Oyo LG Polls: OYSIEC ní APC ló yẹ kò bẹ aráàlú lórí àṣìṣe rẹ̀ nípa ìbò ìjọba ìbílẹ̀

Àkọlé fídíò, Oyo LG Polls: OYSIEC ní APC ló yẹ kò bẹ aráàlú lórí àṣìṣe rẹ̀ nípa ìbò ìjọba ìbílẹ̀

Awuyewuye to n waye lori eto idibo ijọba ibilẹ ti yoo waye lọjọ Satide ọla nipinlẹ Oyo si n gbona jain jain ni.

Idi ni pe ẹgbẹ oselu APC, to jẹ ẹgbẹ oselu alatako gboogi nipinlẹ Oyo si n figbe ta pe ijọba gbọdọ wọgile eto idibo naa ni, ki oun le ni anfaani lati kopa ninu rẹ.

APC ni ẹjọ ti oun gbe lọ sile ẹjọ lori bi gomina Seyi Makinde se juwe ọna ile fun awọn alaga ijọba ibilẹ ti Abiola Ajimọbi yan sipo, lo mu ki oun ma le se igbaradi fun eto idibo ijọba ibilẹ naa.

Eyi lo mu ki BBC Yoruba tọ awọn alẹnulọrọ lori eto idibo naa lọ lati m,ọ ohun to faa ti awuyewuye naa fi n tẹ siwaju atawọn ọna abayọ si.

Lara awọn to si salaye ẹdun ọkan wọn ati awijare ni Alaga ajọ eleto idibo nipinlẹ Oyo, amofin Isiaka Olagunju, alukoro fun ẹgbẹ oselu PDP, Enjinia Akeem Olatunji ati alaga fun ẹgbẹ awọn alaga ijọba ibilẹ ninu ẹgbẹ APC ti wọn yọ nipo, Ayodeji Abass Aleshiloye.

Alaye ree lori bi awọn eeyan naa se n gba ọrọ idibo ijọba ibilẹ mọ ara wọn lọwọ.