Baba Ijesha Rape Saga: Mọ̀lẹ́bí Baba Ijesha pariwo síta, wọ́n ní ara rẹ̀ kò yá láhámọ́ tí wọ́n fi sí kò sì gbọdọ̀ kú

Princess ati Baba Ijesha

Oríṣun àwòrán, other

Gbajumọ oṣere tiata, Olanrewaju Omiyinka ti ọpọlọpọ mọ si Baba Ijẹṣa farahan niwaju ile ẹjọ loni.

Awọn mọlẹbi rẹ si ti pariwo sita pe ohun ti oju rẹ n ri ni ahamọ kọja ohun to han si araalu lọ.

Ninu ọrọ to ba BBC News Yoruba sọ ni ile ẹjọ Ẹwatomilọla Ayẹni to jẹ aburo Baba Ijẹṣa ṣalaye pe o daju pe iya ẹṣẹ ti ẹgbọn oun ko mọ lo n jẹ.

Àkọlé fídíò, Baba Ijesha Rape Case: Yomi Fabiyi ní òun nìkàn lòun rí ara òun tó dúró tí Baba Ijesha
Àkọlé fídíò, Ṣé ìrìnàjò nínú ọkọ̀ Reluwé Ibadan-Lagos-Ogun tuntun bá aráàlù lára mu? Èsì rèé

Gẹgẹ bi o ṣe sọ, ara Baba Ijẹṣa ko ya bayii ni ahamọ to wa gbogb ipa ti ẹbi si n sa lori rẹ lo n ja si pabo.

O ni ẹsun hihu iwa aitọ si ọmọde ti wọn fi kan an ni ọdun meje sẹyin, ohun to pamọ lori rẹ pọ ti araalu ko si mọ.

"ẹsun hihu iwa aitọ si ọmọde ti wọn n pariwo lọdun meje sẹyin ti gbogbo eeyan ba mọ nnkan to ṣẹlẹ si Baba Ijẹṣa ti awa mọlẹbi o le sọ sita ṣugbọn eeyan melo la fẹ ro ẹjọ yii fun"

Awọn mọlẹbi Baba Ijẹsha ni ohun ti awọn ohun to n ṣẹlẹ ni kọọrọ ti mọlẹbi si n farada ni kọọrọ ṣugbọn tawọn olupẹjọ fẹ wu sita gbangba yii lee jẹ iṣu ata yan an yana, ṣugbọn awọn ṣetan fun ohun gbogbo ti wọn ba fẹ ṣe bayii.

Àkọlé fídíò, Ogbomoso: Ẹ kálọ sí Ajilete láti mọ àwọn ibùdó tó mú kí ìlú náà yàtọ̀

"Ṣe Princess ti sọ iye igba ti oun funrarẹ ti bọ aṣọ si ihoho niwaju Baba Ijẹṣa pe ko ba oun lajọṣepọ"

Ẹwatomi ni lootọ Princess lee ṣsore fun Baba Ijẹṣa ṣugbọn ọpọlọpọ igba lo gbe igbesẹ lati fa oju rẹ mọra fun isunmọraẹni ti ko tọna.

Ẹwatomi to ni lẹyin Eleduwa, Baba Ijẹṣa lo sọ oun di gbogbo nnkan ti oun da loni ọdọ rẹ ni oun si gbe fun ọpọlọpọ ọdun lai jẹ pe o fi ọwọ iwa kotọ lọ oun ri ṣalaye fun BBC News Yoruba pe wọn fẹ ba orukọ nla Baba Ijẹṣa jẹ ni.

O fi kun un pe ko si itọju to peye fun Baba Ijẹṣa lahamọ to wa, lọwọ ti a si n sọrọ yii ara rẹ ko ya.

Tuntun tí a gbọ́ nípa Bàbá Ijesha rèé

Baba Ijesha Rape Saga: Nǹkan tuntun tí a gbọ́ nípa Bàbá Ijesha lórí ẹjọ́

Oríṣun àwòrán, Baba Ijesha

Gbájúgbajà òṣèré tíátà Olarewaju Omiyinka ti gbogbo ènìyàn mọ̀ si baba Ijesha ti ọlọ́pàá ipínlẹ̀ Eko n ṣe ìwádìí rẹ̀ lọ́wọ́.

Baba Ijesha ni wọ́n fi ẹsun kan pé ó ṣe ọmọdẹ ti ko ti tójúbọ́ báṣubàṣú.

Ilé ẹjọ́ Magisiereti ti Yaba ni aago mẹ́sàn owúrọ oní ọjọ́rú ọjọ́kẹrindinlógun oṣù kẹfa ọdún 2021.

Ilé iṣẹ́ BBC Yoruba kàn sí agbẹnusọ ọlọ́pàá ìpińlẹ̀ Eko Muyiwa Adejobi, ó sì fi ìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ pé Baba Ijesha yóò fojú balé ẹjọ́ loníì.

Ọjọ́ kẹtàdílógún oṣù karún ọdún 2021, lẹ́yìn àsìkò díẹ̀ tó ti wa látìmọ́lé ti wa látìmọ́lé ni wọn to fi silẹ.

Ẹ̀wẹ̀, lẹ́yìn tí wọ́n ti fún láàyé láti gba onídùró, ní èyí tí wọ́n ni kó mú ẹ̀bí rẹ̀ méjì, oṣìṣẹ́ ìjọba onípele kẹríndílógún àti ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta náìrà ti wan ni kí wọ́n san fún ilé ẹjọ́ gíga ìpínlẹ̀ Eko.