Senior Advocate of Nonsense: Eedris Abdulkareem ṣe àwo orin tuntun fún Festus Keyamo

Eedris Abdulkareem ati Festus Keyamo

Oríṣun àwòrán, Eedris abdulkareem/others

Lẹyin ọjọ diẹ ti gbajugbaja olorin Eedris Abdulkareem gbe awo orin tuntun gẹgẹ bi atunkọ orin to pe akọle rẹ ni Jagajaga, nibi to ti sọ nipa kudiẹ kudiẹ to n jẹyọ lawujọ, ti minisita to n ri si eto igbanisiṣẹ Festus Keyamo si fesi le lori loju opo Twitter lati sọ pe, o fẹ ba ijoba lorukọ jẹ ni. Nigba to n fesi, Keyamo sọ pe olorin naa n gbiyanju lati ba ijọba l'orukọ jẹ ni ti o si tun fi idi rẹ mulẹ pe Eedris Abdulkareem ti wa bẹ oun lati darapọ mọ igbimọ ipolongo Buhari lọdun 2018.

Iyabo Ojo àti Foluke Daramola tako ara wọn lórí ọ̀rọ̀ Baba Ijesha Lati fi idi ọrọ naa mulẹ, Keyamo fi gbogbo itakurọsọ lori ẹrọ ilewọ wọn sita loju opo Twitter.

O fi kun pe Abdulkereem bẹ oun lati mu u mọ minisita eto irinna, Rotimi Amaechi ati akọwe ijọba Boss Mustapha, to fi mọ agbejọro ijọba Naijiria Abubakar Malami.

Lẹyin eyi ni Abdulkareem sọ loju opo instagram rẹ pe lootọ ni oun ke si Keyamo nigba ti ara iya oun ko ya nitori oun ro pe ẹbi oun ni Keyamo.

O dabi ẹni pe eyi ko tẹ akọrin naa lọrun lo fi tun pada lọ se awo orin fun Keyamo to pe akọle rẹ ni Jagajaga Ti Get E fun Keyamo to jẹ amofin agba Naijiria.

Ni ibẹrẹ orin naa ni Abdulkareem ti kọ pe "Keyamo, o gba ipo ni ọdun 2018.

"Mo ro pe akẹgbẹ kan naa ni wa, mo lero pe iyatọ yoo wa ninu iṣejọba rẹ nitori naa ni mo se kọ orin 'Obasanjo Write Buhari Letter' lati ran o lọwọ ninu nkan ti o n ṣe.

"Lootọ ni ọpọ lo fẹran Buhari ti wọn si gbaruku tii, sugbọn a kaba mọ rẹ."

Ni ipele akọkọ orin naa ni Abdulkareem ti kọ pe, "Keyamo ijoba rẹ kun fun abosi.

Ko si ifọkanbalẹ lorile-ede yii mọ, wọn n ji awọn ọmọ gbe nile iwe wọn, ẹjẹ n san lawọn igberiko, iwa alakatakiti lo kun inu ijọba, abi o fẹ faṣọ bo ọrọ Pantami pe ko niṣe pẹlu awọn agbesumọmi?" Eyi si lo mu ki Senior Advocate of Nonsense maa tan ka loju opo Twitter ti ọpọ awọn ọmọ Naijiria si n sọ ero okan wọn.

Diẹ lara nkan ti wọn sọ ree.