Oyo NURTW-PMS Crisis: Àwọn ọ̀dọ́ fi ẹ̀hónú hàn lọ sọ́dọ̀ Seyi Makinde lórí wàhálà awakọ̀ èrò

Agbegbe Iwo Road ni Ibadan

Oríṣun àwòrán, Screen Shot

Se ni ọrọ tun di boolọ, koo yago fun mi ni irọlẹ Ọjọru oni ladugbo Iwo Road nilu Ibadan, nigba ti ohun gbogbo dẹnu kọlẹ, ti awọn eeyan si n sa asala fun ẹmi wọn.

Gẹgẹ bi iroyin to n tẹ wa lọwọ ti wi, awọn ọmọ igbimọ to n se akoso gareeji ọkọ, PMS, eyi ti Alhaji Mukaila, ti ọpọ eeyan mọ si Auxilliary ko sodi, ni wọn fija pẹẹta pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ́ awakọ NURTW, tijọba ipinlẹ Oyo ti fi ofin de.

Bi o tilẹ jẹ pe ko tii si ẹni to le sọ ohun to fa isẹlẹ naa, amọ se ni iro ibọn n dun lakọ-lakọ lagbegbe naa, ti ọrọ si di ẹni ori yọ, o dile.

Àkọlé fídíò, Baba Ijesha Rape Case: Yomi Fabiyi ní òun nìkàn lòun rí ara òun tó dúró tí Baba Ijesha

Gẹgẹ bi ẹnikan ti isẹlẹ naa soju rẹ se salaye fun BBC Yoruba, o ni kawọn to sẹju pẹ, oku meji ti sun nitori isẹlẹ naa.

Bakan naa lo fidi rẹ mulẹ pe se ni awọn igun mejeeji to n kọju ija sira wọn ọhun fọ awọn eroja foonu olowo iyebiye tawọn ontaja n ta nikorita Iwo Road.

Awọn eroja ti wọn bajẹ ni Iwo Road

Oríṣun àwòrán, Screen Shot

Bẹẹ lo ni wọn ba gbogbo ohun ti wọn fi n patẹ ọja wọn jẹ, ti ekufọ igo si kun ilẹ kaakiri agbegbe naa.

Koda, awọn ọdọ ti inu n bi lori isẹlẹ naa ati ẹmi to ba rin, gbe eeyan kan to fara gba ọgbẹ lasiko ti rogbodiyan naa n waye lọ si ọgba Secretariat nilu Ibadan.

Awọn ọdọ naa ti wọn pọ niye, lo duro siwaju ọọ fisi gomina, ti wọn si n pariwo pe awọn fẹ ki gomina Seyi Makinde wa wo itu tawọn eeyan Auxillary pa ni Iwo Road.

Àkọlé fídíò, Ẹ̀yin olórin ẹ̀mí tó ń bóra, lo èékáná gígùn, oò yàtọ̀ sí aṣẹ́wó hòtẹ́ẹ̀lì tí wọ́n ń gbé bíi súùtì Pepper Menti - Bola Are

Amọ titi di igba ta fi n ko iroyin yii jọ, Gomina Seyi Makinde ko yọju rara si awọn ọdọ naa.

Wayi o, wọn ti ko awọn ọmọ ikọ digboluja Operation Burst ransẹ si Iwo Road lati da alaafia pada si agbegbe naa.

Nigba ti BBC Yoruba kan si agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo lati mọ ohun to sokunfa rogbodiyan ọtun yii, wọn ko ti fesi si ibeere wa ta fi ransẹ.