JAMB: Àwọn nkán tí akẹ́kọ̀ọ́ gbọ́dọ̀ mọ̀ láti lè wò èsì ìdánwò JAMB tó jáde

jamb utme e-slip: Jamb ti rọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti láti parí ìforúkọsílẹ̀ lónìí ọjọ́ ìṣẹ́gun

Oríṣun àwòrán, Jamb

Ajọ eleto idanwo igbaniwọle si fasiti ni Naijiria JAMB ti kede esi idanwo igaradi t'awọn akẹkọọ kọ ṣaaju ojulowo idanwo igbaniwọle.

Alukoro ajọ ọhun Fabian Benjamin lo fi ọrọ yi si'ta ninu atẹjade kan lỌjọru nilu Abuja.

O ni:"Esi idanwo igbaradi t'awọn akẹkọọ kọ lọjọ Kẹta osu Kẹfa ti jade soju opo wa."

Idanwo igbaradi yi jẹ eleyi ti JAMB a máa seto lọdọọdun k'awọn akẹkọọ baa le gbaradi daadaa de idanwo gangan.

Idanwo yi a tún máa jẹ kí akẹkọọ mọ nipa awọn ibeere igbaradi iru awọn iṣẹ to rọọrun fun lati ṣe.

Atẹjade Jamb yi sọ bakan naa pe:"ninu apapọ akẹkọọ 160,718 to ṣafihan pe awọn fe kopa ninu idanwo naa, 62,780 lo pada yọjú lati joko kọ idanwo naa t'awọn gbe esi rẹ jáde."

Idanwo igbaradi yi kii ṣe dandan. Ẹni to ba wu lo le kopa.

Ko si ni kí eeyan ma kopa ninu ojulowo idanwo bi ko ba b'awọn joko idanwo igbaradi.

Àkọlé fídíò, Ṣé ìrìnàjò nínú ọkọ̀ Reluwé Ibadan-Lagos-Ogun tuntun bá aráàlù lára mu? Èsì rèé

Fabian Benjamin ti wa rọ àwọn akẹkọọ lati kan sí ojú òpó Jamb lati le wo esi idanwo naa.

Àwọn nkán tó yẹ kó mọ nípa wiwo esi idanwo igbaradi yi:

Kọkọ lọ sí oju opo www.jamb.gov.ng

Tẹle aṣẹ to wa nibe kò sí wo aaye anfaani to wa nibe.Kan si eleyi ti won pe ni Intranet login.

Bo ba je igba akọkọ rẹ lati wọlé si aaye yi,oruko ti waa fi wọlé ni 'code' rẹ ti 'password' rẹ yoo sì jẹ nọmba NIN rẹ.

O máa nilo lati kọ password' mi yi wa fi wọlé s'awọn aye miran.

Profile code rẹ ni waa si lo gẹgẹ bí orukọ idanimọ ìwọlé user name.

Lati le tẹ iwe pelebe esi idanwo rẹ jáde,kan soju opo yi https://portal.jamb.gov.ng/ExamSlipPrinting/PrintMockExaminationSlip

Tẹ nọmba iforukọsilẹ JAMB rẹ sibẹ tabi adiresi imeeli rẹ síbi tó bá yẹ.

Waa tẹ sibẹ pe kí o tẹ iwe pelebe esi idanwo re jade.Lobatan.

Ojulowo idanwo igbaniwọle JAMB yoo waye ni ọjọ Kokandinlogun oṣù Kẹfà ati ọjọ Kẹta oṣù Keje.

Ìdí ni pe JAMB sunmọ idanwo naa siwaju nitori awọn akẹkọọ to ni iṣoro lati forukọsilẹ pẹlu nọmba idanimọ (NIN).

Ọgá agba àjọ naa (JAMB) ọjọgbọn Ishaq Oloyede,sọ pe ìdí t'awọn fi ni ki awọn akẹkọọ máa lo nọmba idanimọ NIN ni lati fi dẹkùn mago-mago lasiko idanwo.

Jamb ti rọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti parí ìforúkọsílẹ̀ lónìí ọjọ́ ìṣẹ́gun

Àjọ tó n mójutó ìdánwò àṣewọlé sí ilé ẹ̀kọ́ fásitì (JAMB) ti gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ti ọ̀rọ̀ wọn ti níyànjú nipa ìforúkọsílẹ̀ ìdánwò (UTME) 2021 láti sàbẹ̀wò si gbọ̀ngán ìdánwò ni ọjọ́ Isegun ọjọ́ ikẹ̀ẹ́dógún fún awọn ètò tó kù.

Ìmọ̀ràn yìí wà fún àwọn olùṣe ìdánwò tí wọn kò tíí ṣe ìforúkọsílẹ̀ tán láàrín àsìkò tí wọ́n dá fún wọ́n tẹ́lẹ̀.

Jamb ṣe ìkéde yìí nínú àtẹjáde kan ti agbẹnusọ àjọ náà Fabian Benjamin fọwọ́sí lọ́jọ́ ajé ọjọ́ kẹrinla, ọdún 2021.

Benjamin sọ pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ti wọ́n ko orúkọ wọn jọ lẹ́yìn tí wọ́n mú ẹ̀sùn wá pé àwọn kò rí ìforúkọsílẹ̀ ṣe, àwọn wọ̀nyí ló gbọdọ̀ ṣe àbẹ̀wò sí gbọ́ngán yìí.

"Lẹ́yín tí àsìkò tí Jamb dá tẹ́lẹ̀ láti fòpin sí iforúkọsílẹ̀ fún ìdánwò UTME 2021/2022 lọ́jọ́ kẹẹ̀dógun oṣù kárún, wọ́n tún sún àsìkò náà síwájú".

"Ọ̀sẹ̀ méjìí mííràn tún gorí rẹ̀ ní ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù karùn láti fún àwọn tí kò le pari ìforúkọísíẹ́lẹ̀ nítorí ọ̀rọ̀ ìfòrúkọsílẹ̀ nọ́mbà ìdánimọ̀. Oṣẹ̀ méjì mííràn tún bo fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mííràn tó sì tún sọ pé àwọn kò rí ìforúkọsílẹ̀ ṣe nítorí ìdí kan tàbi òmíràn".

Benjamin ni àwọn tí kò tíì forúkọ sílẹ̀ sùgbọ́n tí wọ́n ti wọ́n ti gba kóòdù tàbi tí wọn ti bẹ̀rẹ̀ ètò ìforúkọsílẹ̀ náà ló yẹ kí wọ́n lọ sí gbọ̀ngán láti pari ìforúkọsílẹ̀ wọn lónìí, ọjọ́ Isegun ọjọ́ kẹdóógun oṣù kẹfa, 2021.

Ó ni àwọn gbọ̀ngán yìí ni wọ́n ti fi sọwọ́ sí wọ́n tẹ́lẹ̀ pẹ̀lá àtljáisẹ lórí fóònù wọn tàni kí wọn wo ojú opó atagbà JAMB pẹ̀lú àdírẹ̀sì ìsàlẹ̀ yìí: Forukọsilẹ fun idanwo JAMB nibi

Ààyè wà láti ṣe èyí láti aago méjìlá ọ̀sán ọjọ́ Aje ọjọ́ kẹrinla, oṣu kẹfa.

Àkọlé fídíò, 'Ọwọ́ mi ti ń jẹ́rà ká tó mọ̀ pé àfi kí wọ́n tún gé e bí mo bá ṣì fẹ́ máa ṣe iṣẹ́ awakọ̀ lọ'

Àwọn tó ti ni cóòdù nìkàn ni tí wọ́n sí ti fi orúkọ sójú òpó náà sùgbọ́n tí wọn kò tíì rí ìforúkọsílẹ̀ nìkàn ni ko lọ si ibi gbọ̀ghán náà.

Bákan náà ni àwọn kọ̀kan ti wọn kò tíí ri NIN wọn gbà tabi rii kóòdu ṣe ni àwọn ti fi orúkọ wọn sọwọ́ si àjọ NIMC wọ́n yóò sì kàn sí wọ́n ni kété tí NIMC bá ti pari ètò nípa wọn.

Gbogbo akẹ́kọ̀ọ́ tí yóò lọ sí àwọn gbọ̀ngan tí ìforúkọsílẹ̀ yìí gbọdọ san ẹgbẹ̀rún kan náira fún àwọn alábolju tọ gbọ́ngan naa fuin CBT. Ọ̀rọ̀ Benjamin rèé.

Tí ẹ ò bá gbàgbá, ọjọ́ kaarun si ọjọ́ ọjọ́ kọkandílógún oṣù kẹfa àti ọjọ́kọkandinlolgun oṣù kẹfa sí ọjọ́ kẹta oṣù keje ọdún 2021 ló yẹ ki ìdánw['o náà wáye tẹ́lẹ̀ láti fààyè gbà àwọn tí ọ̀rọ̀ NIN dí lọ́wọ́ láti 'se bẹ́ẹ̀