Adebayo Shittu: Ajimobi ló ṣẹ̀ mí, n kò ṣẹ Ajimobi, ipò kan náà la jọ ń wá àmọ́ kò fẹ́ mi ní ìjọba

Oríṣun àwòrán, @adebayoshittuHM
Minisita tẹlẹ fun eto ibaraẹnisọrọ, ti tun se oludije tẹlẹ fun ipo gomina nipinlẹ Oyo, Amofin Adebayo Shittu, ti sọrọ lori bi wọn se yọ nipo Minisita.
Shittu lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ lasiko eto ifọrọwanilẹnuwo kan salaye lori ẹsun aisinru ilu (NYSC) ti wọn fi kan, ati bo se kuro ni ipo minisita.
Shittu ni kii se oun nikan ni oloselu ti ko sinru ilu, ki oun to de ipo oselu nitori gomina ana nipinlẹ Oyo, Abiola Ajimobi gan ko se NYSC, to fi di Sẹnetọ ati gomina.
Bakan naa lo mẹnuba pe, wọn gbe gomina Dapo Abiodun lọ sile ẹjọ lori irufẹ ẹsun aisinru ilu yii, to si jare bọ nitori ofin ti sọ irufẹ iwe ẹri to kere ju, ti oludije fun ipo oselu kan gbọdọ ni.
"O daju pe iwa magomago to waye ninu ẹgbẹ oselu APC lasiko ti Adams Oshiomole jẹ alaga lo mu ko rọrun fawọn ọta mi lati bori mi.
Ki lo de ti wọn fi yọ mi nipo minisita nitori ẹsun pe n ko sinru ilu, se bi Abiola Ajimobi ko se NYSC, to si se gomina ati Sẹnetọ.
Bakan naa, Dapo Abiodun niyẹn, wọn gbe oun naa lọ sile ẹjọ tori ẹsun pe ko sinru ilu, ti wọn ko si tori eyi gba ipo lọwọ rẹ, ofin sa ti sọ iwe ẹri to kere ju fun oludije kan lati ni."
Amofin Shittu, ẹni to tun sisọ loju rẹ pe, oun yoo tun dije fun ipo gomina nipinlẹ Oyo lọdun 2023, wa fi ọwọ sọya pe bi Ọlọrun ba fẹran ipinlẹ Oyo, yoo gba oun laaye lati di gomina.
"Ni kete ti mo pari NYSC ni wọn dibo yan mi sile asofin ipinlẹ Oyo amọ ọrọ naa ti wa nile ẹjọ bayii."
Abiola Ajimobi sẹ mi, tori a dijọ n wa ipo kanna, ko fẹ mi ninu ijọba
Nigba to n sọrọ lori ajọsepọ rẹ pẹlu Abiola Ajimọbi, Adebayo Shittu ni gomina ana naa ti di oloogbe, ko si ni dara ki oun sọ awọn nnkan ti ko ni le fesi le lori.
O ni ipo kan soso ni oun ati Ajimobi dijọ n le, eyi to mu ki awọn mejeeji da bi orogun, oun ko si sẹ Ajimobi amọ Ajimobi sẹ oun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ṣé lóòtọ́ ni mọ́tò tó kọ́wọ̀rín pẹ̀lú Seyi Makinde pa ọmọdébìnrin kan l'Ogbomoso?
- Ìwádìí rèé lórí gbas-gbos tó wáyé lórí ikú ọmọogun òfúrufú l'Oshodi l‘Ọ́jọ́bọ
- Ó yẹ kí Aàrẹ Buhari yọ Malami nípò lórí ọ̀rọ̀ tó sọ nípa ẹ̀yà Igbo àti àwọn darandaran- Amofin Adeoye
- Ìdí rèé tí mo fí kọ PDP sílẹ, lọ darapọ̀ mọ́ APC- Ben Ayade
- Ọlọ́pàá ní ká san ₦500,000 fún béèlì baba Ijesha, mo yarí torí ọ̀fẹ́ ni béèlì - Amòfin Ogunlana
- Ìbúgbàmù wáyé nílé ìyáwé-kàwé Obasanjo, mú ẹ̀mí ènìyàn kan lọ
- Princess jèbùrẹ́, ọ̀rọ̀ Baba Ijesha gbóná ju èrò ọ̀pọ̀ èèyàn lọ - Adewale Eleso
Minisita tẹlẹ naa fikun pe, oun ati Baba Abiola Ajimobi, eyiun Alhaji Ganiyu Ajimobi ni awọn dijọ wa nile asofin ipinlẹ Oyo lasiko kanna, ti baba naa si mu oun bii ọmọ.
O ni o ya oun lẹnu pe iru ọmọ baba naa lo wa n hu awọn iwa to hu naa si oun.
"Ajimobi mọ pe mo ni iwa ikoraẹninijanu pupọ, ti mo si korira iwa ijẹgaba lori ẹni ati iwa ipa, ti ko si fẹ ki n de ipo ijọba, amọ gbogbo rẹ ti pari bayii.
Wọn ro pe maa ran Ajimobi ni ẹwọn, ti mo ba fi di gomina lẹyin rẹ, ni wọn se gbogun ti mi.
Mo ti se ipade pẹlu opo Ajimobi, ohun to si se koko bayii ni bi a se jẹ ki ipinlẹ Oyo lọ siwaju."
Mo kabamọ pe emi ati Ajimobi ko pari aawọ aarin wa, ko to jade laye
Bakan naa ni amofin Shittu salaye pe oun ati oloogbe Abiola Ajimobi ko pari aawọ to wa ni aarin awọn mejeeji, ko to di pe ọlọjọ de si.
O fikun pe, o se ni laanu pe awọn agbaagbaa inu ẹgbẹ to yẹ ko pe awọn joko lati pari aawọ naa, ko sọ bẹẹ, eyi ti ko daa to.
"Emi ati Ajimobi pade nile itura kan nilu Eko nigba to ku bii osu mẹrin ko jade laye, ti a si bẹrẹ si fi ara wa se yẹyẹ.
Mo kabamọ pe awa mejeeji ko pari ija aarin wa, ko to jade laye, awọn agbaagba to si yẹ ko ba awa mejeeji pari ija, ni ko se bẹẹ.



















