Shrine polling unit: Wo ohun tí INEC fẹ́ ṣe lórí ìbò sípò gómìnà Ekiti àti Osun lọ́dún 2022

Alaga ajọ INEC

Oríṣun àwòrán, Inec

O fẹrẹẹ to ibudo idibo ẹẹdẹgbẹrin abọ o di ọkan ti ajọ eleto idibo INEC ti gbe kuro ni orisiriṣi ibi ti wọn wa kaakiri ipinlẹ Naijiria to fi mọ ilu Abuja.

Alaga Ajọ INEC lorilẹede Naijiria, Ọjọgbọn Mahmood Yakubu ninu ọrọ to sọ ṣalaye pe Ọjọ Satide, Ọjọ Kejidinlogun, Osu Kẹfa, ọdun 2022 ni idibo si ipo gomina yoo waye ni ipinlẹ Ekiti.

Bakan naa nibi eto ọhun, ajọ Eleto idibo, INEC ti kede pe ọdun 2022 ni idibo si lọ gomina yoo waye ni ipinlẹ Osun ati Ipinlẹ Ekiti lorilẹede Naijiria.

Yabuku tun fi kun un pe, oṣu kan lẹyin ti idibo ba waye ni ipinlẹ Ekiti, ni idibo si ipo gomina yoo waye nipinlẹ Osun ni Ọjọ Satide, Ọjọ kẹrindinlogun, Oṣu Keje, ọdun 2022.

Bakan naa ni Ajọ INEC ni awọn ti mu afikun de ba awọn ibudo idibo kaakiri orilẹ̣ede Naijiria lati 119,974 si 176,846.

Alaga ajọ eleto idibo, Ọjọgbọn Mahmood Yakubu lo ṣipaya eyi l'Ọjọbọ nibi iṣide olu ileeṣẹ wọn to wa ni ilu Abuja.

Yakubu ni "lẹyin iforikori pẹlu awọn tọrọ kan, ajọ yii ti ṣaṣeyọri lati gbọn ibudo idibo ẹẹdẹgbẹrin abọ o di ọkan kuro lawọn ojubọ irumọlẹ to j ibudo aitọ lati maa dibo.

O ni eyi wa ni ibamu ofin ajọ eleto idibo pe ati ri na lọ dibo nibi to san lai si idiwọ jẹ ẹtọ oludibo ti a gbu mojuto.

Ninu iye ti wọn ri, ibudo idibo 232 ni wọn gbe kuro ni awọn aaye tabi ile to jẹ aladani, 145 lawọn Aafin Ọba, 6 ni Mọṣalaṣi, 21 lati Sọọsi ati mẹsan lati Ojubọ

''A ti gbe awọn ibudo idibo kuro ni awọn agbegbe to jẹ ti aladani bii ṣọọsi, aafin, mọṣalasi ati awọn ile ẹsin abalaye gbogbo''

''Awọn ibudo idibo tuntun ti a ṣẹṣẹ buwọlu naa yoo bẹrẹ iṣẹ lati asiko ibo si ipo gomina ti yoo waye nipinlẹ Anambra ni Ọjọ Kẹfa, Oṣu Kọkanla, ọdun 2021.''

Àkọlé fídíò, 'Sister Tope Alabi yà mí lẹ́nu gan o pé "Oniduro mi" kìí ṣe orin tó yẹ kí ọlọ́run fún mi'

Ajọ INEC ni awọn n ṣiṣẹ takuntakun kaakiri orilẹede Naijiria lati rii pe idibo n lọ ni irọwọ-rọsẹ lai ni magomago ninu.

Bakan naa ni wọn fi kun pe awọn kede ọjọ idibo sipo gomina ipinlẹ Ekiti ati Osun naa ki awọn ti ọrọ kan le lọ si oju opo ayelujara wọn lati lo wo awọn ilana to wa fun awọn oloṣelu ti yoo kopa ninu idibo naa ni ọdun to n bọ.

Ajo INEC wa parọwa si awon ẹgbẹ oloselu lati ri wi pe wọn ṣakoso idibo abẹlẹ wọn lai si magomago, ki ohun gbogbo si lọ ni pẹle pẹlẹ.

INEC kéde ọjọ́ ìdìbò sípò gómìnà l'Osun

Gomina Oyetọla ati Sẹnetọ Adeleke

Oríṣun àwòrán, other

Ajọ eleto idibo lorilẹede Naijiria, INEC ti kede sjọ idibo sipo gomina ni ipinlẹ ọṣun ti yoo waye ni ọdun 2022.

Ninu atẹjade kan to fi sita, INEC ni ọjọ kẹrindinlogun oṣu keje ọdun 2022 ni idibo naa yoo waye.

Atẹjade naa ti akọwe ajọ INEC, Rose Orian-Anthony fọwọsi tun sọọ di mimọ pe ọjọ kini oṣu keji ọdun 2022 ni ajọ naa yoo gbe ikede idibo sita lẹyin eyi ti awọn ẹgbẹ oṣelu to ba fẹ kopa lee bẹrẹ si ni gbaradi.