Prophet TB Joshua: Ẹ̀gbọ́n tí TB Joshua fi sílẹ̀ lọ àti gbogbo ìlú kọ̀ láti jáde nílé torí ìsìnkú rẹ̀
"Alaanu ni TB Joshua jẹ fun wa ni gbogbo ilu Akoko, TB Joshua lo wa tan imọlẹ fun wa nilu Akoko".
Ni agbo ile oloogbe Temitope Joshua ni ilu Arigidi Akoko, lasiko ti wọn n ṣe isinku rẹ ni Eko, BBC Yoruba lọ ṣebẹwo lati mọ bi àwọn mọlẹbi ṣe ń daro ọmọ wọn, baba wọn, ẹgbọn wọn, aburo wn ati ẹni ti wọn pe ni "oludari aye wọn".
Gẹgẹ bi Akọbi baba rẹ ṣe sọ, o ni idi ti oun ṣe padanu pupọ tori pe TB Joshua ku ni pe o jẹ aburo si oun.
- 'Nínú ìran, Olúwa sọ fún mi pé èmi ni màá tẹ̀síwájú nínú iṣẹ́ ìráńṣẹ́ Wòlìí TB Joshua, kàyéfì ti ń ṣẹlẹ̀ nínú ìjọ mi báyìí'
- Ẹ wo bí ìṣìnkú TB Joshua ṣe ńlọ ní Arigidi Àkókó lónìí tí yóò wọlẹ̀ sùn!
- Wo àwọn òjíṣẹ́ Ọlọrun jàǹkàn ní Naijiria tí kò yọjú síbi ayẹyẹ ètò ìsìnkú TB Joshua
- "Kò sí Pásítọ̀ tó ṣiṣẹ́ ìyanu, tó lé ẹ̀mí èṣù jáde bíi TB Joshua"
- Ó dùn wá gaan pé wọn kò gbé òkú TB Joshua wá sílé, bó ṣe ọgọ́rùn ún ọdún, a ṣì ń retí - Àwọn ìyàwó ilé
- 'Ẹ wòó, ẹ máa retí ìdájọ́ àwọn olùwọ́de Yoruba Nation 49 tó wà láhàmọ́ Ọlọ́pàá ní ọjọ́ ...'
"Àbúrò kẹta mi ni TB Joshua àmọ́ Àrólé ẹbí wa ni, oun lo n tọju wa, oun lo n dari aye wa". O ni mọ lo jẹ fun awọn bẹẹ naa lo si tun jẹ baba fun awọn.
Ẹgbọn rẹ yii ko lee jade sita rara tori ko gbudọ foju gaani bi wọn ṣe n gbee bọ inu saare tori ẹgbọn lo jẹ si oloogbe, aṣa Yoruba si ni pe wọn o ki n sin ọmọde loju agbalagba.
- Àrá kọ ṣàràà! Ó sán pa èèyan 16 tó ń ya "Selfie" lórí ilé gogoro
- Kò sí ẹni tí mo fura sí lórí ikú ọkọ mi, àmọ́...- Adebisi aya Titus Ejanla tí wọ́n pa ní Ibadan
- Mo fẹ́ kí a dá Yorùbá Nations sílẹ̀ kí a lè máa mójútó àwọn adarí tó bá kọsẹ́ fúnra wa- Peter Fatomilola
- Ẹlẹ́hà tó ń ró aṣọ tí kò bo ìdí rẹ̀ kìí ṣe aya ti wa ní Ilorin- Batimoluwasi Oníwákà
- Èèyàn kan ti kú, 99 di àwátì lẹ́yìn tí ilé alájà méjìlá wó lulẹ̀ l'óru
- Mó ṣèlérí láti buwọ́lu àtúntò Naijiria, Ilé Aṣòfin o kù sí ọwọ́ yín - Ààrẹ́ Buhari
Yatọ fun awọn mọlẹbi rẹ, awọn ara ilu kun fọfọ nilee wọn, gbogbo ọja si ni wọn ti pa.
Iyalọja ilu Arigidi ni oloore ati alaanu ni TB Joshua to fọwọ kan aye gbogbo awọn to wa ni ilu rẹ.
Bakan naa, Kabiyesi ilu Arigidi, Ọba Isa Olanipeku to jẹ Zaki ti ilu Arigidi-Akoko bu ẹnu atẹ lu gbogbo awọn Pasitọ Naijiria to n foju aidaa wo TB Joshua ko lee ṣe to nkan to n ṣe. Kabiyesi ni oun le fi gbogbo ẹnu sọ ọ wipe ko si ọrọ afẹ aye lọrọ rẹ ju ko maa ronu bo ṣe le ran awọn eeyan lọwọ.
- 'Ìròyìn òfegè ni! Olóyè Sunday Igboho kò ṣàbẹ̀wò sí Ọba Oluwo'
- A ń gbóhùn àdúrà sókè ní orílẹ̀èdè 127 lágbàáyé torí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Baptist tí wọ́n jígbé ní Kaduna -Baptist Convention
- 'Ariwò tí ẹ̀ ń pa kò lè dóòlà ẹ̀mí Sunday Igboho, kò leè sá mọ́ ìjọba lọ́wọ́'
- CAN faraya lórí ikọlù agbofinro sàwọn ajàfẹ́tọ̀ bí Sunday Igboho