Hajj 2021 update: Saudi Arabia gbégilé ìrìnàjò Hajj fáwọn ọmọ Nàìjíríà àt'orílẹ̀èdè àgbáyé gbogbo lọ́dún 2021

Aworan Mecca

Oríṣun àwòrán, haramainsharifain.com

Awọn alaṣẹ orilẹede Saudi Arabia ti fofin de awọn arinrinajo silẹ mimọ lati orilẹede Naijiria atawọn orilẹede miran jakejado agbaye pe ko ni si Hajj fun wọn lọdun yii.

Orilẹede Saudi kede rẹ lọjọ Abamẹta pe iwọnba ẹgbẹrun lọna ọgọta ọmọ orilẹede naa ti wọn ti gba abẹẹrẹ ajẹsara COVID-19 wọn pe perepere ni yoo lanfani lati ṣe eto irinajo mimọ Hajj tọdun yii.

Àkọlé fídíò, Bí wọ́n ṣe ya Sinima Ayinla Omowura rèé, BBC Yorùbá fọ̀rọ̀ wá àwọn òṣèré lẹ́nu wò

Bi ẹ ko ba ni gbagbe, bakan naa lọmọ ṣori ni ọdun to kọja nigba ti ajakalẹ arun COVID-19 gbilẹ lagbaye ti awọn alaṣẹ orilẹede Saudi si se iloro rẹ mọ awọn to n gbero ati rinrinajo Hajj nitori ajakalẹ arun naa.

iwe ikede naa

Oríṣun àwòrán, haramainsharifain.com

Iwọnba bii ẹgbẹrun mẹwaa lawọn to kopa ninu eto irinajo mimọ naa lọdun 2020 eyi to jinna gedegede si nnkan bii miliọnu meji abọ eeyan lọdun 2019.

Eto Hajj tọdun yii, ti yoo waye lopin oṣu keje, ko ni wa fun awọn arinrinajo lati orilẹede miran, bakan naa ni ko si fun ọmọ orilẹede Saudi Arabia ti ọjọ ori rẹ ba ti pe ọdun marundinlaadọrin tabi jubẹ lọ.

Àkọlé fídíò, June 12 protest: Ọlọ́pàá yin tíá gaàsì lu àwọn olùwọ́de l'Eko, wọ́n ní ìjà àráàlù