Netanyahu loses post in Israel: Agbára bọ́ lọ́wọ́ Benjamin Netanyahu, Naftali Bennett di olótú ìjọba tuntun ní Israel

Oríṣun àwòrán, Reuters
Olotu ijọba orilẹede Israel, Benjamin Netanyahu ti padanu ipo rẹ gẹgẹ bi olori ijsba orilẹede Israel lẹyin ti wọn dibo nile aṣofin lati gbe ijọba alajumọṣe tuntun wọle nibẹ.
Nibayii, wọn ti bura fun Naftali Bennett gẹgẹ bi olotu ijọba tuntun lorilẹede Israel.
Bennett kede ijọba tuntun naa gẹgẹ bi ijọba ayipada.
Ibo ọgọta si mọkandinlọgọta lawọn agbarijọpọ ẹgbẹ oṣelu alatako to parapọ fi gbe Netanyahu kuro nipo lẹyin ọdun mejila ni ipo naa.
Ọgbẹni Bennett yoo di ipo olotu ijọba orilẹede Israel mu titi di oṣu kẹsan an ọdun 2021 gẹgẹ bi ara eto fun iṣejọba alajumọ pin.
Lẹyin oṣu kẹsan ni yoo gbe agbara fun Yair Lapid, olori ẹgbẹ oṣelu Yesh Atid fun ọdun meji miran.
Ọgbẹni Netanyahu yoo ṣi wa ni ijanu oṣelu lorilẹede naa gẹgẹ bi olori ẹgbẹ oṣelu Likud Party lati di olori ẹgbẹ alatako.
Ta ni Naftali Bennett to ṣẹṣẹ di olotu ijọba ni Israel?

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ẹni ọdun mọkandinlaadọta ni Naftali Bennett, o dẹ ti fi igbakanri jẹ olori awọn o ṣiṣẹ labẹ olotu ijọba nigba naa laarin ọdun 2006 si 2008.
O fi ẹgbẹ oṣelu Benjamin Netanyahu silẹ lọ dara pọ mọ ẹgbẹ oṣelu Jewish Home Party.
O di ọmọ ile igbimọ aṣofin labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu naa lẹyin ti wọn bori idibo lọdun 2013.
Gbogbo iṣejọba alajumọṣe lo ti n di ipo minisita mu titi di ọdun 2019 nigba ti ẹgbẹ oṣelu New Right Alliance rẹ ti wọn ṣẹṣẹ da silẹ kuna lati ni ijoko kankan ni ile aṣofin orilẹede naa.
Saaju ko to di oloṣelu, Ọgbẹni Bennett jẹ ologun ati eekan oniṣowo.












