Priscila Tsegah CCTV: Ikú akẹ́kọ̀ọ́ ẹni ọdún 23, irú kí ló ṣẹlẹ̀ tí ọlópàá fí ba oku rẹ̀ nílé ìtura?

Oríṣun àwòrán, Priscila Tsegah Family
Ẹkunrẹrẹ ohun to ṣẹlẹ si akẹkọọ akọroyin kan ti wọn ba oku rẹ ninu ibugbe awọn akẹkọọ ṣi ruju si awọn eeyan ilẹ Ghana.
Ọmọ ọdun mẹtalelogun ni akẹkọọ naa ti iku rẹ jẹ iyalẹnu fun ọpọ eeyan.
Losu to kọja ni iroyin gbode lori ayelujara pe akẹkọọ naa Priscila Tsegah dawati lẹyìn t'awọn mọlẹbi kede pe o to ọjọ mẹta tawọn ko ri nile.
Ko pẹ sigba naa l'awọn mọlẹbi gba ipe wí pe o jọ pe wọn ri oku ọmọ wọn nile itura kan.
Nise lawọn ọlọpaa lọ gbe oku naa ṣugbọn wọn ko le sọ oku tii ṣe nitori ko si idanimọ kankan lara rẹ titi di igba ti awọn mọlẹbi sọ pe ọmọ awọn ni.
- Ọkọ àti ìyàwó ri ọmọ ọdún kan àbọ mọlẹ láàyè lọgànjọ oru, àṣírí tú!
- Ìjọba Saudi dájọ́ ikú fún ọ̀dọ́ kan lórí ẹ̀ṣẹ̀ tó ṣẹ̀ láti kékéré, ìdí rèé
- Ojúbọ irúmọlẹ̀ tó jẹ́ ibùdó ìdìbò àti ìbùdó 740 ayédèrú míì gba ìwọ́gilé INEC
- Nǹkan tí a mọ̀ nípa ìlera Asiwaju Ahmed Tinubu
- Àjinigbé pa ọmọ méjì wọ́n ji méjì gbé lọ tí wan jẹ́ ọmọ òbí kan ni Ondo,
Iroyin to n tẹwa lọwọ fi han pe awọn oṣoju mi koro ni akẹkọọ yi ati ọrẹ rẹ obinrin kan ni wọn jijọ san owo oorun ọjọ meji ni ile itura.
Ṣugbọn wọn ni ọrẹ rẹ nikan lo da jade kuro lọjọ keji.
Wọn ni bi ọrẹ rẹ ṣe n jade, niṣe lo wọ aṣọ rẹ,to si gbe baagi ati kaadi idanimọ rẹ pẹlu.
A tun gbọ pe o ko kọkọrọ iyara to sun lọwọ lọ to sí tilẹkun pa.
Awọn oṣiṣẹ ile itura pada si ilẹkùn pada pẹlu kọkọrọ mii to wa lọwọ wọn.
- Ayédèrú òṣìṣẹ́ ìjọba ni Baba Ijesha fà kalẹ́ ló jẹ́ kó ṣì wà láhámọ́ - Ọlọ́pàá
- Nǹkan tí a mọ̀ nípa ìlera Asiwaju Ahmed Tinubu
- Ẹ jọ̀wọ́ ẹ jẹ́ kí àláfíà jọba lórí orin "Oniduro Mi", ìyá ni Tope Alabi jẹ́ sí mi - Adeyinka Alaṣeyori
- Ìjọba Saudi dájọ́ ikú fún ọ̀dọ́ kan lórí ẹ̀ṣẹ̀ tó ṣẹ̀ láti kékéré, ìdí rèé
- Alaseyori kọ́ ló ni orin "Oniduro Mi", àmọ́ ìdí tí mi ò ṣe bá a jà pé ó jí orin mi kọ nìyìí - Tolu Adelegan
Iyalẹnu lo jẹ fún wọn nigba ti wọn ba oku akẹkọọ yi ni ihoho omoluabi ninu agbara ẹjẹ lori ibusun.
Kia ni wọn pe awọn agbofinro ti ayẹwo si fi hàn pe wọn gun lọbẹ ninu ni
Awọn agbofinro Ghana bẹrẹ iwadii ti wọn sì fi fónrán fídíò awọn ọrẹ mejeeji ṣọwọ́ sí araalu.
Price Tsegah to jẹ mọlẹbi arabinrin yi sọ pe awọn fura si ọrẹ rẹ ti wọn jijọ lọ sí ilé itura.
Amọ ṣá awọn ọlọpaa ko ti darukọ ẹnikẹni pe ọ mọ nipa isekupaniyan yi.

















