South-West Leaders Meeting: Fayemi, Akeredolu fọwọ́sí àbọ̀ ìpàdé àwọn adarí ẹgbẹ́ APC

Rotimi Akeredolu ati Kayode Fayemi

Gomina Rotimi Akeredolu ti sọ pe oun faramọ abajade ipade awọn adari ẹgbẹ oṣelu APC to waye nile ijọba ipinlẹ Eko lọjọ Aiku.

O fi kun pe idi ti oun ko fi yọju sibi ipade naa ni pe, wọn ko tete fi iwe pe oun, yatọ si awọn nnkan miran to yọju.

Gomina Akeredolu fi ọrọ naa lede ninu atẹjade kan to fi soju opo Facebook rẹ, eyi ti akọwe iroyin rẹ, Richard Olatunde buwọ lu.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni "O wu Akeredolu lati wa nibi ipade naa nitori o da lori abọ ipade ti awọn gomina iha Guusu Naijiria ṣe niluu Asaba.

Idi ti gomina naa ko ṣe yọju sibi ipade naa ni pe, ko tete ri iwe ipe ati pe o ni ipade miran to ni lati yọju si niluu Ibadan, ṣaaju ki iwe ipe ọhun to de."

Àkọlé fídíò, Down Syndrome Skill centre: Wo bí ọmọ tí ọpọlọ wọn kù díẹ̀ ṣe ń kọ́ iṣẹ́ agẹrun

Sugbọn gbogbo awọn ohun ti awọn ti adari ẹgbẹ APC fẹnuko le lori niluu Eko ni Akeredolu fọwọ si nitori awọn ọrọ naa ṣe pataki fun ilọsiwaju ati iṣọkan orilẹ-ede Naijiria.

"Ẹwẹ, gomina ipinle Ekiti, Kayode Fayemi naa ti fi ọrọ lede lori idi ti ko ṣe yọju sibi ipade apero ọhun.

Ninu atẹjade kan to fi soju opo Twitter rẹ, Fayemi ni kii ṣe pe oun mọọmọ pinnu lati mase yọju sibi ipade ọhun, ṣugbọn iwe ti wọn fi ranṣẹ ko tete tẹ oun lọwọ.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, "Iwe ipe fun ipade naa ti wọn ni amugbalẹgbẹ Tinubu fi ranṣẹ lori ẹrọ atẹjiṣẹ WhatsApp ko tẹ Gomina Fayemi lọwọ.

Àkọlé fídíò, Epe Fish Market: Wá wo oríṣi ẹja tí o rírí lọ́jà ẹja tó tóbi jùlọ ní Nàíjíríà

"Gomina Fayemi ko ri iwe ipe ipade, lo fa ṣababi idi ti ko fi si nibẹ.

Fayemi ni oun ti tọrọ aforiji lọwọ awọn adari ẹgbẹ naa lori bi oun ko ṣe yọju sibi ipade ọhun, oun ko mọọmọ.

O pari ọrọ rẹ pe, digbi ni oun wa lẹyin awọn adari ẹgbẹ naa lori gbogbo oun ti wọn fẹnu ko le lori nibi ipade ọhun.

Ile ijọba ipinlẹ Eko ni ipade awọn adari ẹgbẹ oselu APC naa ti waye, nibi ti wọn ti bu ẹnu atẹ lu awọn to n pe fun ipinya Naijiria.

Wọn tun fẹnuko pe Naijiria dara ni oṣuṣu ọwọ ju ki o pin lọ.

Àkọlé fídíò, Akungba Suicide: Ẹbí, ọ̀rẹ́ àti ọ̀gá iléẹ̀kọ́ sọ̀rọ̀ lórí irú èèyàn tí Feranmi Fasunle jẹ́

Lara awọn to wa nibi ipade naa ni aṣaaju ẹgbẹ APC ni Naijiria, Bola Hamed Tinubu, gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu, atawọn eekan mii ninu ẹgbẹ oṣelu APC.

Amin iyasọtọ kan

Tinubu, Gbajabiamila, Sanwo-Olu gbárùkù tí fífòfin de dída ẹran káàkiri ìgboro

Tinubu, Sanwo-Olu, Gbajabiamila

Oríṣun àwòrán, Lagos State Government

Awọn adari ni ẹgbẹ oṣelu APC ni Iwọ oorun Naijiria ti fi ọwọ sowọpọ pẹlu awọn gomina ni iha Guusu Naijiria lati fofin de awọn Fulani darandaran lati maṣe da ẹran kaakiri igboro mọ.

Awọn adari ẹgbẹ oṣelu APC naa gbe igbesẹ ọhun lasiko ipade to waye ni bonkẹlẹ ni ilu Eko ni Ọjọ Kẹtalelogun, Oṣu Karun, ọdun 2021.

Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu to pe ipade naa ninu atẹjade to fi lede ni awọn fi gbogbo ara wa lẹyin abajade ipade awọn gomina Iwọ Guusu Naijiria.

Àkọlé fídíò, Mo dúpẹ́ pé ìgbà tí mo wà nínú Jesu ni mo lọ sẹ́wọ̀n, tó bá jẹ́ pé mo wà nínú áyé ni ... - Wòlìí Genesis

Bakan naa ni wọn parapọ sọ wi pe eto oṣelu to fi aye gba ki ipinlẹ kọọkan ni agbara lati le da nkan ṣe fun ara wọn, iyẹn ''True Fedralism'' yoo jẹ ki eto oṣelu tiwantiwa gbooro si.

Bakan naa ni wọn fikun pe ijọba apapọ gbọdọ fun ijọba ipinlẹ ni anfaani lati gbe igbesẹ lori eto aabo wọn ni abẹle, ki o to doju ru, ti yoo si fa rogbodiyan kaakiri Naijiria.

Awọn adari ni ẹgbẹ oṣelu APC ni Iwọ Oorun Naijiria naa fikun pe eto aabo ti ko munadoko ni Naijiria, ti mu ki igbeaye niran fun awọn araalu, ti iya ati iṣẹ si gbode kan.

Àkọlé fídíò, Àìsàn jẹ́ kí àwọ̀ ara Amida dàbí ara ẹja