Baba Ijesha: Yomi Fabiyi ní àwọn yóò ṣe ìwọ́de tí ọlọ́pàá kò bá mú àwọn àgbààgbà tó ló ọmọdé fún aṣemáṣe

Yomi Fabiyi ati Baba Ijesha

Ọrọ awuyewuye to n waye lori ọrọ Baba Ijesha ko tii jẹ rodo lọ mumi rara.

Idi ni pe gbajumọ osere tiata, Yomi Fabiyi si n leri leka pe oun ati awọn eeyan kan yoo se iwọde laarin ọjọ meje tako ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko.

Fabiyi ni iwọde naa yoo waye bi awọn ọlọpaa ko ba mu gbogbo awọn agbalagba to lo ọmọde, lati se akọsilẹ ẹri asemase fun Baba Ijesha.

Fabiyi lo fi ọrọ yii ransẹ si igboro lati oju opo Instagram rẹ, eyi to kọ sibẹ tente.

O ni awọn yoo sewọde alaafia ni Alausa ati lawọn agbegbe miran nipinlẹ Eko tako ọga agba ọlọpaa Eko

Ọrọ ti Yomi Fabiyi kọ

Oríṣun àwòrán, /Instagram

Bakan naa lo ni awọn yoo tun beere pe ki wọn gba isẹ lọwọ olori ẹka to wa feto idẹrun araalu nipinlẹ Eko nitori pe wọn ko mọ isẹ wọn bii isẹ.

"A ko le maa wo awọn eeyan yii niran lati maa fi owo ori araalu sofo, wọn ko mọ isẹ wọn doju ami.

A ja fun ọmọ kọọkan ti ko ni ẹsẹ lọrun, ti wọn ko naa ni rẹ. A si n se eleyi fun isisẹ sin ọmọniyan."

Àkọlé fídíò, 'Bàbá, orúkọ yín rèé nínú ìwé òṣìṣẹ́fẹ̀yìntì Nàìjíríà tó ti kú, kí 'ló ṣẹ́lẹ̀?'

Gbajumọ osere tiata naa fikun pe yoo dara ki awwọn eeyan naa se ohun to tọ lasiko, nitori iwọde naa ni yoo wa fun ọmọ kọọkan ti ko ni ẹsẹ lọrun, awọn jẹ wọn ni ojuse yii.

Yomi Fabiyi tun gbe imọran kalẹ pe yoo dara ka lo awọn ọdọ wa bo se yẹ, ojuse yii si ni oun yoo ri daju pe o fidi mulẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, Tóò bá fẹ́ràn àti máa pọ́n ọ̀rọ̀ tàbí èèyàn lé, ẹ̀kọ́ ráńpẹ́ yìí yóò wúlò fún ọ

Bẹẹ ba gbagbe, lati igba ti isẹlẹ ẹsun sise asemase pẹlu ọmọde ti wọn fi kan Baba Ijesha ti waye ni Yomi Fabiyi ko ti panumọ.

Amin iyasọtọ kan

Kò sí àwáwí fún ìwà Baba Ijesha àmọ... -Yomi Fabiyi

Yomi Fabiyi ati Baba Ijesha

Oríṣun àwòrán, Yomi Fabiyi

Saaju la ti sọ fun yin pe, gbajugbaja oṣere tiata, Yomi Fabiyi to n ja fun pe ki gbogbo eeyan farabalẹ tẹle ofin lori ọrọ Baba Ijesha ti fesi lori fọnran ti ile iroyin kan fi si ta lori Baba Ijesha.

"O ṣe ni laanu gidi gan bi mo ṣe wo fọnran CCTV nibi ti Ọgbẹni Lanre Omiyinka ti a mọ si Baba Ijesha ti fi ilọkulọ ibalopọ lọ ọmọdebinrin kan. Ko si awawi. Mo bu ẹnu atẹ lu u tori o ti ni loju o si ba ni lorukọ jẹ pẹlu".

Yomi Fabiyi ni oun ti farabalẹ duro de ohun to tọ gidi ki oun to sọrọ gẹgẹ Bi wọn ṣe n ṣe lawọn orilẹede to laju ti oun si wa ri i pe "eeyan kan ṣoṣo ti ọwọ rẹ mọ ninu kiko si gbaga ọlọpaa ni ọmọdebinrin naa".

Yomi Fabiyi ri i ninu fidio naa pe itasẹ agẹrẹ pọ daadaa latọdọ Baba Ijesha ninu fidio naa.

O ni ibeere to yẹ ki gbogbo eeyan maa bere ni pe "to ba ṣe ọmọ tirẹ obinrin ni ọmọbinrin naa, ṣe o lee jẹ ko tun iru iriri yẹn la kọja nitoripe o fẹ ni ẹri to daju.

Nitori eyi, o tun n funpe si awọn alaṣẹ to n ṣamojuto ohunkohun to n lọ sori ayelujara.

Yomi gba pe ofin ṣe pataki, paapaa nipa didaabo bo ẹtọ awọn ọmọde ni Naijiria.

"Koda, gbogbo ọmọ Naijiria to ba ni kaanu ọmọdebinrin naa ni ko fọn soju popo fun iwọde wọọrọwọ lati ja fun ki wọn fi ọwọ ofin mu awọn to lọwọ si aṣemaẹ yii.

Àkọlé fídíò, 'Wọ́n fipá bá mi lòpọ̀ toyúntoyún títí tí mo pàdánú ọmọ náà, wọ́n jù mi sílẹ̀ níhòhò'