Sunday Igboho on Yoruba Nation: Kò sí ẹni tó lè ní kí a má wá sí Èkó, iwọ́de òní pẹ̀lẹ́ kùtù la fẹ́ ṣe

Sunday Igboho

Ajijàngbara ilẹ̀ Yorùbá, Sunday Adeyemo tí ọ̀pọ̀ mọ sí Sunday Igboho ti tún tẹpẹlẹ mọ pé kò sí ẹnikẹ́ni tó le dá òun atawọn ẹmẹwa rẹ dúró láti má wá sí ìlú Èkó fún iwọ́de Yorùbá Nation.

Igboho sọ èyí di mímọ láti ẹnu agbẹnusọ rẹ̀ Olayomi Koiki.

O fi dáhùn àhesọ tó ń lọ pé alága ẹgbẹ́ awakọ̀ ẹ̀ka tí ìpínlẹ̀ Eko Musilimu Akinsanya tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí MC Oluomo sọ pé òun yóò dena ẹnikẹ́ni tó bá jáde fún iwọ́de ìjìjàngbara ilẹ̀ Yorùbá kankan ní Ìpínlẹ̀ Eko.

Iwọ́de náà tí yóò wáyé ní ọjọ́ kẹta oṣù keje ni wọn ni yóò gbéra sọ láti ibùdókọ̀ Ojota.

Koiki sọ nínú fọ́nrán tó fi síta fi ṣàlàyé pé irú iwọ́de bẹ́ẹ̀ tí wáyé ní àwọn ìpínlẹ̀ Yorùbá tó kù, ó fi kún un pé iwọ́de òní pẹ̀lẹ́ kùtù náà kò kìí ṣe láti dá ètò ìlú ru tàbí rú omi àlàáfíà tó wà ní Ìpínlẹ̀ Eko.

Àkọlé fídíò, End SARS: Kemi jáde níle láti lọ bá mi ra oògùn ni mo gbọ́ pé ọlọ́pàá ti gbée- Ìyá Kemisol

Koiki ni: " A ń fi àsìkò yìí fi ọ̀rọ̀ ransẹ́ sì gómìnà Ìpínlẹ̀ Èkó Babajide Sanwó-Olú. Kò sí nǹkan tó kàn wá pẹlu ẹlòmíràn tó ní kí a má wá sí ìpínlẹ̀ Eko.

Sanwoolu, Igboho

Oríṣun àwòrán, Sanwoolu, Igboho

Igboho ni "Sanwó-Olú ni alaṣẹ àti Alákóso ọ̀rọ̀ àbò nítorí náà a ń sọ fún pé a ń bọ̀ nípìnlẹ̀ Eko".

O fi kun un pe awọn ti lọ sí Ogun, Ondo, Osun, àti Ekiti ní ìrọ́wọ́rọsẹ̀ sì ni gbogbo rẹ̀ lọ, "nítorí náà kò sì ẹni tí ó lè sọ pé kí a má wá sí Eko".