Homosexuality: Nàìjíríà, àtàwọn orílẹ̀èdè tí ìbálòpọ̀ akọsákọ ti lòdì sí òfin rèé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Oriṣiriṣi ọrọ lo ti n gbode lori awọn onibalopọ abosabo, akọsako, awọn to ni nkan ọma ọkunrin ti wọn tun ni ti obinrin papọ tabi awọn to yi ẹda akọ tabi abo ti wọn wa pada.
Lorilẹede Cameroon, o ti fa ki wọn fi ọwọ ofin mu ọgọọrọ awọn eeyan lọdun yii ni ibamu pẹlu ija fun ẹtọ ọmọniyan.
Koda laipẹ yii, eeyan meji to yiẹda ara wọn pada ni wọn ti ran si ẹwọn ọdun marun lẹyin ti wọn fi ẹsun didan ibalopọ akọsakọ wo.
Awọn orilẹede wo ni ko faaye gba ibalopọ akọsakọ?
Orilẹede mọkandinlaadọrin ni ofin wọn lodi si ibalopọ akọsakọ o si fẹrẹẹ to idaji wọn to wa ni Afirika.
Ẹwẹ, lara awọn orilẹede yii ti n gbiyanju lati ma maa pe ibalopọ ẹda kan naa ni iwa to tapa si ofin.
Fun apẹrẹ ninu oṣu keji ọdun yii, aarẹ orilẹede Angola, Joao Lourenco fọwọ si ofin to pada faaye gba ki awọn eeyan maa ni ibalopọ akọsakọ tabi abosabo to si ni ki awan eeyan yee ṣe idẹyẹsi mọ lori ọrọ to ba ni ṣe pẹlu ibalopọ.
Gabon naa ṣe bakan naa lori ibalopọ akọsakọ tabi abosabo ti wọn si kede ẹwọn oṣu mẹfa ati faani fun ẹni ti wọn ba gbamu.
Botswana naa ti da ofin naa pada lọdun 2019; Mozambique ati Seychelles ti wọgile ofin to ti ibalopọ ẹda kan naa lọdun diẹ sẹyin.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ni Trinidada ati Tobago, ile ẹjọ kan tun fagile ofin to tako ibalop akọsakọ pe ofin ọhun funrark tako ofin.
Nibẹrẹ ọdun to kọja yii gan ni Singapore da igbesẹ lati ṣe ayida ofin ti yoo tako ibalopọ akọsakọ.
Ẹwẹ lawọn ibi to ku, igbiyanju lati ṣe bẹẹ ki wan mu ofin yii kuro kuna. Fun apẹrẹ ni Kenya, wọn gbe ẹjọ to tako ibalopọ akọsaka ro daadaa.

Oríṣun àwòrán, AFP
Idi ti ọpọ orilẹede ṣe bẹrẹ si ni gba ibalopọ akọsakọ laye.
Ọpọlọpọ ofin to sọ ibalopọ akọsakọ di ẹṣẹ bẹrẹ lati igba aye awọn oyinbo amunisin to si jẹ pe lawọn ibi kan, ẹwọn gbọọrọ ni ijiya ẹṣẹ naa.
Lara awọn orilẹede to ni ko ba ofin mu ki ibalopọ akọsakọ wa naa ni ofin to lodi si ibalopọ abosabo.
Amọ apaps ẹgbẹ awọn onibalopọ yii - Gay, Bisexual, Transgender ati Intersex (Ilga) ni ijiya iku gan ni ijiya to wa fun awọn ẹsun yii ni iha Ila Oorun Ariwa Naijiria, ni Brunei, Iran, Mauritania, Saudi ati Yemen.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bi igba ṣe n yi
Baye ba ṣe n yi ka maa ba wọn yi... Orin tawọn eeyan maa n kọ eyi to difa fun pe igba ti n yi lori awan ofin aye atijọ ti wan fi de ibalopọ ẹda kan naa.
Nibayii, orilẹede mejindinlọgbọn lagbaye lo faaye gba ibalopọ ẹda kan naa, ti mẹrinlelọgbọn si ti da a bi ọgbọn faaye gba awan nkan kọọkan to ni ṣe pẹlu ibaṣepọ akọ ati akọ tabi abo ati abo. Ẹgbẹ Ilga sọ bẹẹ.

Ẹkunrẹrẹ akọsilẹ awọn orilẹede ti aaye ko ti gba ibalopọ ẹda kan naa ree:
Afghanistan
Algeria
Antigua & Barbuda
Bangladesh
Barbados
Bhutan
Brunei
Burundi
Cameroon
Chad
Comoros
Cook Islands
Dominica
Egypt
Eritrea
Eswatini
Ethiopia
Gambia
Ghana
Grenada
Guinea
Guyana
Iran
Jamaica
Kenya
Kiribati
Kuwait
Lebanon
Liberia
Libya
Malawi
Malaysia
Maldives
Mauritania
Mauritius
Morocco
Myanmar
Namibia
Nigeria
Occupied Palestinian Territory (Gaza Strip)
Oman
Pakistan
Papua New Guinea
Qatar
Saint Kitts and Nevis
Saint Lucia
Saint Vincent and The Grenadines
Samoa
Saudi Arabia
Senegal
Sierra Leone
Singapore
Solomon Islands
Somalia
South Sudan
Sri Lanka
Sudan
Syria
Tanzania
Togo
Tonga
Tunisia
Turkmenistan
Tuvalu
Uganda
Uzbekistan
Yemen
Zambia
Zimbabwe


















