Hadiza Bala Usman: Kí ló dé tí Buhari ní kí olùdarí NPA lọ rọọ́kun nílé?

Oríṣun àwòrán, Twitter/Hadiza Bala Usman
Ojumọ kan ara kan.Ni ijọba aarẹ Buhari orileede Naijiria ara ki tan nile alara.
Eyi to gbode bayi tawọn eeyan n jẹ lẹnu ni ikede to jade lati ọdọ agbẹnusọ aarẹ pe ki oludari ileesẹ to n mojuto ẹru to n gba ibudokọ ọkọ oju omi wọ Naijiria,NPA lọ rọọkun nile.
Garba Shehu ninu atẹjade taa n wi yi ni aarẹ ti buwọlu aba ti Minisita feto irina Rotimi Amaechi da lori idasilẹ igbimọ iwadii ti yoo tọ pinpin akoso ileesẹ yi labẹ akoso Hadiza Bala Usman.
- Ìjínigbé àti ìdigunjalè kò sí ní ìkáwọ́ ìjọba àpapọ̀ - Lai Mohammed
- Ikú tó fẹ́ pa Opeyemi Ayeola ṣí i ní fìlà, ló bá ń kọrin ẹ fọ̀rọ̀ mi kọ́gbọ́n
- Obìnrin tó bá ṣí orí wọ Ààfin Deji Akure, Ọba á gbẹsẹ lé e, tóò bá wá lọ rẹwà ...
- Àwọn agbébọn tún ti jí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ míì gbé ní ìpínlẹ̀ Abia
- Ikú Dare Adeboye kò ní ǹkankan ṣe pẹ̀lú Covid-19, a bẹ̀bẹ̀ láti dá wà lákòókò yìí - Ẹbi Adeboye
- Mo dákú rangbọndan lẹ̀yìn tí amúgbálẹ́gbẹ gómìnà Akeredolu fún mi ní ìgbájú olóyì - Aláboyún
- Àwọn agbébọn tún ti jí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ míì gbé ní ìpínlẹ̀ Abia
- A furasí pé àwọn kan mọ̀ọ́mọ̀ sọ iná sí Ọ̀já aṣọ Kairo l'Oshodi - LASEMA
Yatọ si eyi, atẹjade naa ni aarẹ pasẹ ki Hadiza lo rọọkun nile lopin igba ti iwadii yoo fi waye.
"Ọgbẹni Mohammed Koko ni yoo maa dele nipo naa lasiko iwadii yi.''
Pẹlu atẹjade yi, a ko ri pato nkan ti wọn fi n tori rẹ tọ pinpin ileesẹ yi amọ awa naa fimu finlẹ diẹ la ba ni ka tan imọlẹ si awọn nkankan nipa Hadiza Bala Usman ti o seese ki ẹ maa mọ.
Die ree nipa ohun to yẹ ki ẹ mọ nipa
Lagbo Oselu
O jẹ oloselu to ti bẹrẹ si ni sisẹ gẹgẹ bi alasẹ ileesẹ NPA lati ọdun 2016.
Saaju igba naa lọdun 1999 o lo ọdun kan ni ajọ to n mojuto idagbasoke ijọba awarawa ni Zaria gẹgẹ bi olukọsẹ.
Lẹyin igba naa ni o sisẹ pẹlu ẹka ijọba ti wọn n pe ni BPE laarin osu Kẹfa ọdun 2000 titi di 2004.
Laarin Osu kẹwa 2004 si osu Kini ọdun 2008 o di ipo oluranlọwọ pataki si Minisita lori amojuto ise akansẹ ni Abuja labẹ ajọ UNDP
O dije dupo asoju ẹkun idibo Musawa/Matazu gẹgẹ bi oludije labẹ asia ẹgbẹ oselu APC lọdun 2011 sugbọn o fidirẹmi.
Lẹyin igba naa lo dara pọ mọ ẹgbẹ ti ko ni se pẹlu ijọba to n gbaju mọ isakoso orileede Naijiria bo ti se yẹ taa mọ si Good Governance Group for Nigeria.
Laarin 2011 si 2015 lo fi ba wọn sisẹ
Ipolongo Bring Back Our Girls
Oun ati Aisha Yesufu ni wọn jijọ da ipolongo Bring Back Our Girls kalẹ lọdun 2014
Wọn da ikọ yi silẹ lẹyin ijingbe awọn akẹkọbinrin Chibok lati le pe fun idoola awọn akẹkọbinrin wọn yi.
Pẹlu awọn oluwọde miran wọn fi ohun wọn polongo nipa awọn akẹkọbinrin yi.
Nibẹ lọpọ eeyan ni Naijiria ti mọ ẹni ti wọn n pe ni Hadiza Baala ati Aisha Yesufu.
Koda nigba to gba ipo gẹgẹ bi oludari NPA o si n kopa ninu awọn eto Bring back our Girls nipa sise eto ipade laarin ijọba Naijiria ati awọn obi awọn akẹkọọ ti wọn ji gbe yi.
O darapọ mọ BBOG lati se iwọde lọdun 2016.
Ibasepọ rẹ pẹlu Gomina El Rufai
Wọlewọde loun ati Gomina ipinlẹ Kaduna Nasir El Rufai.
Ibasepọ wọn yi si ti bẹrẹ lati igba ti o ti sisẹ labẹ rẹ gẹgẹ bi ọga agba ileesẹ BPE lasiko ijọba Olusegun Obasanjo.
Eyi lo mu ki pupọ awọn eeyan maa ni El Rufai fi forukọ rẹ sọwọ gẹgẹ bi oludari ileesẹ NPA.
Koda El Rufai yan si ipo olori awọn osisẹ ile ijọba lẹyin to jaweolubori ninu idibo Gomina ni ọdun 2015.
Oun ni obinrin akọkọ ti wọn yoo yan si ipo yi ninu akọsilẹ ipinlẹ Kaduna.
Idile lọbalọba lo ti wa
Hadiza wa lati ile ọlọba awọn Fulani Sullubawa ti wọn ti n jọba ni Katsina lati ọjọ to ti pẹ.
Baba to bi Ọjọgbọn Bala Usman ni ọmọọmọ Emir Katsina Muhammadu Dikko.
Bakan naa baba to bi iya baba rẹ rẹ ni o jẹ Emir kẹwaaa ti elyi naa si mu ki oun gaan wa lati idile ọlọba.
Ilumọọka ni Baba to bi
Baba Hadiza Bala Usman,oloogbe Ọjọgbọn Bala Usman figba kan jẹ ọkan lara awọn eekan to wa lati ariwa Naijiria.
Ọjọgbọn onimọ ẹkọ itan yi lọpọ sapejuwe rẹ gẹgẹ bi alakatakiti to se pe ọpọ ọrọ rẹ́ a maa tako ijọba to wa lode nigba naa.
O figba kan sisẹ gẹgẹ bi akọwe ijọba Kaduna lasiko ijọba Balarabe Musa ni saa keji ijọba awarawa ni Naijiria.
O fẹ oludamọran si aarẹ
Tanimu Bala Kurfi ni ọkọ ti Hadiza Bala Usman fẹ tẹlẹ to si jẹ oludamọran si aarẹ Naijiria tẹlẹ Umaru Musa Yar Adua.
Gẹgẹ bi wọn ti se lorukọ ni mọlẹbi Hadiza, bẹẹ naa ni orukọ mọlẹbi Tanimu jẹ eyi ti ọpọ mọ ni Naijiria ti ọkọ rẹ si di orisi ipo mu ni Naijiria.
Awọn mejeeji bimọ ọkunrin meji ki wọn to pinya.
Aarẹ Buhari yan Hadiza sipo oludari ileesẹ NPA ni osu Kẹfa ọdun 2016.
Ọpọlọpọ awuyewuye lo ba iyansipo yi wa nitori awọn kan sọ pe ko kaju osunwọn lati di ipo naa mu.












