Tope Alabi ti Tolu Adelegan síbi ògò rẹ̀ ni bó ṣe bu ẹnu àtẹ́ lu orin Oniduro mi - Èsì tó ń jáde sí Tope

Tope Alabi, Adelegan, Alayesori

Oríṣun àwòrán, Tope Alabi, Adelegan, Alayesori

Olorin ẹmi kan to fi ilu Akure ṣe ibugbe, Ajihinrere Tolu Adelegan, lo ti sọrọ nipa bi o ṣe gba imisi orin "Oniduro" ti o n fa awuyewuye lori ẹrọ ayelujara lati bii wakati mejidinlaadọta sẹyin.

Awuyewuye ọhun lo bẹrẹ lẹyin ti gbajugbaja olorin ẹmi, Tope Alabi, fẹnu tabuku orin naa pe o tako ọrọ Ọlọrun.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu ile iṣẹ iroyin BBC Yoruba, Adelegan wipe ohun gba imisi orin yii lasiko ti awon ẹgbẹ Akọrin rẹ n ṣe igbaradi orin kikọ ni ọdun 2014 atipe lẹyin naa ni ẹmi mimọ tun dari oun lati kọ ọ nibi ipade itagbangba kan lẹyin eyi.

Àkọlé fídíò, 'Sister Tope Alabi yà mí lẹ́nu gan o pé "Oniduro mi" kìí ṣe orin tó yẹ kí ọlọ́run fún mi'
Àkọlé fídíò, Baba Ijesha Rape Case: Yomi Fabiyi ní òun nìkàn lòun rí ara òun tó dúró tí Baba Ijesha

"Lọgan ti mo rii pe Yinka Alaseyori ti ṣe ẹda orin mi sita ni mo fi ẹjọ rẹ sun Bisi Alawiye ati Bukola Akinade (Ṣẹnwẹlẹ Jesu) ti wọn jẹ atọnisọna fun Alaseyori, dipo ki n wọ iyaaja pẹlu rẹ".

Adelegan wipe Alawiye ati Akinade ni wọn panupọ ba Alaseyori wi pe ohun kọ lo lorin, bi kii ṣe Adelegan.

Olorin ẹmi to fi ilu Akure ṣebugbe ọhun ṣalaye fun BBC Yoruba pe Ọlọrun lo fun oun ni imisi orin ọhun to si wipe ki oun gba alaafia laaye nigba ti Alaseyori ṣe ẹda orin naa.

Àkọlé fídíò, Ẹ̀yin olórin ẹ̀mí tó ń bóra, lo èékáná gígùn, oò yàtọ̀ sí aṣẹ́wó hòtẹ́ẹ̀lì tí wọ́n ń gbé bíi súùtì Pepper Menti - Bola Are

"Mi o ba Alaseyori ja toripe ọmọ ti mo julọ lọjọ ori ni, amọ mo fi ẹjọ rẹ sun awọn to ju wa lọ nidi iṣẹ orin ẹmi ki wọn ki i nilọ, mo si tun fi si ori ẹrọ facebook. Bakan naa ni Ọlọrun sọ fun mi pe ki n fi ọwọ lẹran pe ọjọ ọrọ o tii to, titi di ana ti Ọlọrun pada sọ fun mi pe ki n sọrọ soke pe ohun yoo ṣe atilẹyin fun mi."

Adelegan ti ko fibẹẹ mọ pe orin olorin ṣee gbe sita tẹlẹ gẹgẹ bo ṣe sọ ni "mo ṣẹṣẹ mọ nipa bi a ṣe n daabo bo iṣẹ ọpọlọ ni. Mo si ti ṣetan lati ṣiṣẹ le e lori. Koda, ogidi iṣẹ ọhun ṣi wa nibi ti wọn ti poo pọ."

Àkọlé fídíò, King Sunny Ade's son: Ohùn orin bàbá mi nìkan kọ ni l’Ọlọrun fún mi, ijó bíi kòkòrò ni ṣáá
Àkọlé fídíò, Bí wọ́n ṣe ya Sinima Ayinla Omowura rèé, BBC Yorùbá fọ̀rọ̀ wá àwọn òṣèré lẹ́nu wò