Israel-Palestinian conflict: Ẹ wo bí ìgbé ayé aráàlú ní Gaza ṣe dà lẹ́yìn ìkọlù

Ọmọkunrin kan to n kiri ọja

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ija nla to waye laarin Gaza ati Israeli ti mu ki Ajọ Iṣọkan Agbaye, UN kede wi pe ti wọn ko ba ṣọra, ogun abẹle ti agbara orilẹede mejeeji ko le e ka, yoo bẹ silẹ nibẹ.

Orilẹede Egypt lo n ṣe akoso Gaza, ki orilẹede Israel to ja ogun lati gba isakoso agbegbe Gaza ni ọdun 1967, amọ Israel yọ ikọ ọmọogun rẹ ati awọn Jew to le ni ẹgbẹrun meje to n gbe nibẹ kuro ni ọdun 2005.

Awọn ajijagbara Hamas lo gba ijọba agbegbe yii lẹyin ti wọn gbajọba lọwọ awọn adari ilẹ Palestine Authority(PA) lasiko ogun to bẹ silẹ ni ọdun 2007.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lati igba naa ni Israel ati Egypt ti dẹkun bi awọn eniyan ṣe n jade ati wọle ni agbegbe naa, to fi mọ bi ẹru ati awọn ohun ini ṣe n wọle-jade ni agbegbe naa.

Awọn ajijagbara Hamas doju ija kọ Israel ni ọdun 2014 , ti ọpọ ẹmi si lọ si iṣẹlẹ naa, ko to di wi pe ija miran bẹ silẹ ni ọdun 2021.

Lara ile ti ado oloro bajẹ ni agbegbe Gaza

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ki lo fa ija to ṣẹṣẹ waye ni Oṣu Karun, Ọdun 2021?

Ija laarin awọn ajijagbara Hamas ati Israeli bẹrẹ, lẹyin ti awon ara Palestine to n gbe ni East Jerusalem bẹrẹ si ni fa rogbodiyan lori awọn Ilẹ Mimọ to wa ni agbegbe naa.

Awọn ilẹ mimọ naa si lo se iyebiye si awọn Musulumi ati awọn ara Jew to n gbe lagbegbe Gaza.

Ọjọ Kẹwaa, Oṣu Karun un, ni awọn ajijagbara Hamas bẹrẹ si ni ju ado oloro rọkẹẹti, ti wọn fi kilọ fun awọn sọja ilẹ Israel pe ki wọn le awọn eniyan wọn kuro ni agbegbe naa, ko to di wi pe Israel naa bẹrẹ si ni kọju ija si Hamas.

Ikọlu to waye laarin Israel ati Palestine yii si ti ni ipa nla lori awọn eeyan to n gbe lagbegbe Gaza, diẹ lara ipenija ti wọn n koju lati ipasẹ ikọlu naa ree:

Ado oloro rọkẹẹti ba opo ina jẹ

Ina ọba ṣọwọn fun awọn ara agbegbe Gaza, ko to di wi pe ija bẹ silẹ laarin Isreal ati Hamas, eyi to wa mu ki ina ọba to ma n wa fun wakati mẹjọ tẹlẹ, ma a wa bayii fun wakati mẹta pere.

Bakan naa ni ẹrọ alupupu ati gẹnẹratọ ti wọn n lo lati fi pese ina ṣọwọn nitori ibode ti Isreal ati Egypt ti mọ awọn ara Gaza, nitori awọn ajijagbara Hamas.

Ina ti ko si ni Gaza mu ki igbe aye araalu dẹnu kọlẹ

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ibode titi ni gbogbo igba

Lati igba ti Hamas ti gba isakoso Gaza ni ọdun 2007, ni orilẹede Egypt ti ti ibode pẹlu Gaza.

Ni ọdun to kọja ni wọn tun ti ibode naa nitori ajakalẹ arun Coronavirus to bẹ silẹ kaakiri agbaye.

Ni ọdun 2019, eniyan to to ẹgbẹrun mejidinlọgọrin lo kuro ni Gaza ni ọgọọrọ, ko to di wi pe o bẹrẹ si ni dinku ni bi ọdun to kọja.

Ki ija to bẹ silẹ ni saa yii, wọn n gba Ajọ Iṣọkan Agbaye laaye lati gbe ounjẹ ranṣẹ si awọn eniyan, amọ wọn ko gba ki awọn eniyan kuro ninu ilu naa.

Ọdun 2007 ni ilẹ Egypt ti gbe ẹnu ibode rẹ plu Gaza ti pa

Oríṣun àwòrán, AFP/Getty

Orilẹede Israel ba awọn oju ọna abẹ ilẹ ti Hamas se jẹ

Ida ọgọrin awọn ara Gaza ni wọn nilo iranwọ ounjẹ lojoojumọ nitori iya ati iṣẹ to n ba wọn finra nibẹ.

Idena ti orilẹede Israel ṣe, nipa bo se kọ lati jẹ ki iranwọ de ọdọ awọn ara Gaza, lo ṣokunfa bii awọn eniyan ibẹ ko fi le ṣe kara-kata kankan.

Lọna ati bori idojukọ yii ni Hamas fi gbẹ oju ọna si isalẹ ilẹ, ki ounjẹ ati ohun ija le ma a wọle sibẹ lore-koore.

Wọn gbẹ iho ilẹ lati la ọna fi maa gbe oniruuru eroja atawọn ohun ija oloro wọle ni Gaza

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ainile lori awọn ara ile Gaza

Gaza jẹ ọkan lara awọn orilẹede to ni awọn araalu to pọju lọ lagbaye, ti wọn si fun ara wọn jọ papọ si ojukan.

Ajọ Iṣọkan Agbaye, UN ni o to awọn ogunlende bii ẹgbẹrun lọna ẹgbẹta, ti wọn n gbe ni agbegbe Gaza ati awọn ibudo ogunlende mii ni agbegbe naa.

O le ni ẹgbẹrun marun si ẹgbẹrun mẹsan awọn eniyan ti wọn n gbe kilomita kan, eleyii to fẹrẹ to iye eniyan to n gbe ni ilu London.

Amọ, Ajọ UN ni o le ni ogoje ile to wo lasiko ti orilẹede Israel sigun bo Gaza ni ọdun 2014, ti ẹgbẹgbẹrun eniyan si nilo iranwọ ile gbigbe tabi lati tun ile wọn kọ.

Eto ilera ti ko kunjuwọn

Eto ilera ile Gaza ku diẹ kaato nitori idena lati orilẹede Israel ati Egypt ti ko jẹ ki awọn eniyan lẹtọ si eto ilera pipe ni agbegbe naa.

Ajọ Iṣọkan Agbaye,UN n pese ile iwosan bii mejilelogun fun awọn eniyan, amọ ija laarin ilẹ Israel ati Palestine ti mu ki awọn ile iwosan yii wo palẹ.

Ọpọ eeyan to fi mọ awọn ọmọde ni ado oloro ba lasiko ija Israel ati Gaza

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ajọ Eleto Ilera Lagbaye,WHO ni eyi ti ṣokunfa ki adinku ba fifun awọn eniyan ni abẹrẹ ajẹsara tako aarun Coronavirus to peleke si ni agbegbe naa.

Ounjẹ ṣọwọn ni Gaza

O kere tan miliọnu kan eniyan ni ko ri ounjẹ jẹ lasiko ni Gaza, ti wọn si nilo iranwọ ni ojoojumọ.

Lore-koore ni wọn n ṣi ibode lati fun awọn ọkọ laaye lati ko ounjẹ wole si agbegbe naa.

O ṣoro fun wọn lati ṣiṣẹ agbẹ nitori ija pẹlu Israel, bẹẹ si ni wọn ko le e pa ẹja ni odo nitori ala ti wọn ni pẹlu Isreal.

Omi mimu naa ṣọwọn nibẹ nitori omi okun to kun fun iyọ ni wọn ni, ti ko si yẹ fun mimu.

Awọn eniyan agbegbe yii ki n ri omi taara pọn, bi ko ṣe pe igba ti ina ijọba ba wa laarin wakati mẹfa si mẹjọ.

Amọ, ija to waye yii tun ti tubọ mu ifasẹyin ba ina ọba ni Gaza.

Ounjẹ ati omi mimu sọwọn ni agbegbe Gaza

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ileewe di ile gbigbe fun awọn ara Gaza

Ọpọlọpọ awọn ọmọde ni ilu Gaza n lọ si ileewe ti Ajọ Iṣọkan Agbaye, UN da silẹ ni agbegbe naa.

Amọ, awọn ileewe yii ni wọn n lo gẹgẹ bi ibugbe fun awọn ogunlende ti wọn sa kuro nile wọn.

Awọn olotu ilẹ Palestine ni ida mẹrinlelọgọta ile iwe naa ni awọn eniyan ti ma n lọ si ileewe ni arọ ati alẹ.

Ọpọ idile lo n gbe ni agọ awọn atipo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọpọ ọdọ ni ko ri iṣẹ ṣe ni Gaza

Gaza pẹlu awọn orilẹede to ni awọn ọdọ to pọjulọ ni agbaye, ti ọpọlọpọ wọn si ju ẹni ọdun marundinlọgbọn lọ.

Amọ, ohun to buru jai nipe ọpọlọpọ wọn ni ko ni iṣẹ lọwọ.

Arun Coronavirus pẹlu ohun to fa akọba ainiṣẹ fun wọn nitori ọpọlọpọ padanu iṣẹ rẹ lasiko ti ajakalẹ aarun naa bẹ silẹ.

Titi di asiko yii, awọn ajijagbara Hamas ti orilẹede Isreal, Amerika, UK, Yuroopu kasi ikọ agbesunmọmi lo n ṣakoso ibẹ.

Ọpọ eeyan lo n se atipo ni awọn ileẹkọ to jẹ ti ajọ isọkan agbaye UN nitori akọtun ikọlu yii

Oríṣun àwòrán, Getty Images