Chinese Railway workers: Ọṣíṣẹ́ Chinese tó ń ṣe Reluwé mẹ́rin ni àwọn agbébọn jí gbé ní Oogun

Ajínigbé ṣọṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ mejì

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àwọn ènìyàn kan tó jọ àwọ́n jàndúkú àgbénipa ṣe ìkọlù sí ilé àgbẹ̀ kan ti wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Dele ni ìlú Ajowa Akoko, níjọba ìbílẹ̀ Akoko West, ìpínlẹ̀ Ondo.

Wọ́n ji àwọn ọmọ méjì gbé nígbà tí wọ́n pa méjì mííràn nínú àwọn ọmọ ọkùnrin náà.

Ìròyìn sọ pé, àwọn ènìyàn náà ti kọ́kọ́ lọ sí ilé ọkùnrin darandaran kan ti orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Yinka Oladotun, ni owúrọ kùtùkùtù ọjọ́ náà tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí yìbọ̀n sókè ṣùgbọ́n wọn kò rí ààyè wọ ibẹ̀.

Àkọlé fídíò, Baba Ijesha Rape Case: Yomi Fabiyi ní òun nìkàn lòun rí ara òun tó dúró tí Baba Ijesha

Ẹni kan ti ọ̀rọ̀ náà sojú rẹ̀ sàlàyé pé ọpọ́lọpẹ́ pé àwọn ọmọogun tètè dé lati da ete wọn ru ti wọ́n sì le wọn lọ lágbègbè náà.

"Lẹ́yìn ti wọn kò rí ààyè wọ ilé Yinka ni wọn mórí lé ilé Dele ti wọ́n fi lọ pa àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin méjì ti wọ́n sì kó àwọn méjì tókù lọ sí ibi ti ẹnikẹni kò mọ̀"gẹ́gẹ́ bi ẹni náà ṣe sọ.

Ẹni náà fi kun pé, ọlọ́pàá, Soja àti àwọn ikọ̀ Amotẹkun lo jọ parapọ báyìí láti wọ igbó Ajowa láti wá àwọn ọ̀daràn náà jáde.

Agbẹnusọ ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Ondo, Tee-Leo Ikoro náà fi ìdí ọ̀rọ̀ yìí múlẹ̀ pé àwọn ẹlẹ́sọ̀ ààbò gbogbo ló ti bẹ̀rẹ̀ sí ni wọ́ àwọn ọmọ méjì tí wọ́n jí gbé.

Ẹ̀wẹ̀, ní ìpínlẹ̀ Ogun, wọ́n ti jí àwọn ọmọ Chinese tó jẹ́ òṣìṣẹ́ Reluwe mẹ́rin gbé níbẹ̀.

Àwọn yìí ló n sàbójútó ọkọ ojurin Ibadan-Lagos Reluwe ni ojú ọ̀nà Ibadan-Abeokuta.

kí wọ́n tó ji wọ́n gbé insìkpẹ́tọ̀ ọlọ́pàá kan tó n sọ wọ́n ni wọ́n yìn níbọ̀n tó si farapa púpọ̀, èyí sì ni wan fi gba ìbọn AK-47 ọwa ọlọ́paàá náà.

Wọ́n ni àwọn agbébọ̀n yìí to mẹ́jọ ti gbogbo wọn si wọ aṣọ ọ̀lẹ́ ń tẹ̀lé àáfà dúdú pẹ̀lú ìbọn AK-47 lọ́wọ́, wọ́n ya wọ ibi ti wọ́n ti n ṣiṣẹ́ nilu Adeaga/Alaaga, ìjọba ìbílẹ̀ Odeda nipinlẹ Ogun.

Bákan náà àkójọpọ̀ àwọn elétò ààbò ló tí wọ inú ìgbo agbègbè náà láti wá wọn kan.

Baálẹ̀ ilú Alaagba tó wà ni ẹnu ibòde ìpínlẹ̀ Oyo àti Ogun olóyè Adekunle Olabamiji fìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ pé ó jọ bí ẹni pé àwọn ajínígbé náà tí n dọdé wọn ni àwọn inú igbó tó wà lágbègbè kí wọ́n tó jí wọn gbé.

Olabamiji sàpèjúwe ìṣẹ̀lẹ̀ náà bí èyí ttó báni lójijì tó sì yani lẹ́nu.

Agbẹnusọ ọlọ́pàá ìpińlẹ̀ Oyo DSP Abimbola Oyeyemi fidi ọrọ náà múlẹ̀ àti pé ọlọ́pàá àti àwọn ọmọ ẹgbẹ́ OPC àti àwọn ọlọ́dẹ ti lọ sínú igbó láti ṣe àwárí wọn.