New Minimum Wage: Aráàlú fẹ́ kíjọba dín owó olóṣèlú kù dípò owó oṣù òṣìṣẹ́

Oríṣun àwòrán, NLC
Awọn ọmọ Naijiria fesi lori ẹrọ ayelujara lori igbesẹ ijọba lati din owo oṣu oṣiṣẹ ku lori ọrọ aje to dẹnukọlẹ
Igbe ilu o fararọ ni awọn eniyan nke ni Naijiria pẹlu ariwo pe ki ijọba wa nkan ṣe si ọwọngogo owo ounjẹ, ko ma si gbero lati din owo oṣu oṣiṣẹ, ti ko to nkankan ku.
Ọrọ yii ati bẹẹ bẹẹ lọ ni awọn eniyan n fi ranṣẹ ni oju opo ikansiraẹni Facebook lati fi aidunnu wọn han si ijọba to wa lode yii lori bi nkan ko ṣe fararọ fun awọn eniyan.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Sunday Igboho, dẹ́kun ariwo fún ìyapa Nàíjíríà - YAF
- Ẹbí Fela Anikulapo yarí fún APC àti Tinubu torí èròjà ìpolongo ìbò
- Wo ọjọ́ gangan tí Pásítọ̀ Dare Adeboye ti jáde láyé, ẹgbẹ́ àwọn ọmọ Pásítọ̀ RCCG kéde
- Èèyàn kan kú nínú ìjà tó n wáyé ní Mile 12 láti bíi ọ̀sẹ̀ kan
- NECO gbé èsì ìdánwò ọdún 2020 jáde!
- Ganiyu fẹ́ na pápá bora lẹ́yìn tó gún ìya ìyàwó rẹ̀ lọ́bẹ pa lọ́sàán àwẹ, ọwọ́ bá tẹ̀ ẹ́
- Ṣé o mọ àwọn òrìṣà ìṣẹ̀mbáyé méje tó di ilẹ̀ gbogbo àgbáyé mú?
- Àwọn agbébọn tún ti jí ènìyàn tó lé ní 100 gbé lọ ní Nàìjíríà
Ijọba orileede Naijiria lo kede wi pe awọn n gbero lati din owo oṣu oṣiṣe ku nitori ọrọ aje ti dẹnukọle patapata ni Naijiria.
Amọ, ẹgbẹ oṣiṣẹ ni Naijiria to fi mọ awọn araalu lo fi lede wi pe, ko gbọdọ si ohun to jọ bẹẹ, afi ti ijọba ba fẹ din owo oṣu awọn oloṣelu ku.
Adeniji Olugbenga to sọrọ loju opo BBC News Yoruba ni owo awọn aṣofin ni Naijiria ju ti awọn oṣiṣẹ lọ ni ọna igba.
O ni nitori idi eyi, ki ijọba din owo oṣu wọn ku, ki wọn fi ti awọn oṣiṣẹ silẹ nitori owo ọhun ko to ra nkankan pẹlu ọwọngogo owo ounjẹ.
Bolaji Abdullateef ni ijọba fẹ sọ awọn oṣiṣẹ to ti talaka tẹlẹ di ekute sọọṣi ti ko tilẹ lee fi owo ra nkankan mọ ni ọja, nitori gbogbo rẹ ti dojuru patapata.
Ninu ọrọ tirẹ, Oko Oro Wumi beere pe se ni asiko ti gbogbo nkan wọn gogo yii ni ijọba n gbero lati din owo oṣu ku, nigba to si jẹ pe owo ori awọn oṣiṣẹ yii ni awọn adari Naijiria n na lai ṣiṣẹ fun un.
Adenike Ireoluwa Amoo ni owo oṣu ti awọn oṣiṣẹ n gba lọwọlọwọ ni Naijiria ko ka nkankan ati pe aanu Ọlọrun ni wọn fi n gbera, ti ọpọlọpọ oṣiṣẹ si ti di onigbese tan.
Pẹlu ibinu ni Olakunle Timothy Orokunbi fi sọ wi pe ki ijọba lọ din owo oṣu ti gomina kọọkan n gba ku pẹlu owo mọto wọn.
Bakan naa lo ni owo aṣọ ti wọn n wọ, owo ijoko ile awọn aṣofin ati owo oṣu awọn minisita ni ki ijọba lọ dinku, kii ṣe ti awọn oṣiṣẹ.
Amọ, arakunrin Olatunde Awe O'Connell ni ki ijọba Naijiria ṣe ohun gbogbo ti wọn ba le ṣe lati ri wi pe ọrọ aje to dẹnukọlẹ bọ si ipo pada ni Naijiria.

















