Covid-19 Pandemic funeral: Òkú àgbàlagbà ló di ǹkan táa lè mú lé ọwọ́ fi ráńṣẹ sí mọ̀lẹ́bí wọn yìí

Àkọlé fídíò, 'Iṣẹ wá burẹkẹ síi tórí Covid-19, owó ńlá ló wà nínú dídáná sun òkú, ìsìnkú Zoom, Live streaming'

"Àìmọ́yé àwọn èèyàn tó wá sọ́dọ̀ wa ló ń dúpẹ́ pé Covid-19 wà - Abáni ṣayẹyẹ ìsìnkú".

Awọn ayipada ti asiko ajakalẹ arun Covid-19 mu ba ilana isinku fun awọn eniyan Naijiria.

Adari ileeṣẹ eleto abani sinku kan, Bolanle Okusanya Feyita kẹnu bọ ọrọ pe iyatọ nla ti de ba ọja fun wọn gẹgẹ bii abanisinku.

Awọn abaniṣe ayẹyẹ oku

Gẹgẹ bo ṣe koba awọn ile isin igbagbọ bii ṣọọṣi ati mọṣalaṣi, bẹẹ naa lo ṣe koba awọn ileeṣẹ. Eyi to koba awọn abanisinku yii kii ṣe kekere rara.

Bolanle jẹ ko di mimọ pe o jẹ́ nkan aa riri tẹlẹ ki awọn idile kan ṣe adura nibi itẹ, ki wọn dẹ sinku lọsẹkẹsẹ.

Iru awọn iṣẹ tio wọn maa n ri gba ni ki wọn gbe oku jo lọ si le baba oku ati ile iya oku amọ iru iṣẹ yii ka ẹsẹ ko lasiko covid-19.

Paapaa awọn to jẹ pe oku ku si Naijiria amọ mọlẹbi rẹ wa lawọn orilẹede mii kaakiri agbaye, aye ati rinrinajo wa ṣe inawo rẹpẹtẹ ko si bo tilẹ jẹ pe owo wa to n gun wọ lara lati na fẹ na.

Ẹwẹ, are kenge mii to tun n waye nileeṣẹ awọn abaniṣayẹyẹ isinku yii ni ki wọn maa dana sun oku di eeru.

Ọrọ pọ lẹnu Bolanle Okusanya Feyita to ba BBC Yoruba sọrọ.

"Àwọn okú ọmọ Yoruba mii wa ti a fi eeru wọn ranṣẹ ti awọn ẹbi ṣẹ lọ sun si ilu wọn nigba ti eeyan ṣẹṣẹ n jade nigba ti Covid-29 rọlẹ".