June 12 Protest: Ó yẹ kí ọlọ́pàá tọrọ àforíjì lọ́wọ́ àwọn olùwọ́de tí wọ́n mú ní June 12 - Falana

June 12 Protest: Ó yẹ kí ọlọ́pàá tọrọ àforíjì lọ́wọ́ àwọn olùwọ́de tí wọ́n mú ni June 12- Falana

Agbẹjọ́rò àgbà ni Nàìjíríà, Ọ̀gbẹ́ni Femi Falana ti ké sí àwọn ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá láti tọrọ àforíjì lọ́wọ́ àwọn olùwọ́de tí wọ́n mú lọ́jọ́ June 12 jákèjádò Nàìjíríà.

Falana ni àwọn ọlọ́pàá tẹ ẹ̀tọ́ àwọn ará ìlú tó fi aayè gbá fífí èrò ẹni hàn mọ́lẹ̀ ní.

" Ó ṣe pàtàkì kí ọlọ́pàá máa bọ̀wọ̀ fún ẹ̀tọ́ ará ìlú. Ó jẹ́ nǹkan tó jìnà sí ìwà ọ̀làjú kí ọlọ́paàá m'Áa lé àwọn olùfẹ̀hóinúhàn tí kò mú nǹkan ìjà lọ́wọ́ lójú pópó bí ọ̀daràn.

Falana fi èrò yìí hàn nínú ìwé aapárò tó fi síta lọ́jọ́ Aikú.

Àkọlé fídíò, 'Sister Tope Alabi yà mí lẹ́nu gan o pé "Oniduro mi" kìí ṣe orin tó yẹ kí ọlọ́run fún mi'
Àkọlé fídíò, Bí wọ́n ṣe ya Sinima Ayinla Omowura rèé, BBC Yorùbá fọ̀rọ̀ wá àwọn òṣèré lẹ́nu wò

Ẹ̀wẹ̀, ọ gbóríyìn fún àwọn olùfẹ̀hónúhàn náà bí wọ́n ṣe hùwà ọmọlúàbí tí wọ́n sì ṣe gbogbo nǹkan tí wọ́n yóò ṣe ni ìrọwọ́rọsẹ̀.

Ọ̀gbẹ́ni Falana bẹ̀nu àtẹ́lu àwáwí àwọn ọlọ́pàá pé àwọn lo tajútaju níbl láti fi dẹ́rùba àwọn jàndùkú kí má ba lé já ìwọ́de náà gbà mọ́ wọ́n lọ́wọ́.

Ajàfẹ́tọ ọmọniyàn náà rọ àwọn olùwọ́de kí wọ́n rIi dájú pé wọ́n ti sọ fún ọlọ́pàá lati gba ìyọ̀nda sáájú àsìkò ìwọ́de gẹ́gẹ́ bí òfin ṣe sọ.

Sáájú ni àgbẹnusọ ọlọ́pàá, Frank Mbba sọ lórí ètò ilé ìròyìn Channels pé àwọn gbé ìgbésẹ̀ láti lo tajútajú láti tú àwọn olùwọde, tó sì fi ìdí rl múlẹ̀ pé, ìgbásẹ̀ náà bá ètò àti ìlànà bí wan ṣe n ṣe lágbàyé mu.

Àwọn ọlọ́paàá fí tajútajú tú àwọn olùwọ́de ká ni Eko àti ìlú Abjua ní ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn oníròyìn kò rí ohun kóhùn tó farapẹ́ jàgídíjàgàn láàrín àwọn olùwọ́de lásìkò ìwọ́de ki àwọn ọlọ́pàá tó da gbogbo rẹ̀ rú.

Ẹ̀wẹ̀, ọ̀gbẹ́ni Mba sàlàyé pé, nǹkan tó ṣẹ̀lẹ̀ ni Abuja yàtọ àti pé àwọn ni láti lo tájutajú lásìkò tí ìwọ́de ti fẹ́ dá wàháà sílẹ̀ l'Abuja.

Ó ni báyìí ni wọ́n ṣe ń ṣe noi gbogbo àgbáyé, yálà ni Abuja Paris tàbi London. nǹkan ti a le ṣe tí o lé mú wàhálà dáni ni ti ọlọ́pàá bá yin ẹnikan ni ìbọn.

" Mọ fẹ́ fi dá yin lójú bákan náà pé, kò sí ẹnikẹ́ni yálà ni Kwara, Eko, Port Harcout, Kano tabi ni ibikibi tí ó wà ni àtìmọ́lé ọlọ́paàá nítori ìwọ́de June 12.

Àkọlé fídíò, 'Nínúu ká ṣe oríire níbí tàbí káa kú'! Àwọn tó ń fẹsẹ̀ rìn sálọ orílẹ̀èdè míì ṣe fídíò ráńṣẹ́ sílé