Oshodi Military Crisis: Kí ni ìdí abájọ wàhálà lórí ikú ọmọogun òfúrufú l'Oshodi?

Aworan Oshodi nilu Eko

Oríṣun àwòrán, other

Ọpọlọpọ awọn olugbe Oshodi nipinlẹ Eko atawọn to n wọ ọkọ nibẹ ni wọn sa asala fun ẹmi wọn lọjọbọ, lori wahala to bẹ silẹ laarin awọn ọmọogun kan atawọn janduku lagbegbe naa.

Agbegbe Mosafẹjọ ni Oshodi ni iṣẹlẹ naa ti waye.

Gẹgẹ bi awọn iroyin abẹle kan ṣe sọ, awọn ologun naa ya bo Oshodi "lati gbẹsan iku ọmọogun ofurufu kan, ti awọn janduku pa lagbegbe naa"

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọpọlọpọ ọkọ ero ni wọn bajẹ tawọn awakọ ero si sa fi skọ silẹ, bẹẹ lawọn ọlọja pẹlu juba ehoro ti wọn si fi ṣọọbu wọn silẹ.

Awọn miran sọ pe wọn ri oku ọmọogun naa ni agbegbe naa ti awọn eeyan si fura pe awọn janduku lo gba ẹmi rẹ ki wsn to fi awọn ṣọja naa ṣọwọ sibẹ lati lọ gbe oku rẹ ki wọn si le awọn janduku kuro lagbegbe naa.

Amọṣa ileeṣẹ ọlọpaa ti fi atẹjade kan sita pe awọn ti bẹrẹ si ni wadi ohun gan to fa wahala naa.

Àkọlé fídíò, Oyo LG Polls: OYSIEC ní APC ló yẹ kò bẹ aráàlú lórí àṣìṣe rẹ̀ nípa ìbò ìjọba ìbílẹ̀

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Eko, Muyiwa Adejọbi ṣalaye ninu atẹjade naa pe, " Ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Eko gbọ si wahala to waye lagbegbe Capa Park/Mosafẹjọ ni Oshodi loni Ọjọbọ ogunjọ oṣu karun un ọdun 2021 ni agogo meje owurọ. A ti da alaafia pada si agbegbe naa, a si n ṣe iwadii lori rẹ.

A rọ awọn olugbe ilu Eko lati maa ba iṣẹ wọn ls laisi wahala."