EndSars Protest: TB Joshua, Indaboski àtàwọn Wòlíì méjì míràn ti kéde wàhálà ìwọ́de sáájú

Awọn wolii mẹrin to sọ asọtẹlẹ nipa iwọde EndSARS

Oríṣun àwòrán, Twitter, Facebook, AFP

Ni asiko ti ọdun tuntun ba n kan ilẹkun gbọn-gbọn, tabi to ba wọle de, kii se ajeji mọ lati ri awọn ojisẹ Ọlọrun kan, ti wọn yoo sọ asọtẹlẹ nipa awọn nnkan ti yoo sẹlẹ ninu ọdun naa.

Bi o tilẹ jẹ pe arun Coronavirus bẹ jiga saarin agbaye ninu ọdun 2020, amọ ko daju pe ojisẹ Ọlọrun kankan sọ asọtẹlẹ nipa rẹ, lati mu kawọn eeyan gbaradi fun.

Ninu osu kẹwaa ọdun 2020 yii naa ni iwọde EndSARS waye, ninu eyi ti ọpọ ẹmi ati dukia ti baa rin, ti laasigbo si gbode pẹlu.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amọ nibayii, awọn ojisẹ Ọlọrun kan to gbajumọ bii isana ẹlẹẹta lorilẹede Naijiria, ti fọwọ gbaya pe awọn ti sọ asọtẹlẹ nipa rogbodiyan naa saaju.

Diẹ lara awọn ojisẹ Ọlọrun ti wọn si ti kede pe awọn ti sọ asọtẹlẹ nipa iwọde EndSARS ati ipaniyan to tẹle ree:

Wolii TB Joshua:

Wolii TB Joshua

Oríṣun àwòrán, Twitter/tbjoshua

Ọkan lara awọn wolii lorilẹede Naijiria to maa n sọ asọtẹlẹ loore-koore ni oludasilẹ ijọ Synagogue lagbaye, TB Joshua.

Wolii ijọ Sinagọgu naa si ti sọ asọtẹlẹ to fara pẹ laasigbo to tidi iwọde EndSARS yọ, amọ o kan jẹ pe ọjọ ti pẹ, to ti sọ asọtẹlẹ naa.

Asọtẹlẹ naa si lo sẹ lẹyin ọdun meje to ti kede nipa rẹ.

Ninu iwaasu rẹ to se ninu ijọ rẹ to wa nilu Eko, lọjọ Kẹrinla, osu Keje, ọdun 2013, ti wọn si gbe sori ayelujara, ni TB Joshua ti n ke tantan nipa ajalu to n bọ.

Wolii TB Joshua

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Ninu fidio naa, ti ileesẹ kan gbe sita lo ti n pariwo pe "Iran ti mo ri niyi, ẹ fa awọn ọdọ yin mọra, mo ri ijijagbara awọn araalu tii se Revolution.

Mo ri ti ọpọ eeyan ya bo oju popo, o seese kẹ le da iwọde duro, amọ ẹ ko le da ijijagbara duro.

O seese kẹ le dawọ ijijagbara naa duro ni ibẹrẹ pẹpẹ amọ nigba to ba ya, wahala naa yoo fẹju sii, ti ko si ni dawọ duro mọ.

Awọn nnkan ti mo ri pe yoo waye ree, orilẹede Naijiria, ẹ gbadura.

Wolii Chukuemeka Odumeje ( Indaboski):

Wolii Chukwuemeka Odumeje, ti ọpọ eeyan mọ si Indaboski naa jẹ wolii keji to kede pe Ọlọrun ti fi isẹlẹ EndSARS han oun saaju.

Loju opo Instagram rẹ si lo ti kọkọ se alabapin iroyin naa, to si tun tun sọ lẹyin ti rogbodiyan suyọ lẹyin iwọde EndSARS.

Wolii Chukuemeka Odumeje

Oríṣun àwòrán, Instagram/odumeje_dlion

Indaboski ni nibẹrẹ ọdun 2020 ni oun ti sọ asọtẹlẹ pe ki olori di ori rẹ mu ni nitori ọdun yii kii se ọdun awada tabi ẹfẹ rara, ọdun ija ati wahala gbaa ni.

"Ẹ gbọ mi, ẹ gbadura fun orilẹede Naijiria nitori idaru-dapọ, rogbodiyan nibi gbogbo. Mo ri awọn agbegbe kan ti wọn kede isede konile o gbele.

Amọ awọn eeyan tako ikede naa, ti wọn si bọ sita lati fi ẹhonu han lai bikita fun aabo ẹmi wsn rara."

Wolii I. O Samuel:

Bakan naa ni Wolii Samuel ninu iran rẹ fun ọdun tuntun, ti sọ asọtẹlẹ lori rogbodiyan EndSARS.

Wolii I.O Samuel

Oríṣun àwòrán, prophet_i_o_samuel

Ninu asọtẹlẹ naa lo ti kede pe oun ri awọn eeyan to mura bii ologun, ti wọn n se iwa ika sawọn araalu ati ọpọ ọmọ orilẹede Naijiria.

"Bakan naa ni mo tun ri awọn ọdọ, ti wọn n sare sọtun-sosi lasiko iwọde, ti ọpọ ẹmi si bọ sinu rẹ, bakan naa ni awọn dukia sofo pẹlu."

Wolii Jeremiah Omoto Fufeyin:

Wolii kẹrin to kede nipa asọtẹlẹ rẹ saaju lori rogbodiyan ati iwọde EndSARS ni Wolii Jeremiah Omoto Fufeyin.

Wolii Jeremiah Omoto Fufeyin

Oríṣun àwòrán, Facebook/Prophet Jeremiah Omoto Fufeyin

Lọjọ Kejilelogun osu Kefa ọdun 2020 si lo ti sọ saaju pe orilẹede Naijiria, lati ipasẹ awọn ipinlẹ kan yoo mi titi, ti gbogbo agbaye yoo si gburo rẹ.

"Iku yoo pọ lati ipasẹ rogbodiyan nla kan to n bọ, mo si n rọ awọn ọdọ lati gbadura gidi lori isẹlẹ naa.

Ẹ sọ́ra fún ìwà olè àti jàgídíjàgan nílẹ̀ Yorùbá - Sunday Igboho

Ọkan gboogi lara awọn ajafẹtọ ọdọ lorilẹede, Oloye Sunday Adeniyi Adeyemo ti ọpọ eniyan mọ si Sunday Igboho, ti pe fun alaafia laarin awọn ọdọ kaakiri orilẹede Naijiria.

Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Igboho

O fi ikilọ yii lede nigba to n sọrọ lori ifẹhọnuhan EndSars ti awọn janduku n lo lati fa rogbodiyan kaakiri orilẹede Naijiria.

O rọ awọn ọdọ lati ri ifẹhọnuhan EndSars gẹgẹ bi ọna ati beere fun ọjọ ọla to dara lọwọ ijọba, eleyii ti wọn wa n lo lati ba ohun ini ijọba jẹ.

''Nitori naa, mo bẹ awọn ọdọ lati jọwọ fi gbogbo iwa ipa silẹ, ki wọn si gba alaafia laaye.''

O ni: ''Lilo iwa ipa, ija ati jijo ohun ini ijọba ati ti awọn eniyan ko ni wa ọna abayọ si iṣoro to doju kọ orilẹede Naijiria.''

''Nitori naa, mo fẹ kẹ gba alaafia laaye, ki a si duro de ijọba lati sọrọ lori ibeere ti awọn ọdọ bere lọwọ wọn.''

Amọ, Sunday Igboho bu ẹnu atẹ lu bi ikọ ọmọogun Naijiria ṣe yinbọn lu awọn afẹhọnuhan ni Lekki Toll-Gate nipinlẹ Eko.

Bẹẹ si lo tako gbogbo iṣekupani to waye kaakiri orilẹede Naijiria gba ọwọ awọn janduku ati awọn ọlọpaa lorilẹede Naijiria.

Bakan naa lo ni iwa buruku ni awọn ikọ ọmọogun to yinbọn naa hu, nitori owo ori awọn ọmọ Naijiria ni wọn fi n sanwo oṣu wọn, ti wọn si fi ra ibọn naa fun wọn.

Sunday Igboho wa kesi ijọba apapọ lati ri wi pe wọn ṣewadii finifini lati mọ awọn to ṣiṣẹ ibi yii, ki wọn si fi wọn jofin.

Ìwọ́de EndSARS ló ń sọ pé inú ń bí àwọn ọ̀dọ́, ìjọba, ẹ náání wọn - Obasanjo

Olusegun Obasanjo ati Ooni Ogunwusi

Ọ́ba Enitan Ogunwusi ni awọn ọdọ ti gba akoso orilẹede yii, lati ọjọ akọkọ iwọde, si ni wọn ti se afihan pe awọn ni abuda asaaju rere.

Agba kii wa lọja, ki ori ọmọ tuntun wọ, idi ree ti awọn agba meji nilẹ Yoruba fi fori kori lori iwọde EndSARS to n lọ lọwọ yika Naijiria.

Awọn agbaagba mejeeji naa ni Oloye Olusegun Obasanjo ati Ọọni tilu Ile Ife, Ọba Adeyeye Enitan Ogunwusi, ti wọn sọrọ lori iwọde naa.

Oloye Obasanjo, lasiko to lọ se kara o le si ọọni salaye pe iwọde to n lọ yika Naijiria yii ti fun ijọba lanfaani lati sọ fun araalu pe oun naani wọn.

Obasanjọ ni iwọde yii lo n safihan inu to n bi awọn ọdọ Naijiria, eyi to yẹ ki ijọba tete kọbi ara si.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Aarẹ ana ni Naijiria naa ni o le ni ida ọgọta ninu ọgọrun awọn eeyan Naijiria ti ọjọ ori wọn ko to ọdun marundinlogoji, ti wọn si n fi oju sọna fun igbe aye to dara amọ ti wọn n jijagudu pẹlu eto ẹkọ lọwọ.

Olusegun Obasanjo ati Ooni Ogunwusi

"Ọpọ wọn gan ni ko ni anfaani si ẹkọ iwe, to si jẹ pe aisi anfaani lati se rere ti da irẹwẹsi si awọn ọdọ to kawe lọkan, o si yẹ ko ye wa pe o di dandan ki wọn si ideri lori omi to n ho naa."

"Amọ mo mọ pe ọpọ anfaani lo wa fun ijọba lati samulo rẹ lori ipese idẹrun fun awọn ọdọ, aarẹ, gẹgẹ bii baba orilẹede ati awọn ọdọ, to si ni ọmọ tirẹ, o yẹ ko mọ bi awọn ọdọ ti le huwa."

Nigba to wa n fesi, Ọba Ogunwusi ni iwọde yii jẹ ọna lati fi isẹ ransẹ sijọba pe awọn ọdọ naa lee se nnkan lọna to dara.

Olusegun Obasanjo ati Ooni Ogunwusi

"Ta ba wo iwọde naa, a ri pe awọn ọdọ ti gba akoso orilẹede yii, lati ọjọ akọkọ iwọde, si ni wọn ti se afihan pe awọn ni abuda asaaju rere.

Bakan naa ni wọn n jiyin isẹ iriju wọn laarin ara wọn, ti wsn si n se ojuse to yẹ, eyi to n paroko fun ijọba nipa bawọn ọdọ ilẹ yii ti dangajia to."

Ọba Ogunwusi wa rawọ ẹbẹ sawọn ọdọ naa lati jeburẹ, ki wọn si duro de ohun ti ijọba fẹ se lori ibeere wọn.