Tinubu: Àìmọsẹ́ dé òjú àmì ló fa ìkọkúkọ tí àwọn kan n kọ nípa Bola Tinubu- BAT

Nǹkan ti a mọ nípa ìlera Asiwaju Ahmed Tinubu

Oríṣun àwòrán, BAT

Lòdì sí ariwo tó gbòde kan pé Asiwaju Bola Ahmed Tinubu wà lórí àkéte àìsàn tó ṣí wà ni ilé ìwòsàn, bàbá ti wọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lánàá òde yìí.

Ìròyìn sọ pé àgbà ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressive Congress kan lọ fún ìsìnmi ránpẹ́ ni gẹ́gẹ́ bi olùdásílẹ̀ ẹgbẹ́ Bola Ahmed Tinubu (BAT) ṣe sọ.

Alẹ́ ọjọ́ Isegun ni Asiwaju wọ ìlú lẹ́yìn wákàtí díẹ̀ ti òkìkí kàn pé ìlera rẹ̀ mẹ́hẹ àti pé òun gba ìtọ́jú nílé ìwòsàn kan tí àwọn fi orúkọ bò láṣìrí nílẹ̀ òkèrè.

Àkọlé fídíò, Ṣé ìrìnàjò nínú ọkọ̀ Reluwé Ibadan-Lagos-Ogun tuntun bá aráàlù lára mu? Èsì rèé

Sùgbọ́n Lẹ́yìn náà ni amúgba lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ tó jẹ́ olórí BAT Abiodun Ajiboye sàlàyé pé, iṣẹ́ ọwọ́ àwọn tí kò kọ́sẹ́ mọsẹ ló kọ irí ìròyìn bẹ́ẹ̀ àti pé àhesọ lásán ni wan ń sọ.

" Láti mú iyèméjì kúrò, Asiwaju ní ilé ìwòsàn tó forúkọsílẹ̀ sí ní ilẹ̀ gẹ́ẹ̀sì àti onísègùn rẹ̀ ti ọ̀pọ̀ mọ ìtàn nípa rẹ̀" ìbéèrè tẹ̀mi ni pé, ibo ni ilé ìwòsàn tí wọ́n kò le dárúkọ"

"Kókó tó wà níbẹ̀ ni pé, ènìyàn tó wà ni ọjọ́ orí Asíwáju, ẹni ọdún mọ́kàndáláádọ́rín nílò láti máárín dókìtà rẹ̀ fún àyẹ̀wò láti ìgbà dé ìgbà."

Tinubu: Kokoko ni ara baba le

Oríṣun àwòrán, BAT

Mo rọ gbogbo ènìyàn láti kọ etí ikún sí ìròyìn òfégè tó n lọ káàkiri nípa ipò ìlera Asiwaju, nitórí pé kokoko ni ara baba le, wọn yóò sì dé láìpẹ́.

Kò pé sí àsìkò tí àtẹjáde BAT yìí jáde ni fótò àti àwọn fọ́ràn Asiwaju Bola Ahmed Tinubu bẹ̀rẹ̀ sí ni ṣẹyọ pé ó ti pada dé sórilẹ̀ èdè Nàìjírá.

Tinubu: Kokoko ni ara baba le

Oríṣun àwòrán, BAT

Ọ̀kan nínú àwọn amúgbálẹ́gbẹ̀ rẹ̀ tí wọ́n jọ kọwọ̀ọ́rin rin ìrìnàjo sọ fún oníròyìn pé nǹkan bi aago méje alẹ́ ànà ni Asiwaju balẹ̀ kí ìròyìn pé Tinubu wà nilé ìwòsàn tó de ẹ̀ka ètò ìròyin Tinubu.

"A balẹ̀ ni ìṣẹ́jú díẹ̀ sẹ́yìn, ṣùgbọ́n sáájú àsìkò yìí ati wa lójú òfurufu láàrín orílẹ̀-èdè yìí, mo sì le fi gbogbo ẹnu sọ pé ọkùnrin tí ẹ n bèrè yìí, ara rẹ le kòkò ju àwa ti a tẹ̀lé wọn rìn ìrìn àjò lọ.

Sáájú àsìkò yìí ní ọ̀pọ̀ ọmọ Nàìjíríà tí ke gbàjarè pé níbo ni Asiwaju Bola Ahmed Tinubu wà? nítorí tí kò péjú síbi ètò ìfilọ́lẹ̀ Reluwe tuntun ti ààrẹ Muhammadu Buhari wa ṣe ni ìpińlẹ̀ Eko lọsẹ̀ tó kọja.

Ọjọ́ márùblélagbọ̀n oṣu kaarùn ọdún yìí ni a ti ri gómìnà ìpińlẹ̀ Eko tẹ́lẹ̀ ri Bola Tinubu ni gbangba ìta gbẹ̀yìn