Ija laarin awon ọmọ ẹgbẹ awakọ NURTW ni Idumọta ti gbẹmi eeyan kan

Nnkan o rọgbọ ni agbegbe Idumọta ni Lagos Island nipinlẹ Eko lẹhin ti awọn apaniyan dẹmi ọmọkunrin kan ti wọn n pe orukọ rẹ ni Alnold Swagger aka "Pero" legbodo.
Iku rẹ ko sẹhin awuyewuye lori ija ti o wa laaarin awọn ọmọ ẹgbẹ awakọ ti ẹka Lagos Island.
Awọn ẹlẹri-osojumi salaye fun BBC wi pe awọn apaniyan kan dẹnu ibọn kọ ọkọ ayọkẹlẹ Alaga ẹgbẹ, Kunle Poly,ti wọn si yin in nibọn loru ọjọ isẹgun laimọ wi pe Alaga (Kunle Poly) ko si ninu ọkọ ayọkẹlẹ rẹ sugbọn ọmọlẹhin rẹ kan, Swagger ko agbako yi ti o ku lẹsẹkẹsẹ ti awọn meji miran si fara gbọta ninu ijamba naa.

Isẹlẹ yi sokunfa bi awọn onisowo asọ ni agbegbe naa ati awọn eleto ọrọ aje gbogbo se palẹmọ mọ lọgan ti wọn si tilẹkun ṣọọbu wọn.
Nigbati ikọ BBC Yoruba se abẹwo si ibi ti isẹlẹ naa ti sẹ lọjọru, ọpọlọpọ awọn ikọ ọlọpa lo wa ni gbogbo ayika Idumọta.
Ọkan lara awọn ọlọpa ti o ba wa sọrọ ti ko fẹ ki a darukọ oun salaye wi pe ọga ọlọpa ipinlẹ eko ti pasẹ fun awọn lati wa si agbegbe naa fun igbofinro ati lati pese aabo to peye fun awọn olugbe pẹlu onisowo. O wi pe iku ọkan pataki lara awọn ọmọ ẹgbẹ awakọ ti ẹka Lagos Island, ti o tun jẹ oluranlọwọ fun Alaga Kunle Poly lo se okunfa isẹ pajawiri fun awọn ọlọpa.

Oríṣun àwòrán, AFP
Diẹ ninu awọn oniṣowo ti o sọrọ pẹlu BBC ni agbegbe naa n parọwa si Gomina Akinwumi Ambode lati dẹkun wahala ati iṣoro to nwaye ninu ẹgbẹ NURTW, Lagos Island ki alaafia le jọba.








