Baba Ijesha case: Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Eko ní àwọn ti yọwọ́ lórí ẹjọ́ Baba Ijesha, àárín òun àti ìjọba lọ̀rọ̀ wà báyìí

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti sọ pe awọn ko mọ ohunkohun nipa ọrọ Baba Ijẹṣa ati igbẹjọ rẹ mọ.
Ninu ọrọ ti wọn ba awọn oniroyin sọ ni gbagede ile ẹjọ Majisireeti ipinlẹ Eko to wa ni agbegbe Yaba, adari ẹka ofin nileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, Arabinrin Cardoso Yetunde ṣalaye fun awọn akọroyin pe ọlọpaa ti yọwọ kuro ninu ẹjọ Baba Ijẹṣa ati pe ọfiisi adari olupẹjọ DPP nipinlẹ Eko lọrọ ẹjọ Baba Ijẹṣa wa bayii.
- Tuntun tí a gbọ́ nípa Bàbá Ijesha rèé
- Ìjọba Saudi dájọ́ ikú fún ọ̀dọ́ kan lórí ẹ̀ṣẹ̀ tó ṣẹ̀ láti kékéré, ìdí rèé
- Nǹkan tí a mọ̀ nípa ìlera Asiwaju Ahmed Tinubu
- Ẹ jọ̀wọ́ ẹ jẹ́ kí àláfíà jọba lórí orin "Oniduro Mi", ìyá ni Tope Alabi jẹ́ sí mi - Adeyinka Alaṣeyori
- Mo rí òkú TB Joshua tó yọ sí mi lẹ́yìn ikú rẹ̀ - Jaiye Kuti
O ni lootọ ni wọn fun Baba Ijesa ni Beeli lasiko iyanṣẹlodi ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ẹka iṣedajọ nigba naa, ṣugbọn nitori awọn gbedeke beeli ti wọn fun un nigba naa ti ko lee mu ṣẹ lo fi jẹ ki wọn gbe e wa sile ẹjọ Majisireeti lọjọru lati bẹrẹ igbẹjọ rẹ ni pẹrẹu.
O ni lara gbedeke beeli ti wọn fun un ni pe ko fa oṣiṣẹ ijọba to wa ni ipele ikẹrindinlogun kalẹ gẹgẹ bi oniduro eleyi to ni ko ri ṣe.
Ọga ọlọpaa Cardozo ni awọn rii pe ayederu ni ẹni ti awọn agbẹjọro rẹ fa kalẹ gẹgẹ bi oṣiṣẹ ijọba onipele ikẹrindinlogun.
"Oṣiṣẹ onipele ikẹrindinlogun ti wọn mu wa, a ni lati mu u tọ olori awọn oṣiṣẹ ijọba nipinlẹ Eko lọ lati lee fidi rẹ mulẹ boya lootọ ni ipele iṣẹ ijọba ti ẹni naa wa.
Olori awọn oṣiṣẹ si fun wa ni esi pe ẹniyẹn kii ṣe oṣiṣẹ."
O ni ọfiisi adari olupẹjọ DPP nipinlẹ Eko ti tẹwọ gba ẹjọ naa lọwọ awọn ọlọpaa ati pe ẹjọ naa kii ṣe ti ọlọpaa mọ, o ti di ẹjọ ijọba.
"Lọwọ yii a ti taari ẹjọ naa sọdọ ọfiisi adari olupẹjọ DPP nipinlẹ Eko ko si nnkan to kan ọlọpaa mọ pẹlu ọrọ igbẹjọ Baba Ijesha"
ki ni ohun ti awọn agbẹjọro fun Baba Ijẹṣa sọ nile ẹjọ?
Ninu ọrọ rẹ Agbẹjọro fun Baba Ijẹsa, Amofin Kayọde Ọlabiọrẹ ṣalaye pe adajọ Majisireeti to gbọ ẹjọ Baba Ijẹṣa ni oun ko lagbara lati gbọ ẹjọ naa mọ nitori pe ọfiisi adari olupẹjọ DPP nipinlẹ Eko ti sọ niwaju ileẹjọ pe awọn wọn ti pe ẹjọ naa niwaju ile ẹjọ giga ipinlẹ Eko.
Amofin Ọlabiọrẹ ni arọwa wọn lati beere fun beeli ko le gba itusilẹ fun igba diẹ ko bọ si.
O fi kun un pe gbedeke oṣiṣẹ ijọba onipele ikẹrindinlogun ti wọn fun Baba Ijẹsa lo fa a to ṣi fi wa ni ahamọ ijọba lọwọlọwọ.
Amọṣa o ni ẹbẹ awọn fun ile ẹjs lati tun ọrọ beeli naa yẹwọ foriṣanpọn nitori pe wọn ti pe ẹjọ naa niwaju ile ẹjọ giga.
O ni bi wọn ba gbe ẹjọ naa de iwaju ile ẹjọ giga ipinlẹ Eko ni wọn yoo to tun gbe ẹbẹ fun beeli dide fun Baba Ijẹṣa.















