ́ Ileya- Ọ̀gá ọlọ́pàá Oyo
- Wo ìlú kan ní Italy tó ṣetán láti fún ọ ní N13.6 mílíọ̀nù tí o bá gbà láti gbé níbẹ̀















