Denrele Edun sọ pé ìjá nínú ìrìnàjò ìfẹ́ pẹ̀lú obìnrin ló mú kó dán ọkùnrin wò

Oríṣun àwòrán, Denrele Edun
Gbajugbaja ọkùnrin agbohunsafẹfẹ, to tun gbajúmọ fun mimura bii obìnrin, Denrele Edun sọ pe bi oun ṣe fẹ ọkùnrin ẹgbẹ oun ni àṣìṣe to tobi julọ ti oun ti ṣẹ laye.
Ọjọ Aiku to kọja ni Denrele ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi ogoji ọdun.
Lasiko ifọrọwanilẹnu kan to ṣe pẹlu akọroyin, Chude Jideonwo ni Denrele sọ ọrọ naa.
O ni ki eeyan ní idunnu to ti ọkan wá jẹ nkan to ṣòro, nitori naa si ni oun fi ma n wa idunnu kiri lọdọ àwọn eeyan mii.
Denrele Edun ṣalaye pe ọpọ igba ni oun ni ijakulẹ ninu irinajo ifẹ pẹlu obìnrin.

Oríṣun àwòrán, Denrele Edun
O ni ọpọ ọkùnrin ẹgbẹ oun si lo n fi ọrọ ifẹ lọ òun, eyi to mu ki oun pinnu lati gbiyanju rẹ wo.
"Sugbọn, ijakulẹ ni mo ba pade nibẹ, nitori pe asiko naa lo buru julọ ninu igbesi aye mi.
"Mi o ti i fi bẹ ẹ rinrinajo ifẹ to pọ lasiko naa, idi si niyii ti mo fi ma n ṣiyè meji ki n to wọ wọn."
O ni lọjọ kan ni oun ronu pe boya àwọn obinrin ko ni anfaani kankan ti wọn le ṣe oun, ni oun ba pinnu lati gba ìkan ninu awọn ọkunrin to n fi ọrọ ifẹ lọ ọ laaye.
" Igbesẹ naa lo buru julọ ninu igbesi aye mi. Lati igba naa ni mo si ti ba ara mi sọrọ pe emi ni baba alaanu ara mi bayii."
"Idaamu ni asiko naa mu ba mi. Mo si ti pinnu pe iru rẹ ko tun ni waye mọ."
Denrele sọ pe nibi ti oun ba ọrọ aye oun de, oun ko nilo ẹnikẹni ninu igbesi aye oun.














