Akure Oloyemekun: Ṣé ẹ ti gbọ́ nípa Ua Agbeto rí níbí tí ìtọ̀ kìí rùn bó bá ṣe pọ̀ tó?

Àkọlé fídíò, 'Ẹ kálọ sí ìlú mi'... Ètò ńlá tó bẹ̀ sílẹ̀ kìjà lórí BBC Yorùbá

Ṣé ẹ ti gbọ awọn itan kankakanka nipa iṣẹdalẹ ilu Akurẹ?

BBC Yoruba ba eeyan ilu Akure rinrinajo lọ si ilu nla naa koda to fi mọ awọn kọrọ ilu Akure.

A ni ifọrọwerọ pẹlu Deji, Ọba ilu Akure to sọ idi ti gbogbo Ọba ilu Akurẹ fi n jẹ Déjì lái ṣe Alakurẹ.

Ọna kan wa ninu aafin Deji Akure to ṣe pataki leyi to jẹ wipe ẹẹkan ṣoṣo ni Kabiyesi lee gba ibẹ ni igbesi aye rẹ to jẹ pe igba to ba ṣẹṣẹ jba ti wọn a mu u wọ inu aafin.

Aafin Deji

Ṣe ẹ tun ti gbọ nipa ibi iṣẹmbaye to n jẹ Ua Agbetọ nibi ti ẹ o le gbọ oorun itọ kankan ko si bi ọgọọrọ eeyan ba ṣe tọ sibẹ to.

Ẹ ba wa kalọ ninu fidio yii si awọn ibi kọlọfin ati ibi gbangba ilu nla nni, Akurẹ.

Ilu Akure