Yoruba Nation: Mi ò faramọ́ orílẹ̀-èdè mìí yàtọ̀ sí Naijiria tí a wà yìí

Oríṣun àwòrán, facebook/oluwarotimi akeredolu aketi
Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu ti fesi si iroyin to n lọ pe o faramọ idasilẹ Oduduwa Nation.
Ninu atẹjade to fi sita ni ọjọ Aiku, ni Gomina Akeredolu ti sọ pe fifi aaye gba awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ, lati ṣe iwọde itagbangba ni ipinlẹ naa, nitori pe ẹtọ wọn ni, ko tumọ si pe oun fi ara mọ tabi ṣe atilẹyin fun ipinya lorilẹede Naijiria.
Ọjọ Satide ni gbajugbaja ajijagbara nilẹ Yoruba, Sunday Adeyẹmọ 'Igboho', ati awọn eeyan mii ṣe iwọde ni ilu Akurẹ, tii ṣe olu ilu ipinlẹ Ondo, lati ṣe ipolongo fun idasilẹ orilẹ-ede Oduduwa.
Lẹyin iwọde naa si ni iroyin ti n lọ pe Sunday Igboho sọ pe Akeredolu faramọ iwọde naa ati idasilẹ orilẹ-ede tuntun.
Akọwe ipolongo fun Akeredolu to fi ikede naa sita, Richard Olatunde, sọ pe gomina ko ni igbagbọ ninu ipolongo fun idasilẹ orilẹ-ede Oduduwa, tabi faramọ jijade kuro ni Naijiria ni ilana ti wọn n gba polongo.
"Orilẹ-ede Naijiria to wa ni iṣọkan, to ni agbara, ti ko si ṣe e pin, ni Akeredolu fi ara mọ, gẹgẹ bi awọn gomina ni Gusu Naijiria ṣe fi ọwọ si.
O ṣalaye pe gomina ṣe bẹẹ nitori ifẹ ati ifọkansin fun orilẹ-ede Naijiria, ati fun ẹya rẹ to jẹ Yoruba.
"O ṣe pataki fun awọn ajijagbara to n fẹ ipinya awọn Yoruba kuro ni Naijiria lati mọ pe ko si atiẹyin Gomina Akeredolu fun wọn."
Akure gbàlejò olùwọ́de 'Yoruba Nation', wọn ń pariwo fún ìyapa Nàíjíríà
Awọn ọmọ Yoruba ni ipinlẹ Ondo ti bẹrẹ iwọde nilu Akure lati fi beere fun idasilẹ orilẹede Oduduwa.
Ni ikorita Isikan nilu Akure, ni iwọde naa ti gberasọ, ti ireti si wa pe awọn oluwọde naa yoo lọ yika ilu naa lati la awn araalu lọyẹ nipa pataki idasilẹ orilede Oduduwa.
Akọroyin BBC Yoruba to wa nilu Akure jabọ pe ni irọwọrọsẹ ni iwọde naa n lọ, lai si rogbodiyan kankan.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ìtàn nípa orúkọ àdúgbò tó níí ṣe pẹ̀lú ìjà Oyo, Fulani àti Ilorin ní 1835
- Ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ bẹ̀rẹ̀ l‘Oyo, àwọn olùdìbò kò tíì jáde lọ́gọ̀ọ̀rọ̀
- Èèmọ̀! Ọmọogun 20 sọnù sínú ìjàmbá ọkọ̀ òfurufú mẹ́ta lóṣù mẹ́ta
- Seyi Makinde, máṣe bo ẹni tó pa ọmọ l‘Ogbomoso, tú aṣìrí rẹ̀ síta - APC, Akala
- Àdánù àti ìbànújẹ́ ńlá ni iku ọgá àgbà àwọn ọmọgun Nàìjíríà jẹ́ -Ààrẹ Buhari
- Ẹ le fi owó ra gbogbo ayé àmọ́ kò sí owó tó lè ra ẹ̀rí ọkàn mi - Obasanjo
Koda, a kofiri awọn agbofinro ti wọn duro wa wa lati dena rogbodiyan to le fẹ su yọ lasiko iwọde naa.
Ninu awọn to ba BBC lori idi ti wọn fi kora jọ fun iwọde naa ni awọn n se nitori iya n jẹ Yoruba awọn si gbọdọ ji giri.

Nigba ti wọn n ba ikọ iroyin BBC Yoruba sọrọ, awọn eeyan to n polongo fun idasilẹ orilẹede Oduduwa naa salaye idi ti wsn se wa si Akure.
Gẹgẹ bi wọn se wi, awọn n tẹsiwaju pẹlu iwọde ti awọn n se kiri origun mẹrẹẹrin ilẹ Yoruba fun idasilẹ orilẹede Oduduwa lo gbe awọn wa, ilu Akure si ni ọpọn sun kan.
Iwọde naa, ti ẹgbẹ Ilana Omo Oduduwa n se agbatẹru rẹ wa fọwọ gbaya pe ko ni si iporogan kankan lasiko iwọde alaafia naa.

Ọpọ wọn to ba wa sọrọ lo ni iya ti pọ ju, to n jẹ iran Yoruba ni awọn se fẹ ki ipinya wa, ki ẹkun iwọ oorun Naijiria si da duro.
Awọn ọlọkada, awọn obinrin, gende atawọn agbaagbaa lo peju sibi iwọ̀de naa pẹlu oniruuru akọle lọwọ wọn.

Ìwọde Yoruba Nation ń tẹ̀síwájú ní Ondo ní ọ̀la- Ilana omo Oodua
Ilana omo Oodua kede pe iwode ita gbangba fun Yoruba Nation ti won ti bẹ̀rẹ̀ yoo tesiwaju ni ipinle Ondo ni ọ̀la, ọjọ̀ Abameta, ọjọ̀ kejilelogun, osu karun un, ọdún 2021.
Won ni nilu Akure to jẹ́ olu ilu Ondo ni yoo ti waye.

Oríṣun àwòrán, Oodua Nation
Won ni iwode naa yoo waye pẹ̀lu atileyin alaga Ojogbon Banji Akintoye.
Awon to n seto ipade iat gbangba naa ni ko ni mu iwa ipa tabi itajesilẹ̀ dani rara nitori pe iwode alaafia lati pe fun orile-ede Oodua ni won fẹ́ se.
- Wíwá lórí Twitter, Facebook àti Instagram ní gbogbo ìgbà máa ń pa àyànmọ́ ẹ̀dá- Oyedepo
- Ìwọde Yoruba Nation ń tẹ̀síwájú ní Ondo ní ọ̀la- Ilana omo Oodua
- Irọ́ ni, àwa kọ́ la bèèrè fún nọ́mbà IMEI lọ́wọ́ àwon olùgbé Nàìjíríà- NCC
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo ti fòfin de lílọ àti bíbọ̀ ọkọ̀ láti aago mẹ́fà sí mẹ́ta ọ̀sán nítorí ìdìbò ọ̀la
- Àwọn olórí ìjọ méjì ni wọn jí gbé ní ìjọ àgùdà ní Katsina- Rev Fr Chris



















