Mustafa al-Darwish: Kíni ọdọ̀mọkùnrin Saudi yii ṣe tí ìjọba fi dájọ́ ikú fún un?

Mustafa al-Darwish

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Orile-ede Saudi Arabia ti dajọ ṣiseku pa arakunrin ọmọ ọdun mẹtadinlogun kan lori ẹsẹ ti wọn lo ṣẹ nigba to ṣi wa l'ọmọde.

Gẹgẹ bi awọn ajafeto-omoniyan ti ṣe sọ igbesẹ yi tako ipinu ti ijọba ilẹ naa ṣe ṣaaju pe awọn ti wọgile idajọ iku fawọn ọmọde ti ko ba ti balaga.

Lọdun 2015 ni wọn mu Mustafa Hashem al-Darwish lori ẹsun pe o kopa ninu iwọde.

Awọn alaṣẹ Saudi ni wọn fẹsun kan wi pe o ṣe akojọ ikọ agbesunmomi ti wọn si n gbero lati ṣe iwọde tipa lati da ìjọba ru.

Amọ ṣá awọn ajọ ajafeto-omoniyan ni ki ijọba dawọ idajọ iku rẹ duro nitori pe igbẹjọ rẹ ko t'ọna.

Amnesty International ati ẹgbẹ ajafeto-omoniyan Reprieve to n tàkò idajọ iku sọ pe ọmọ ọdun mẹrindinlọgbọn ọhun ti ṣaaju yi ohun pada pe oun ko mọ si ẹsun naa.

Àkọlé fídíò, 'Sister Tope Alabi yà mí lẹ́nu gan o pé "Oniduro mi" kìí ṣe orin tó yẹ kí ọlọ́run fún mi'

O ni wọn fiya jẹ oun lo mu ki oun jẹwọ ohun ti oun ko ṣe.

Awọn alaṣẹ Saudi ko tii fesi lori ẹsun yi.

Gẹgẹ bi ileesẹ iroyin Reuters ti ṣe wi, lara ẹsun ti wọn fi kan al-Darwish ni pe o gbero lati da alaafia ilu ru nipa ṣiṣe iwọde ati dida wahala silẹ lawujọ.

Lara ẹri ti wọn mú wa ni aworan kan ti wọn sọ pe ko dun mọ awọn ọmọ ogun ninu to sì fi han pe o kopa ninu apejọ iwọde to le ni mẹwaa lọdun 2011 ati 2012.

Lọdun to kọja ni awọn alaṣẹ orileede Saudi kéde pe awọn ko ni dajọ tabi sẹku pa awọn ti ko ba ti balaga mọ.

Dipo idajọ iku, wọn ni idajọ ẹwọn ọdun mẹwaa ni wọn yoo da fun wọn.

Àkọlé fídíò, Ẹ̀yin olórin ẹ̀mí tó ń bóra, lo èékáná gígùn, oò yàtọ̀ sí aṣẹ́wó hòtẹ́ẹ̀lì tí wọ́n ń gbé bíi súùtì Pepper Menti - Bola Are