EndSARS Protest Update: Aráàlú gbé ajílẹ̀ àti oògùn apakòkòrò dípò oúnjẹ ìrànwọ́ Covid-19 l'Ekiti

Eroja ounjẹ majele

Oríṣun àwòrán, @Areatalkr

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Lẹyin ikọlu to waye nibi iwọde EndSARS ni Lekki Toll Gate l'Eko, ni ọpọ awọn ara ilu kan bẹrẹ si n kọlu awọn ile ti ijọba ko awọn ounjẹ to yẹ ko pin lasiko igbele Covid-19 si.

Gẹgẹ bi ọpọlọpọ fidio to n tan kalẹ lori ayelujara, ilu Eko ni awọn eeyan naa ti kọkọ kọlu awọn ile ti wọn ko ounjẹ naa si, ti wọn si ri ọpọ ounjẹ ko.

Ko pẹ si asiko naa ti awọn eeyan ipinlẹ miran bii Oyo, Osun, Kwara ati Ekiti naa bẹrẹ si n kọlu irufẹ ibudo nnkan pamọ si bẹẹ ni ipinlẹ wọn, lati ko ounjẹ ọhun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ṣugbọn ni ti ipinlẹ Ekiti, ọrọ ko ri bẹ nitori ohun ti a gbọ ni pe, oogun apakokoro ati ajilẹ ni awọn eeyan ji ko dipo ounjẹ.

Lara awọn to ke gbajare ni ọkunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Babajide lori Twitter to sọ pe "gbogbo ipinlẹ ni awọn eeyan ti n ji ounjẹ iranwọ Covid-19 ti ijọba fi pamọ ko, ayafi Ekiti ti awọn eeyan rẹ n ko oogun apakokoro ati ajilẹ."

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Yatọ si ọgbẹni yii, awọn eeyan miran na tun n lọgun lori ayelujara pe majele ni ẹnikẹni to ba ro pe oun ko ounjẹ Covid-19 l'Ekiti ko.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Ṣaaju ni ijọba ipinlẹ naa ti kọkọ ke gbajari pe awọn janduku kan n gbimọ lati kọlu awọn ile ikẹru si ni ipnlẹ naa nitori pe wọn wa ounjẹ iranwọn Covid-19.

Ninu atẹajde ti kọmiṣona fun eto iroyin, Akin Omole fi lede, o ni ijọba Ekiti kò kó ounjẹ iranwọ Covid-19 pamọ sibi kankan nitori o ti pin gbogbo rẹ lasiko igbele.

Ekiti

Oríṣun àwòrán, @Areatalkr

Ṣugbọn ṣe ootọ ni pe ounjẹ iranwọ Covid-19 ni awọn eeyan ko l'Ekiti tabi ko ri bẹẹ?

Ijọba Ekiti ko tii sọ ohunkohun nipa ọrọ yii.

Àkọlé fídíò, #EndSARS : Àwọn ọ̀dọ́ dáná sun tírélà akẹ́rù tẹrùtẹrù ní Ekiti