Harry Akande: Makinde, Dele Momodu ń ṣèdárò Àgbà Oyè Ilẹ̀ Ibadan, Harry Akande tó jáde láyé

Oríṣun àwòrán, AFriTVOnline
Awọn eekan ilu ti bẹrẹ si ni ṣe idaro gbajugbaja olokoowo ati Agba Oye ilẹ Ibadan to di oloogbe, Oloye Harry Akande.
Ninu ọrọ ibanikẹdun tiẹ, Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ṣe apejuwe iku Oloye Akande gẹgẹ bi adanu nla fun ipinlẹ Oyo ati fun orilẹede Najiria lapapọ.
Makinde sọ ninu ọrọ ibanikẹdun to fi ranṣẹ si idile oloogbe naa pe ilẹ Ibadan ati ipinlẹ Oyo ti padanu eeyan nla mii.
- Tí a bá yọwọ́ àwọn ọba alayé kúrò, kò ní sí Nàìjíríà mọ́- Alaafin Oyo
- Díẹ̀ ló kù kí ọjọ́ ìkúnlẹ̀ di ọjọ́ ikú fún ìyá mi lọ́jọ́ tó bí mi - Seyi Makinde
- Àwọn èèkàn ìlú péjú s'Ibadan níbi ìsìnkú màmá Omotola àkọ́bí obìnrin Awolowo tó wọ káà ilẹ̀ lọ
- Kò bá àṣà wa mu kí obìnrin máa kó ọmú síta! ẹ̀ báà bú mi di ọ̀la - Ọ̀gá Amotekun l'Osun
- Àwọn èèkàn ìlú péjú s'Ibadan níbi ìsìnkú màmá Omotola àkọ́bí obìnrin Awolowo tó wọ káà ilẹ̀ lọ
Ninu atẹjade ti akọwe iroyin fun Gomina ipinlẹ Oyo, Taiwo Adisa fi sita lorukọ Gomina, Makinde gbadura pe ki Eleduwa tẹwọ gba Akande, ki O si tu awọn ẹbi rẹ ninu.
Makinde sọ pe ipinnu Oloye Akande lati wọ agbo oṣelu Naijiria lo fun ọpọ oniṣowo ni igboya lati dije fun ipo osẹlu ni Naijiria bayii.
Bakan naa, ilumọọka oniroyin, Dele Momodu gboṣuba fun Agba Oye ilẹ Ibadan ninu ọrọ to fi lede loju opo Twitter rẹ.
Momodu ni Oloye Akande fi imura bi ẹni n rode pawọn ku nilẹ Amẹrika.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
O ni Oloye Akande ni alawolodu bi iyere ọmọ ilu Ibadan keji ti yoo jẹ ọlọrun ni pe lọdun 2020 yii lẹyin ti Parakoyi, Oloye Bode Akindele ti kọkọ ku.

Oríṣun àwòrán, Olumide Akande
Àgbà Oyè Ilẹ̀ Ibadan, Harry Akande ti jáde láyé
Harry Akande ti o jẹ gbajugbaja Olokoowo ati Agba Oye ilẹ Ibadan ti di oloogbe.
Akande ṣe alaisi l'ọjọ Abamẹta lẹni ọdun mẹtadinlọgọrin lẹyin aisan ranpẹ.
Oloye Harry Ayoade Akande gbe aye rẹ laarin ọjọ kẹta oṣu kẹta ọdun 1943 si ọjọ karun oṣu kejila ọdun 2020.
Oloye Harry Akande jẹ gbajumọ oniṣowo nile ati lẹyin odi Naijiria.
O ti gbe apoti ibo lati dije du ipo aarẹ orilẹede Naijiria ri.
Awọn mọlẹbi oloogbe ni iku iroyin iku rẹ ba awọn lojiji gẹgẹ bi Olumide Akanbi ṣe fi ọrọ sita lorukọ ẹbi.













