Fulani attack, Ajowa Ondo: Àwọn Bororo yìí ti kọ́kọ́ ń dàná gba owó ní Ajọwa tẹ́lẹ̀, ọmọ mi 5 di aláìníbaba- Idowu ìyàwó Fulani

Àkọlé fídíò, Fulani attack, Ajowa Ondo: Àwọn Bororo yìí ti kọ́kọ́ ń dàná ní Ajọwa tẹ́lẹ̀, ọmọ mi 5 di

Àwa Fulani mọ̀ pé ǹkan tí wọ́n ń se kò dára ṣùgbọ́n...- Baba Fulani

Idowu to jẹ iyawo ọkunrin Fulani ti wọn ṣapejuwe pe o ni suuru lo ba BBC Yoruba sọrọ lori bi nkan naa se ṣẹlẹ.

Saaju ni Toyin Osuolale ti salaye pe awọn bororo yii ti maa n da ọna gba owo lọwọ awọn ara ilu Ajowa nipinlẹ Ondo tẹlẹ.

Wọn ni saa deede ni awọn agbebọn naa ya wọ ilu Ajowa ni agbegbe Oba Akoko nipinlẹ Ondo ni guusu NAijiria.

Nibẹ ni wọn ti pa ọkunrin Fulani kan ti ọpọ maa n pe ni Babatunde Fulani.

Fulani Ajowa

Idowu to jẹ aya rẹ ni abẹ bẹẹdi ni oun ni lati ko awọn ọmọ marun un ti oun bi fun Babatunde Fulani pamọ si nitori ojo ọta ibọn to n rọ.

Nilu Ajowa lọsẹ to kọja yii ni wọn ti pa Fulani kan ti wọn si ji awọn mii gbe.

Toyin Osuolale, agba baba tọrọ naa kan salaye fun BBC pe nitootọ Bororo ni wọn ti wọn si gbọ Hausa daadaa.

O ni ọpẹlọpẹ Amotekun, Ọdẹ ilu, Agbofinro ati Soja lo ran wọn lọwọ lati lepa awọn Bororo naa.

Fulani Ajowa

O ni: Awa Fulani naa mọ pe nkan to n ṣẹlẹ yii ko dara, a ti gbe awọn igbese eto aabo kọọkan ṣugbọn iṣẹ pọ lọwọ ijọba.

Baba Osuolale ni pe awọn ba wọn ti wọn si koju ara wọn ki wọn to ri eeyan meji gab pada ninu awọn ti wọn jigbe ni Ajowa.

Eni ti ìṣẹlẹ naa ṣoju rẹ, Oludofin Yekini naa sọ ohun ti oju awọn eniyan Ajowa ni Oba Akoko naa ri lori iṣẹlẹ naa.

Otitoju Ayodeji to jẹ Kansilọ ibi ti ọfọ naa ti ṣe parọwa sijọba lati dide si eto aabo ni Naijiria ni eyi to ti n gba ẹbọ lọwọ koowa bayii..

O ni ko si ẹni to le sọ nipato iye ẹmi ti wọn ti pa ni Akoko bayii.

Fulani Ajowa