Makinde vs Algon: Iléẹjọ́ ní bí Makinde ṣe lé àwọn alága APC l'Oyo lọ lòdì sófin

Seyi Makinde atawọn alaga kansu Oyo to da duro

Oríṣun àwòrán, Facebook/Seyi Makinde

Ileẹjọ to ga julọ lorilẹede Naijiria ti dajọ pe igbesẹ Gomina Seyi Makinde ipinlẹ Oyo lati le awọn alaga ati kansilọ ijọba ibilẹ nipinlẹ Oyo lọ lodi sofin.

Ileẹjọ tun ni igbesẹ Makinde lati fi awọn alaga fidihẹ rọpo awọn alaga naa lodi si ofin pẹlu.

Ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ nipinlẹ Oyo, ALGON gbe ijọba ipinlẹ Oyo lọ si ileẹjọ to ga julọ lẹyin ti ileẹjọ kotẹmilọrun buwọlu igbesẹ Makinde to da wọn duro lẹnu iṣẹ.

Ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu karun un ọdun 2019 ni Gomina Makinde dawọn alaga atawọn kansilọ naa duro.

Amọ, ileẹjọ to ga julọ paṣẹ pe ijọba ipinlẹ Oyo gbọdọ san gbogbo owo oṣu ati ajẹmọnu awọn alaga kansu naa fun wọn patapata.

Ileẹjọ sọ ninu idajọ rẹ pe owo naa gbọdọ jẹ sisan titi oṣu kẹjọ, bi bẹẹ kọọ afojudi ileẹjọ ni ọrọ naa yoo jẹ.

Bakan naa ni ileẹjọ paṣẹ pe ki Makinde san ogun miliọnu naira nitori iwa aitọ to hu nipa lile awọn alaga atawọn kansilọ ẹgbẹ oṣelu APC lọ.

Ọdun 2018 ni wọn dibo yan awọn alaga atawọn kansilọ naa ki Makinde to dawọn duro lọdun 2019.