Titus Badejo, ibadan broadcaster murder: A ti fún Makinde ní gbèdeké ọjọ́ mẹ́ta láti fojú àwọn tó pa Ejanla hàn- NUJ

Àkọlé fídíò, Kò sí ẹni tí mo fura sí lórí ikú ọkọ mi, àmọ́..- Adebisi aya Titus Ejanla tí wọ́n pa ní Ib

Idajọ ododo ni Adebisi aya Badejo Ejanla, sọrọsọrọ tí agbebọn pa ní Ibadan n beere fun lasiko yii.

Iyawo gbajugbaja sọrọsọrọ ni Ibadan ti ba BBC Yoruba sọrọ lori ohun to ṣẹlẹ.

Titus Badejọ ni awọn agbebọn pa ni Ibadan ni Oluyole Estate.

O fi iya, iyawo to wa ninu oyun ati ọmọ mẹta silẹ lọ.

Adebisi Badejọ ṣapejuwe ọkọ rẹ ni oniwa tutu eeyan.

O ni ki ijọba se idajọ ododo ni oun n fẹ ki iku Ejanla ma ba a ja si asan.

Ejanla

Alaga ẹgbẹ awọn akọroyin ni ipinlẹ Oyo, NUJ Ademola Babalọla naa ba BBC Yoruba sọrọ.

O ni NUJ ti fun ijọba gomina ipinlẹ Oyo ni gbendeke ọjọ mẹta lati foju awọn aṣebi to ṣiṣẹ naa han nita.

Bakan naa ni Isaac Brown, agbohunsafefe naa sọrọ pe o to gẹ lori eto abo awọn osisẹ ijọba ni ipinlẹ Oyo.

Awọn NUJ mẹnuba awọn ipenija to n koju akoroyin ni ipinlẹ Oyo.

Ejanla