Women Life saver car: Ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ yì ti gba ẹ̀mí ọ̀pọ̀ aláboyún àtọmọ ọwọ́ lá ní Jigawa

Àkọlé fídíò, Life saver car: Ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ yì ti gba ẹ̀mí ọ̀pọ̀ aláboyún àtọmọ ọwọ́ lá ní Jigawa

Awọn obinrin abule Bardo nipinlẹ Jigawa wa ọna abayọ si iṣoro iku to n pa wọn.

Ile iwosan jinna pupọ si awọn olugbe abule Bardo ni ipinlẹ Jigawa ni ariwa Naijiria.

Ọpọ igba ni ẹmi awọn obinrin ati ọmọ wọn maa n sọnu nipase ilera lasiko iloyun atiu irọbi.

Eyi si ti jẹ ki wọn wa ni ipo ibanujẹ fun ọpọlọpọ igba.

Lẹyin o rẹyin, awọn obinrin abule yii forikori pẹlu imọran Halima Adamu, wọn si da owo jọ pọ fi ra ọkọ ayọkele olugbala ti yoo maa gbe wọn lọ sile iwosan fun itọju.

Moto
Àkọlé àwòrán, Ọkọ ayọkẹlẹ olugbala ni Bardo

Yunnusa Mohammed to jẹ awakọ ọkọ naa ba BBC sọrọ pe gbogbo wọn ni wọn ni nọmba oun.

O tun salaye ọna alakalẹ ti wọn n gba fi lo ọkọ naa fun igbala ẹmi alaboyun ati ọmọ ọwọ nibẹ.

Yunussa sọ bi ọkọ ayọkẹlẹ yii se ti ra ọpọ ẹmi pada ti inu gbogbo obinrin abule naa si n dun.

Bakan naa ni Halima salaye bi wọn ṣi ṣe n da owo lati mojuto ọkọ naa ati awakọ rẹ titi di isinyi.