Katsina Kidnap: Àwọn olórí ìjọ àgùdù méjì ni wọn jí gbé ni Katsina, ṣùgbọ́n- Rev Fr Chris

Àwọn olórí ìjọ méjì ni wọn jí gbé ní ìjọ àgùdà ní Katsina- Rev Fr Chris

Oríṣun àwòrán, Rev. Fr. Cornelius Tagwai,

Rev Fr Chris Omotosho, tó jẹ́ adarí ìbànisọrọ̀ ìjọ Aguda ti Sokoto ní Nàìjíríà ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé wọ́n jí àwọn olórí ìjọ méjì gbé nígbà tí àwọn ajínígbé kọlu ìjọ St Vincent Catholic Church Malunfashi, Ìpínlẹ̀ Katsina lówùrọ̀ ọjọ́ Ẹtì.

Fada Joe Keke ẹni ọdún márùnléláádọ́rin àti Fada Alphonus Bello ẹni ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n.

Sùgbọ́n ó ṣeni láànú pé, òkú Fada Bello ni wọn pada rí nínú oko rúsúrúsú kan ní ẹyin sọ́ọ̀sì, sùgbọ́n wọ́n ji Fada Keke gbé lọ.

Gẹ́gẹ́ bi Omotosho ṣe sọ, àwọn ajínígbé náà kò tíi kan sí ìjọ tàbi ẹbi nígbà ti ìròyìn yìí jáde.

Agbẹnusọ ọlọ́paàá ni ìpínlẹ̀ Katsina Gambo Isah, ko gbé ago rẹ̀ laásìkò láti fi ìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ nígbà tí a ń kọ ìròyìn yìí. Sùgbọ́n àwọn ìwé iròyìn ìbílẹ̀, sọ pé ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé, àti pé ọlapàá ń ṣiṣẹ́ takuntakun láti lépa àwọn ọdaran náà, àti láti mú olórí ìjọ naa pada wále láàfíà.

Ìjínigbé ti di ǹkan to gbòde ni ìpínlẹ̀ Katsina, tó jẹ́ ìpińlẹ̀ ti ààrẹ Muhamadu Buhari

O ti di ìgbà méjì báyìí tí ikọlu yóò wáyé ni agbègbè náà pàápàá jùlọ ìhà tó jẹ́ pé àwọn mùsùlùmmí ló pọ̀ níbẹ̀.

Ẹ̀wẹ̀ ìjọ Aguda jakèjádò Nàìjíríà ni àwọn kìí san owó ìtúsílẹ̀ ti wọ́n ba jí Bísọ̀ọ̀bù àti katkis gbé.