Oyo insecurity: Ọ̀gá ọlọ́pàá Oyo ní kò sí ohun tó jọ pé Wakili ń gbèrò láti ṣe ìkọlù sí Ibarapa lọ́jọ́ Ileya

Iskilu Wakili ati CP Ngozi Onadeko

Oríṣun àwòrán, Facebook/Ngozi Onadeko

Kọmiṣọnna ọlọpaa ipinlẹ Oyo, CP Ngozi Onadeko ti ṣalaye fun BBC Yoruba ileeṣẹ ọlọpaa ko gbọ ohun kan to jọ pe Iskilu Wakili pẹlu awọn iṣọmọgbe rẹ n gbero lati ṣe ikọlu si ilu Igangan ati agbegbe Ibarapa nipinlẹ Oyo lasiko ọdun Ileya.

Ẹgbẹ OPC ẹka ti ipinlẹ Oyo lo kọkọ ke gbajare pe Wakili n gbero lati kọlu awọn eeyan Ibarapa lasiko ọdun Ileya.

Alaga OPC nipinlẹ Oyo, Rotimi Olumo sọ fawọn akọroyin pe oun wa pẹlu Aarẹ Onakakanfo, Iba Gani Adams nigba ti o gba ipe pe Wakili fẹ ṣe ikọlu si ilu Igbo Ora, Idere, Tapa, Ayete, ati Igangan lasiko pọpọsinsin ọdun ileya.

Olumo wa rọ awọn eeyan ilu naa lati wa lojufo bi wọn ti n ṣe ọdun Ileya.

Alaga OPC nipinlẹ Oyo fikun ọrọ rẹ pe Aarẹ Gani Adams ti sọ fawọn ọmọ ẹgbẹ OPC nipinlẹ Oyo lati ri pe erongba Wakili atawọn eeyan rẹ ko wa si imuṣẹ.

Kọmureedi Olumo ni OPC ti wa lojufo lati ri pe erongba Wakili ko ni wa si imuṣẹ lagbegbe Ibarapa.

Olumo ṣalaye siwaju si pe nkan to buru jai ni pe awọn ọmọ ẹgbẹ OPC mẹta to mu Wakili dero atimọle ọlọpaa ki wọn to pada fi wọn silẹ.

Alaga OPC tun ke si awọn ọba alade legbegbe Ibarapa lati fẹnuko ki wọn si kọju si awọn Fulani darandaran to n da agbegbe Ibarapa laamu.

Ṣugbọn nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, CP Onadeko ni iroyin naa ko ti dọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo.

Kọmiṣọnna ọlọpaa Oyo ni wamu wamu lawọn ọlọpaa duro lati ri pe awọn janduku to ba fẹ da rogbodiyan silẹ foju wina ofin.

O ni ileeṣẹ ọlọpaa ko figba kankan fi ọrọ abo nipinlẹ Oyo ṣere.

''Ko si ohun to jọ bayẹn lagbegbe Ibarapa nipinlẹ Oyo, awa ọlọpaa gan an wa ni ṣẹpẹ fun ẹnikẹni to ba fẹ huwa ọdaran.