Ibadan Violence: Bí ìkọlù jàǹdùkú sí àgọ ọlọ́pàá Mapo ní Ibadan ṣe wáyé rèé

Awọn janduku to n da igboro ru

Oríṣun àwòrán, @PoliceNG

Iroyin to tẹ wa lọwọ lati ilu Ibadan sọ pe, awọn afurasi janduku kan ti ṣe ikọlu sawọn ọlọpaa nitori bi wọn se mu awọn afurasi meji ti wọn lo n da omi alaafia ilu ru.

A gbọ pe ikọlu naa bẹrẹ lagbegbe Odo-Osun lọjọbọ, ti o si tan de agọ ọlọpaa to wa ni Mapo.

Eeyan meji ku ninu iṣẹlẹ naa gẹgẹ bi iroyin to tẹ wa lọwọ ti wi.

Lọjọbọ ni awọn ọlọpaa mu awọn janduku meji kan ladugbo Odo-Osun nitosi Mapo.

Bi awọn akẹgbẹ wọn ṣe ri pe ọwọ ti tẹ wọn, ni wọn gbiyanju lati fipa tu wọn silẹ lọwọ awọn ọlọpaa.

Aworan afihan agọ ọlọpaa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Amọ ṣa, ọlọpaa ṣina bolẹ fun wọn ni agbegbe Odo-Osun ti eeyan kan si ku nibẹ.

Lẹyin ikọlu ti Odo-Osun yii, awọn janduku taa n wi yi tun ṣigun lọ si agọ ọlọpaa to wa ni Mapo, lati fẹhonu han lori eeyan wọn kan ti o ku.

Ninu wọdu-wọdu to waye nibẹ, awọn ọlọpaa tun yinbọn lati daabo bo agọ wọn, eeyan kan tun fara gbọta to si gba ibẹ ku.

Àkọlé fídíò, Ilorin Conjoined Twins: Àwọn òbí ìbejì tó lẹ̀pọ̀ ní ọ̀kàn àwọn bàjẹ́ láti rí ibèjì wọn tó

Alukoro ọlọpaa ni ipinlẹ Oyo, Olugbenga Fadeyi fidi iṣẹlẹ yii mulẹ fawọn akọroyin ninu atẹjade kan to fi sita.

O ni ''lẹyin tawọn ọlọpaa mu awọn janduku meji kan, arakunrin kan ti wọn n pe orukọ rẹ ni ''Packaging'' lewaju awọn janduku mii to to ọgbọn,

lati ṣigun bo agọ ọlọpaa, ki wọn le tu akẹẹgbẹ wọn silẹ''