Olusegun Obasanjo: Nàìjíríà yóò ṣẹ́gun ìpèníjà àbò tó mẹ́hẹ láìpẹ́

Mí o gbọ́ pé àwọn ènìyàn ń pari ìpinya orílẹ̀-èdè Nàìjíríà- Olusegun Obasanjo

Oríṣun àwòrán, Obasanjo

Aarẹ nigbakanri lorilẹede Naijiria, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ ti fi da awọn ọmọ Naijiria loju pe, gbọnmọ-gbọnmọ abo to mẹhẹ bayii yoo di itan laipẹ.

Ọbasanjọ ṣalaye pe ẹpọn agbo ni ọrọ Naijiria ati ipenija abo to n koju rẹ lọwọ bayii; O ni mimi lo n mi, ko le jabọ.

O ni bo pẹ bo ya imọlẹ yoo tan, ti idẹrun yoo si de pẹlu gbogbo itajẹsilẹ to n waye yii.

Oloye Ọbasanjọ ni digbi ni igbagbọ oun duro pe orilẹede Naijiria yoo ṣẹgun ipenija abo to mẹhẹ to n ba a finra lọwọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nibi eto ifẹyinti fun Biṣọbu agba ijọ onitẹbọmi lorilẹede Naijiria, Nigeria Baptist Convention, Ẹniọwọ Samuel Ayọkunle lagba oṣelu naa ti sọ eyi.

Oloye Olusẹgun Obasanjo ni bopẹ boya, orilẹede Naijiria yoo bori awọn iṣoro rẹ gbogbo.

Aarẹ Naijiria nigbakanri naa wa fi kun pe igbagbọ oun ko figbakan yẹ ninu orilẹede, oun si yi ri oye pe ohun gbogbo to le koko bayii m bọ wa dẹrọ laipẹ.

Amin iyasọtọ kan

N kò gbọ́ rárá pé àwọn ènìyàn kan ń pariwo fún ìpinya Nàìjíríà - Obasanjo

Olusegun Obasanjo

Oríṣun àwòrán, Obasanjo

Ààrẹ tẹ́lẹ̀ ní Nàìjíríà, Olusegun Obasanjo sọ pé òun kò ri gbọ́ pé àwọn ènìyàn kán kígbe pé àwọn fẹ́ ìpinyà orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn IPOB àti àwọn tó n bèèrè fún orílẹ̀-èdè Oduduwa wà lára àwọn tó n pè fún ìpinyà Nàìjíríà, sùgbọ́n ààrẹ àná ní òun kò mọ̀.

Lásìkò tó n ṣe ìfọ̀rọ̀wérọ̀ pẹ̀lú àwọn oníròyìn ní Sokoto, ni Obasanjo ti dáhùn ìbèérè tí akọròyìn kan bi i láti sọ sí ọ̀rọ̀ ìpinyà ti àwọn ọmọ Nàìjíríà kan ń pè fún.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nínú ìdáhùn rẹ̀, ààrẹ àná ní " ìpinyà? mí o gbọ́ ǹkankan nípa ìpínyà tàbí pé àwọn kán ń pè fún un ni Nàìjíríà."

Obasanjo ti rìnrìnajo lọ sí Sokoto láti ọjọ́ Satide, níbi to tí lọ ṣe ìfilọlẹ̀ afárá olókè towo rẹ tó bílíọ̀nù mẹ́ta àti mílíọ̀nù lọ́nà irinwó nàìrà, tó sì tún sàbẹ̀wò sí àwọn iṣẹ́ àkànṣe mííràn ní ìpínlẹ̀ náà.