Iwo road mayhem: Ọlọ́pàá ní àwọn ti fi páńpẹ́ ọba mú ènìyàn mẹ́ta lórí ìpànìyàn tó wáyé ní Iwo Road, Ibadan

Ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ọyọ ti fi lede pe awọn ti mu eniyan mẹta to lọwọ ninu rogbodiyan to waye ni ibudokọ Iwo Road, ni ilu Ibadan.
Kọmisọnna ọlọpaa nipinlẹ Ọyọ, Ngozi Onadeko lo sọ bẹẹ lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ lẹyin ti wọn fi oju awọn mẹta naa han fun awọn araalu.
Onadeko ni awọn mẹta naa ni awọn fi oju wọn han nitori wọn pẹlu awọn to hu ṣe adari rogbodiyan to waye ni Iwo Road naa.
- Fulani attack, Ajowa Ondo: Àwọn Bororo yìí ti kọ́kọ́ ń dàná gba owó ní Ajọwa tẹ́lẹ̀, ọmọ mi 5 di aláìníbaba- Idowu ìyàwó Fulani
- Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ ọmọ ọdún 40 tó fipá bá ìyá ọdún 60 lòpọ̀ ní ìpínlẹ̀ Ogun
- A kò gbọ́ pé Sunday Igboho fẹ́ ṣe ìwọ́de ní ìpínlẹ̀ Eko- Kọmisọ́nnà ọlọ́pàá
- Lẹ́yìn ìjà tò gbẹ̀mí èèyàn bíi mẹ́ta, Makinde sè ìfilọ́lẹ̀ ìgbìmọ̀ àlákòóso Amọtẹkun
- Dino Melaye fi ọkọ Rolls Royce bùgá lórí Instagram, ni oníṣòwò ọkọ́ bá ní kó wá san gbèsè owó ọkọ̀ tó jẹ́ òun
- Ọwọ́ tẹ ọmọdébìnrín tó jí ara rẹ̀ gbẹ́ nítorí ìyá rẹ̀ ní kó lọ kọ́ ẹ̀kọ́ láti ṣe dókítà
O ni ileeṣẹ ọlọpaa ṣi n ṣe iwadii lọwọ ati wi pe awọn yoo ma fi to awọn araalu leti abajade iwadii awọn ti asiko ba to.
Ileeṣẹ ọlọpaa ke si awọn araalu lati ran awọn lọwọ pẹlu iroyin ti wọn ba ni lori iṣekupani naa ati bi wọn ba ṣe le ri awọn to n da ilu ru naa mu.

Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ni awọn ẹgbẹ onimoto ati awọn onifoonu ni wọn doju ija kọ ara wọn ti ẹmi sọnu, ti awọn kan si farapa.
Ọpọ ẹmi lo bọ ninu iṣẹlẹ naa. Ọkan ninu wọn ni Rahman to jẹ ọmọ ẹni to ni ile itaja nla ti wahala naa ti ṣẹlẹ ni agbegbe Iwo road.
- 'Kò sí ẹni tó lè ní kí a má wá sí Èkó, iwọ́de òní pẹ̀lẹ́ kùtù la fẹ́ ṣe'
- Ohun tó dára fún ètò ọ̀rọ̀ ajé wá ni láti yá owó fún ṣíṣe ojú pópó wá - Fashola
- Gómìnà ṣàbẹ̀wò sí àwọn tí ọlọ́pàá yìnbon lù l'Enugu, Ọ̀gá ọlọ́pàá ní ìwádìí gbọdọ̀ wáyé kíákíá
- Father's Day fa gbas-gbos láàrin Mercy Aigbe àti ọkọ rẹ̀ tẹ́lẹ̀, Gentry, ọkọ́ ní òun le tú àwọn àṣírí ìwà nọ̀bì rẹ̀ síta
- Ìgbẹ́jọ́ Kemisola Ogunniyi kò wáyé lóní, ó tún dọ̀la, ṣùgbọ́n... - Agbẹjọ́rọ̀
- Ẹ wo ohun tí a mọ̀ nípa bí agbébọn ṣe gbẹ̀mí sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀, Titus Badejo Ejanla ní ìlú Ibadan
- Ẹ wo bí olówó 'billionaire', Usifo Ataga ṣe kú ikú òjijì ní Eko
Ninu ọrọ tirẹ, ọkan lara awọn ti ọwọ tẹ naa ni awọn onifọọnu lo kọkọ ṣekọlu si ohun lasiko ti oun n ṣe iṣẹ oojọ oun.
Bakan naa ni gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ṣẹlẹri pe gbogbo awọn to n fa rogbodiyan nipinlẹ naa, ti wọn si n ṣekupa awọn eniyan ko ni lọ lai fi oju wina ofin.












