Ogun Police: Àwọn jàǹdùkú kọlu ọlọ́pàá, DPO faragbọta, ọlọ́pàá mẹ́rin di àwátì

Ọlọpa ilẹ Naijiria

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Ìgbà àkọ́kọ́ kọ́ nìyí tí irú ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ̀ yòó wáyé

Bi awọn to n ṣọ araalu ba di ẹni ti awọn janduku wa bẹrẹ si ni jigbe, kini ki ara yooku wa a ṣe?

Ibeere to gba ọkan awọn eeyan nipinlẹ Ogun ree lẹyin ti awọn janduku ji ọlọpaa mẹrin gbe ti wọn si tun yinbọn lu ọga agọ ọlọpaa, DPO, kan.

Ṣugbọn ohun taa tun ri gbọ lati ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, wọn ti ribi doola mẹta ninu awọn ọlọpaa tawọn janduku ji gbe yi.

Ladugbo Aba Tuntun, Ijebu Igbo ni ijọba ibilẹ Ijebu North ni ipinlẹ Ogun niṣẹlẹ yi ti waye.

Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyemi lo fi ọrọ yi to awọn akọroyin lati ọjọ Abamẹta.

O sọ pe ọlọpaa kan arakunrin Emmanuel Gene lo ṣi yi wa lọdọ awọn ajinigbe yi ati pe awọn ti da ọlọpaa sita lati ṣawari rẹ.

Nipa mimu awọn to wa nidi iṣẹlẹ yi, alukoro yi ni afurasi mẹta lawọn ti mu ti wọn si ti n wi tẹnu wọn nipa iṣẹlẹ yi.

Gẹgẹ bi Oyeyemi ti ṣe sọ, baalẹ abule naa lo fi iwe ranṣẹ si awọn ọlọpaa lati wa ba wọn koju awọn kan ti wọn ni nkan ija lọwọ,

''Ọga ọlọpaa agọ to wa ni Ijebu Igbo lo lewaju pẹlu awọn fijilante lati koju awọn obilẹjẹ yi.

Abalọ ababọ, wọn ri awọn ibọn atamatase mẹfa gba, ibọn ẹtu mẹrindinlogun ati ọta''

''Wọn mu awọn afurasi naa.

Àkọlé fídíò, India: Ẹ wo bí àwọn ènìyàn ṣe dóòlà èmí erin tó jálulẹ̀

Nigba ti wọn n gbe wọn lọ si agọ ọlọpaa lawọn janduku kan dawọn lọna ti wọn si ji ọlọpaa mẹrin gbe''

O fi kun un pe: ''Wọn yinbọn lu DPO ti wọn si tu awọn afurasi ti ọlọpaa mu silẹ''

Oyeyemi wa pari ọrọ rẹ pe awọn ti doola ọlọpaa mẹta ti iwadii si n tẹsiwaju lati ṣawari awọn ti o ku.

Àkọlé fídíò, Ìgbátí ìgbámú àná látọwọ́ sọ́jà obìnrin ti bá arákùnrin náà dé iléèwòsàn