Iwo Road fight: Rahmon n múra láti lọ rí ìyàwó àti ìbèjì tó bí ní US kí jàndùkú tó pa ní Iwo road - Ẹbi Rahmon

Rahmon Azeez

Oríṣun àwòrán, Punchng

Yoruba bọ, wọn ni ẹni ti ko ni di ọla, to ba ri ẹni sọ fun un, i ba jiyan pe ko le ri bẹẹ lailai.

Bẹẹ gan ni ọrọ ri fun Rahmon Azeez, ọkunrin ẹni ọdun mẹrindinlogoji, ti awọn janduku pa lasiko ija igboro to waye ni Iwo-Road, nilu Ibadan, ni Ọjọru.

Iroyin sọ pe ọkunrin naa n mura lati lọ wo iyawo ati awọn ọmọ rẹ tuntun, ibeji, ni orilẹ-ede America, ko to di pe o ku iku ojiji.

Ẹgbọn oloogbe to ba awọn akọroyin abẹle sọrọ, Ahmed Azeez, sọ pe Rahmon ko tii ri awọn ọmọ naa tabi fi ọwọ kan wọn ni ojukoroju lati igba ti iyawo rẹ ti bi wọn si ilu oyinbo.

Lati igba naa si ni iyawo ti n gbe nibẹ, pẹlu erongba pe oun naa yoo lọ ba wọn laipẹ.

Àkọlé fídíò, 'CAC Agbala Itura ni mo ti bẹ̀rẹ̀ ìlú lílú kí ń tó máa bá Janet, àbúrò Michael Jackson lù Gangan àti Omele'

Ọgbẹni Ahmed sọ pe wọn ti fun Rahmon ni 'visa' lati rinrinajo naa, amọ, iku ko jẹ ki erongba rẹ wa si imuṣẹ.

"O gbero lati fi oju kan idile rẹ, amọ iyẹn ko waye. A ti sin oku rẹ. Ọkan mi bajẹ pupọ, nko ti ẹ mọ boya àlá ni mo n la."

Ki gan-an lo fa ija laarin awọn oniṣowo foonu ati awọn janduku to pa Rahmon Azeez?

Iroyin to n lọ, ti a ko ri ibi fidi rẹ mulẹ ni pe iya to bi Rahmon Azeez, Mama Ahmed, gan-an lo kọ ile itaja ti wahala ti waye, nibi ti awọn ṣọọbu ti wọn ti n ta foonu wa.

A gbọ pe ninu ile itaja naa ni Rahmon naa ti n ta foonu, to si gbajumọ laarin awọn oniṣowo ẹgbẹ rẹ nibẹ.

Àkọlé fídíò, Ẹ pàdé olórin Fuji alhaji Besco tó jọ Ayinde Barrister to tún ń kọrin gẹ́lẹ́ bíi tirẹ̀

Wọn ni ni owurọ Ọjọru ti ija waye, Rahmon lo fẹ gbe ọkọ rẹ wọle sinu ọgba ile itaja naa, amọ awọn awakọ bọọsi to n gbe ero nibẹ ti wa ọkọ wọn di ẹnu ọna.

Eyi lo mu ki Rahmon sọ fun awọn awakọ ọhun lati kuro ni ẹnu ọna, ki awọn onibaara ati oniṣowo le raaye wọle.

Iroyin sọ pe ọrọ ti Rahmon sọ bọ si apo ibinu awọn awakọ, eyi to fa tita ohun si ara wọn.

Lẹyin naa ni wọn ni awọn awakọ naa lọ fi ẹjọ rẹ sun awọn alaṣẹ gareji ọkọ, amọ awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ pe igbati ati ẹṣẹ ni wọn bẹrẹ si ni fi da sẹria fun Rahmon.

Eyi naa si lo mu ki awọn to oniṣowo foonu, doola rẹ kuro lọwọ awọn awakọ naa ati awọn alaṣẹ gareji.

Ṣugbọn, ija naa ko tan. Wọn ni niṣe ni awọn eeyan naa fi ọrọ wọn ṣe ipadabọ abijawara bi ẹkun, nitori ṣe ni wọn lọ pọ si wa, ti wọn si bẹrẹ si ni kọlu ile itaja naa pẹlu oriṣiriṣi nkan ija oloro.

Awọn to wa nibi iṣẹlẹ naa sọ pe Rahmon gan-an ni wọn doju kọ, ti wọn si bẹrẹ si ni ju okuta, igi ati awọn nkan ẹlẹnu ṣomu-ṣomu mọ, ko to di pe wọn fi nkan gun un ni àyà.

Àkọlé fídíò, Baba Ijesha Rape Case: Yomi Fabiyi ní òun nìkàn lòun rí ara òun tó dúró tí Baba Ijesha

Ọkan lara awọn to ba oniroyin sọrọ, Taye Salawu sọ pe awọn janduku naa rii pe ẹmi bọ lara Rahmon ki wọn o to kuro nibẹ.

Bi awọn kan ṣe doju ija kọ Rahmon, ni awọn miran n kọlu awọn oniṣowo to ku, ti wọn si n ko wọn ni ọja.

Lẹyin naa ni awọn akẹẹgbẹ rẹ gbe oku rẹ lọ si ẹnu ọna ọfiisi ijọba ni adugbo Secretariat lati fẹhonu han.

Inu ibanujẹ ni ẹbi Rahmon Azeez wa

Iwe iroyin abẹle The Punch to ṣe abẹwo si ẹbi oloogbe sọ pe mama rẹ, to ni ile itaja naa, Alhaja Salmot Azeez sọ fun awọn akọroyin pe oun lo n gba awọn awakọ ni aaye lati ma lo aye diẹ niwaju ile itaja oun fi ṣe garej, botilẹ jẹ pe wọn n di ẹnu ọna.

O ni ọrọ wọn ti kọkọ fa wahala, eyi to de agọ ọlọpaa.

"Kọmisanna ọlọpaa nigba kan, Adisa Bolanta ba wa dasi, mo si gba pe ki wọn o ma a duro nibẹ lati gbe ero.

"Ṣugbọn, o jẹ ibanujẹ pe iku ọmọ ni wọn fi san ore fun mi."