Ekiti fake kidnap: Ọwọ́ tẹ ọmọdébìnrín tó jí ara rẹ̀ gbẹ́ nítorí ìyá rẹ̀ ní kó lọ kọ́ ẹ̀kọ́ láti ṣe dókítà

Dokita

Oríṣun àwòrán, Others

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ekiti ti kede pe ọwọ awọn ti tẹ obinrin ọmọ ọdun mẹrindinlogun, Suluka Abimbola ati awọn mẹta miran lori ẹsun pe o parọ ji ara rẹ gbe.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ekiti, Abutu Sunday to fi iroyin naa lede ni nkan bi aago mẹjọ alẹ ni ọwọ tẹ Suluka Abimbola ati ọrẹkunrin rẹ Oluwaseun Daniel Olajide.

Eyi ko ṣẹyin lori ẹsun pe wọn ṣiṣẹ pọ lati pa irọ gba owo.

Sunday ni ileeṣẹ ọlọpaa bẹrẹ iwadii lẹyin ti ẹgbọn Abimbola wa fi ẹjọ sun ni agọ ọlọpaa ni agbegbe Bawa Estate pe aburo ohun to kuro ni ile lọ si ileewe Christ School, Ado Ekiti ti di awati.

Arakunrin naa ni lasiko ti wọn pe ẹrọ ilewọ rẹ ni ọkunrin kan gbe e to si sọ wi pe awọn ti ji aburo rẹ gbe.

Ki wọn si wa iye owo to to ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta (500,000) ki wọn san an bi apo iṣuna banki kan ti o jẹ ti arakunrin Adisa Damilọla.

Ado Ẹkiti ijinigbe

Oríṣun àwòrán, @NPF

Ileeṣẹ ọlọpaa ni kete ti wọn gbọ ọrọ naa ni wọn bẹrẹ iwadii naa lori ẹni to ni apo isuna banki ti wọn ni ki wọn san owo si, ti wọn si tun ri ọrẹ rẹ Oluwaseun Daniel Olajide ti wọn wa ri ti wọn si fi panpẹ ọba mu.

Adisa Damilola lo mu awọn ọlọpaa naa lọ si ile itura, Alex Grace Hotel nibi ti Suluka Abimbola ati ọrẹkunrin rẹ, Oluwaseun Daniel Olajide ati Adefolaju Caleb fi ara pamọ si, ki ọwọ to tẹ wọn.

Laiko ifọrọwanilẹnuwo ni Suluka Abimbola jẹwọ wipe oun lo n gbero bi wọn ṣe ji oun gbe pẹlu ajọmọ awọn ọkunrin mẹta iyoku.

Abimbola ni idi ti oun fi ji ara oun gbe ni lati le gba owo lọwọ awọn obi oun ki oun le sakuro ni Ekiti, nitori iya oun sọ wi pe dandan oun gbọdọ lọ si ileẹkọ giga Fasiti lati lọ kọ ẹkọ imọ Dokita.

Àkọlé fídíò, 'CAC Agbala Itura ni mo ti bẹ̀rẹ̀ ìlú lílú kí ń tó máa bá Janet, àbúrò Michael Jackson lù Gangan àti Omele'

Amọ, o ni kii ṣe iṣẹ ti oun fẹ yan laayo niyẹn, nitori iṣe oṣere lo wu oun ṣe amọ iya oun to kọ fun oun ni oun ṣe fẹ salọ.

Ninu ọrọ tirẹ, Kọmisọnna ọlọpaa nipinlẹ Ekiti, Tunde Mobayo koro oju si iṣẹlẹ naa, to si ni iwadii ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa, ti yoo si jẹ ẹkọ fun awọn ẹlomiran lati maṣe hu iru iwa naa mọ.

Àkọlé fídíò, 'Ọwọ́ mi ti ń jẹ́rà ká tó mọ̀ pé àfi kí wọ́n tún gé e bí mo bá ṣì fẹ́ máa ṣe iṣẹ́ awakọ̀ lọ'