Teslim Folarin: Ọwọ́ tẹ àwọn tó kó nkan tówó rẹ̀ tó N200m nílée Sẹ́nétọ̀ tó n ṣojú Oyo Cental

Oríṣun àwòrán, @BolanleCole
Ọwọ sinkun ọba ti tẹ lara awọn to ṣe ikọlu silee Sẹnetọ to n ṣoju ẹkun arin gbungbun ipinlẹ Oyo nile igbimọ aṣofin, Teslim Folarin,
Lasiko ikọlu naa pẹlu afihan fọnran to gba ori ayelujara kan, ọpọlọpọ nkan ti ko lonka ni awọn afurasi janduku naa ji ko.
Latori awọn ọkada tuntun ti iroyin ni o le ni ọọdunrun, firiiji, ẹrọ ilọta ati ọpọlọpọ nkan mii ti iye rẹ to ọpọlọpọ miliọnu naira.
Iru iṣẹlẹ bayii ti n waye kaakiri orilẹede Naijiria lẹnu ọjọ mẹta yii.
Ẹwẹ, gẹgẹ bi ikọ apapọ awọn oṣiṣẹ alaabo ipinlẹ Ọyọ iyẹn Operation Burst ṣe sọ ọ, wn ti gba eeyan marun mu ti wọn lọwọ ninu iṣẹlẹ naa ti wọn si ni ijọba atawọn oṣiṣẹ alaabo to ku ti da si i.
Wọn fi kun un pe akitiyan ti n lọ lọwọ lati tun fi ọwọ ofin mu awọn mii sii to lọwọ ninu ikọlu si ile aṣofin naa.
Lyin iṣẹlẹ yii, iroyin sọ pe ohun gbogbo ti pada sipo bo ṣe yẹ ni agbegbe naa ni ilu Ibadan.
- Ẹni tó jí ọ̀pá aṣẹ ń bọ̀ wá túbá fúnrarẹ̀, mo fi dáa yín lójú gẹ́gẹ́ bí ìyá - Erelu Kuti
- Ó tó gẹ́ẹ́! Ẹ̀yin ọlọ́pàá, ẹ di ìhàmọ́ra kẹ́ẹ já àlàfíà ìlú gbà padà - Ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá
- Wo àwọn ayédèrú ìròyìn tó gbà'gboro kan lásìkò ìwọ́de #EndSARS
- Àwọn ìbéèrè tí Tinubu bi gómìnà Sanwo-Olu àtàwọn olùwọ́de tó faragbọta ní Lekki Tollgate rèé
Bí àwọn jàndúkù ṣe yabo ilé Sẹ́nétọ̀ Teslim Folarin, tí wọ́n kó ẹ̀rọ ata, ọ̀kadà, fírìíjì àti àwọn nkan tí owó rẹ̀ tó N200m
Ni ọsan ọjọ Satide ni iroyin jade pe awọn janduku kan yabo ile sẹnetọ to n ṣoju ẹkun idibo aarin gbungbun Oyo.
Oludamọran pataki fun Sẹnetọ Folarin, Ọgbẹni YSO Olaniyi sọ fun BBC Yoruba pe ni owurọ kutukutu ọjọ Satide ni awọn janduku naa to to igba niye, kọlu ile naa to wa ni Oluyole Estate nilu Ibadan, ti wọn si ko awọn nkan ti Sẹnetọ ra fun idẹrun ara ilu salọ,
Lara nkan ti wọn ko ni ọkada bi igba, ẹrọ to n lọ ata, firiji, ẹrọ ti wọn fi n pọ taya ọkọ, ati awọn nkan miran.

Oríṣun àwòrán, yso olaniyi
Olaniyi ṣalaye pe ninu oṣu Kejila ọdun 2020 ni Asofin Folarin fẹ ẹ pin awọn irin'ṣẹ naa fun awọn eeyan ti ko ri ọwọ rọri ni ẹkùn idibo rẹ, amọ awọn janduku ti ko gbogbo rẹ lọ.
O ṣalaye pe niṣe ni wọn kọkọ fi iya jẹ ẹṣọ alaabo to wa ninu ile naa, ti wọn fi raaye ṣiṣẹ ibi wọn.
Bakan naa lo sọ pe ọwọ pada tẹ diẹ lara wọn to sa pamọ sinu ile naa nigba ti awọn ọlọpaa de si ibẹ.
Ọgbẹni Olaniyi sọ pe "abẹ ibusun, ati awọn ibomiran bi kọnbọọdu, ni awọn janduku naa sa pamọ si, ki ọwọ to o tẹ wọn.
"Ọwọ tẹ awọn kan naa laarin igboro, a si ti fa gbogbo wọn le awọn agbofinro lọwọ.
"Ṣugbọn ọpọlọpọ awọn nkan ni wọn ti ko lọ ki awọn oṣiṣẹ alaabo to o de si ile naa."
O fi kun ọrọ rẹ pe awọn to wa ninu ile naa lasiko ikọlu ọhun fi ara pa, amọ ẹmi ẹnikẹni ko ba a lọ. Bakan naa lo sọ pe Sẹnetọ Teslin fun'ra rẹ ko si nile lasiko iṣẹlẹ ọhun.













