Toyin Lawani: Kílódé tí ariwo ìgbéyàwó Toyin ṣe fa orí ayélujara ya?

Kílódé tí ariwo ìgbéyàwó Toyin Lawani ṣe gba orí ayélujara kan?

Oríṣun àwòrán, Tiannahsplace

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Toyin Lawani to jẹ́ gbajugbaja onísòwò ṣe ìgbéyàwo lánàá tíi ṣe ọjọ́ kejìlá, oṣù kẹfà ọdún 2021, ayé gbọ́ ọ̀run mọ̀.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ohun málegbàgbé ló súyọ níbẹ̀, lára rẹ̀ ní akọlé ti Toyin Abraham gbé jáde lórí ìkànsíraẹni Instaram rẹ̀ pẹ̀lé àkọ́lé lórí fótò Mercy Aigbe àti Iyabo Ojo.

Skip Instagram post, 1
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 1

Àkọlé fídíò, 'Sister Tope Alabi yà mí lẹ́nu gan o pé "Oniduro mi" kìí ṣe orin tó yẹ kí ọlọ́run fún mi'

Láti bíi oṣù díẹ̀ sẹ́yìn ní òkìkí tí ń kàn lórí ayélujára bí Toyin Lawani ṣe ń polongo pé, ìgbéyàwó tí òun fẹ́ ṣe yìí yóò yàtọ̀ sí gbogbo ìgbéyàwó tí àwọn ènìyàn tí ń ṣe láti ẹ̀yìn wá.

Lóòtọ́ ọjọ́ ayẹyẹ àyájọ òmìnira ìjọba àwa-arawa tí àwọn ọmọ Nàìjíríà ń wọ́ lójú pópó láti wọ́de ìfẹ̀hónúhàn lóríi bí ìlú ṣe rí lọjọ́ náà, Toyin Lawani àti olólùfẹ́ rẹ̀ tuntun lo ọjọ́ náà láti bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò ìdílé.

Tani Toyin Lawani?

A bi toyin Lawani ni ọjọ́ kini, oṣù kẹta, ọdun 1982 ní ìpińlẹ̀ Ekiti, O jẹ́ gbájúgbajà jùlọ nínú àwọn aṣe aṣọlọ́ṣọ̀ọ́ ní Nàìjíríà.

Ọmọ gbajugbaja olóṣèlú Olarewaju Lawani tí bàbá rẹ̀ sì ti bá ológun Gowon ṣiṣẹ́ nígbà ayé rẹ̀, tí ìyá rẹ̀ pẹ̀lú Atinuke Babalola sì jẹ́ onísòwò irun ṣíse àti aṣọ títa nílùú Amerika kí ó tó papòdà.

Àkọlé fídíò, Bí wọ́n ṣe ya Sinima Ayinla Omowura rèé, BBC Yorùbá fọ̀rọ̀ wá àwọn òṣèré lẹ́nu wò

Oníruuru òwò ní Toyin ń ṣe tí ó sì ti làmìlaaka níbẹ̀. Gẹ́gẹ́ bi gbájúgbàjà òun ṣe sọ, Toyin Lawani ni òun ń ṣe owo tó lé ni ọgbọ̀n lábl Olrùlé kan náà tó pè ni "Tiannah's Empire".

Toyin Lawani lọ sí fasiti Unilag níbi tí ó ti ka ìmọ̀ nípa ìròyìn, lẹ́yìn náà ló tún lọ sí fasiti ìlú Eko láti ka imọ èdè òyìnbó láti mú inú bàbá rẹ̀ dùn.

Ní kété tó ṣe èyí tán ló padà síní nǹkan tó yàn láàyò, èyí tí ṣe mímú nǹkan rẹwà, àti ṣíṣe aṣọ lógé.

Kílódé tí ariwo ìgbéyàwó Toyin Lawani ṣe gba orí ayélujara kan?

Oríṣun àwòrán, Tiannahsplace

Báyìí ni ọ̀pọ̀ ń bẹ̀rẹ̀ sí ni gbé iṣẹ́ fún, láti ibẹ̀ lọ ló ti dí ẹni tọ n rán àṣọ fún àwọn èèyàn jánkanjànka àti àwọn ọ̀tọ̀kùlú láwùjọ.

Lábẹ́ òrùlé kan ní Toyin ti ń ṣe ilé ìkọ́ṣẹ́ aṣọ rírán, ilé òunjẹ́ ìgbàlódé, ilé iṣẹ́ tó n tún ara tò, (SPA) , ilé iṣẹ́ tó n bá ènìyàn gba ìwé ìrìnàjò.

Àkọlé fídíò, 'Nínúu ká ṣe oríire níbí tàbí káa kú'! Àwọn tó ń fẹsẹ̀ rìn sálọ orílẹ̀èdè míì ṣe fídíò ráńṣẹ́ sílé

Ẹ̀ẹ̀mélòó ni Toyin Lawani ti Lọ́kọ?

Toyin Lawani jẹ́ ìyá ọlọ́mọ méjì Tiannah àti Laord Maine fún bàbá méjì.

Ní ọ̀pọ̀ ìgbà Touin Lawani kìí ṣọ̀rọ̀ lórí ìgbéyàwó rẹ̀ àkọ́kọ́, sùgbọ́n ní nǹkan bi ọdún kan sẹ́yìn ló fí sójú òpó Instagram rẹ̀ pé kí àwọn ènìyàn wo bàbá àkọ́bi ọmọ òun.

O ní òun fẹ́ nígbà tí òun wà ní ọmọ ọdún mọ́kàndílógún, àti pé lásìkò náà òun ti ni oríṣi okoòwò márùn tí òun ń ṣe, bákan náà ni òun ń lọ sí ilé ìwé.

Nínú ìfọ̀rọ̀wáni lọ́nuwò kan ni Toyin ti ṣàlàyé bí ọ̀rẹ́ ṣe kó sí òun lọ́kan láti jáwe mí o ṣe ma fún ọkọ́ rẹ̀.

O ní ó máá ń fi ọ̀rọ̀ àbùkù ránṣẹ́ sí òun pé, ìnú ìgbáyàwó tí kò ni ayọ ni òun wà súgbọ́n òun ń ṣe bi ẹni pé inú òun dùn.

Gbogbo èyí ni òun rò papọ̀ tí oùn fi mú ọmọ tí òun bí ní àsìkò tí òun wà ni ọdún mẹ́tàlélógun kúrò nínú ìgbéyàwọ náà láti lọ bẹ̀rẹ̀ ìgbé ayé tuntun.

Ẹ̀wẹ̀, ó ni ọ̀rẹ́ tó gba òun nímọ̀ràn lásìkò náà ń kòjú nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ sí òun nígbà náà báyìí, sùgbọ́n kò kúrò nínú ìgbéyàwó ọ̀hún.

Kílódé tí ariwo ìgbéyàwó Toyin Lawani ṣe gba orí ayélujarakan?

Oríṣun àwòrán, Tiannahsplace

Lẹ́yìn èyí ló ṣe alábàpádé Kensington Womadi tí wọ́n ń pè ni Lord Trigg tó jẹ́ olórín, Trigg lo bí ọmọ rẹ̀ ọkùnrin fún.

Bí àwọn olólùfẹ́ méjèèjì yìí ṣe túka mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ aríwo dáni pẹ̀lú, gẹ́gẹ́ bi ìtàn náà ṣe lọ, Toyin Lawani fi ẹ̀sùn kan pé ifẹ́ owó lásán ni ọmọkunrin náà ní sí òun.

Kílódé tí ariwo ìgbéyàwó Toyin Lawani ṣe gba orí ayélujara kan?

Oríṣun àwòrán, Tiannah

Bákan náà ní àwọnm mííràn sọ pé ọ̀rọ̀ ìhẹ́ tó wà láàrín wọ́n forí sọ́pọ́n nítrorí ìyàtọ ọdún gbọọrọ tó wà láàrín àwọn méjèèjì (Toyin 1982 Triggs 1992).

Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan ti Lord Triggs ṣe lo ti sọ pé ọdún mẹ́rìn ni àwọn ti n bá ifẹ́ àwọn bọ̀, kò sí sí òtítọ́ nínú pé, nítorí owó ni òun 'se ń fẹ́ Toyin Lawani.

Kílódé tí ariwo ìgbéyàwó Toyin Lawani ṣe gba orí ayélujara kan?

Oríṣun àwòrán, Tiannah

Báwó ní ètò ìgbéyàwó ọkọ kẹta yìí ṣe bẹ̀rẹ̀?

Sáájú àsìkò yìí ní Toyin Lawani tí sọ fún gbogbo àwọn ènìyàn tó n fí òn ṣe ẹlẹ́yà pé òun bí ọmọ méjì fún bàbá méjì pé, kìí ṣe pé òun wu ònu bẹ́ẹ̀ bíkòṣe pé bí a ṣe kọ ọ́ fún òun ni.

Nínú oṣù kéjì ọdún yìí ní òkìkí kan lórí ayélujára pé Toyin Lawani tún fẹ́ dá ilé ọkọ wò lẹ́ẹ̀kan sí nígbà tí Segun Adebayo tó ṣe ùgbéyàwó pẹ̀lú yìí dá ẹnu ifẹ́ kọọ ní gbangba lọ́jọ́ àyájọ́ olólùfẹ́ ọdún 2021.

Lẹ́yìn èyí ní oníruurú ọ̀rọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ni jáde nípa Toyin Lawani àti ọkọ tuntun tí ó fẹ́ yìí

Sáájú àsìkò yìí àyàwòrán Toyin Lawani ni Segun Adebayo jẹ́ tí ọ̀pọ̀ sì máá n ké gbàjarè lórí àwọn fótò oníhòhò tí Toyin máá ń gbé sórí ayélujára.

Kílódé tí ariwo ìgbéyàwó Toyin Lawani ṣe gba orí ayélujara kan?

Oríṣun àwòrán, Tiannah

Láti àsìkò yìí ní ètò tí bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹwu. Ọ̀pọ̀ àwọn gbájugbajà òṣèré pẹ̀lú ló ń fọ́rere pé ìgbéyàwó náà yóò dùn gbọ́ngbọ́n yóò kan sí.

Toyin tikara rẹ̀ sọ pé pé àwọn àárùn ìyàwó òhún yóò tó àádọ́jọ ènìyàn pọ́lu ọ̀rẹ́ ọkọ méjì.

Bákan náà lo pe àkòrí ètò ìgbéyàwó wan ni #TheArtistAndHisMuse2021

Kílódé tí ariwo ìgbéyàwó Toyin Lawani ṣe gba orí ayélujara kan?

Oríṣun àwòrán, @segun_wealth

Lára àwọn ènìyàn jànkàjànkàn tó péjú síbi àyẹyẹ ìgbéyàwó náà ni Shina Peters, àwọn gbájúgbajà nínú èré tíatá, àwọn àdẹ́rìn pòṣọ́nú àti gbájúmọ̀ láwùjọ.

Lára àwọn nǹkan tó tún jọ àwọn ènìyàn lójú níbi àyẹyẹ náà ni pé, àṣọ aláwọ̀ dúdú ni aṣọ ẹbi tí wọ́n mú níbí ayẹyẹ náà.

Kílódé tí ariwo ìgbéyàwó Toyin Lawani ṣe gba orí ayélujara kan?

Oríṣun àwòrán, Tiannahs

Ìròyìn sọ pé, ọkùnrin tuntun ti Toyin Lawani fẹ́ yìí ni ìyàwó nílé sáájú àsìkò yìí, tí ó sì tí bí ọmọ méjì kí ó tó wá kẹnu ìfẹ́ sí Toyin.

Ọ̀kàn nínú nǹkan tó fí ìdí ọ̀rọ̀ yìí múlẹ̀ ní ọ̀rs kan tí Toyin kọ sójú òpó instagram rẹ̀ níbi tó tí sọ fún aya Segun pé kó lọ jòkó jẹ́ nítori òun lóun ni ọkọ báyìí.

Kílódé tí ariwo ìgbéyàwó Toyin Lawani ṣe gba orí ayélujara kan?

Oríṣun àwòrán, Tunezmediablog

Kílódé tí ariwo ìgbéyàwó Toyin Lawani ṣe gba orí ayélujara kan?

Oríṣun àwòrán, Tunezmediablog

Kílódé tí ariwo ìgbéyàwó Toyin Lawani ṣe gba orí ayélujara kan?

Oríṣun àwòrán, Tunezmediablog

Kílódé tí ariwo ìgbéyàwó Toyin Lawani ṣe gba orí ayélujara kan?

Oríṣun àwòrán, Tunezmediablog

Kílódé tí ariwo ìgbéyàwó Toyin Lawani ṣe gba orí ayélujara kan?

Oríṣun àwòrán, Tunemedikablog

Sááju ọjọ́ ìgbéyàwọ ni wọ́n ti ṣae fọ́ran kan jáde láti fí kí àwọn ènìyàn kú àfójúsọ́nà ìgbéyàwó wọn.

Kò tán síbẹ̀ o, àwọ dúdú ni àkàrà òyìnbó tí Toyin Lawani àti ọkọ rẹ̀ Segun Adebayo lò fún àyẹyẹ ìgbéyàwò wọ́n.