Florence Ajimobi: Ohun tí n kò lérò ni mo bá lẹ́yìn tí a kúrò ní ìjọba - Florence Ajimobi

Abiola Ajimobi ati aya rẹ, Florence

Oríṣun àwòrán, florenceajimobi/Instagram

Aya gomina ipinlẹ Oyo tẹlẹ ri, Florence Ajimobi ti salaye pe idakeji ohun ti oun ko gbaradi fun lati koju loun ba pade, lẹyin ti oun ati ọkọ oun kuro ni ijọba tan.

Arabinrin Ajimobi sọrọ yii nibi iṣinu awẹ pẹlu awọn alaṣẹ ẹgbẹ akọroyin, NUJ ati NAWOJ nipinlẹ Oyo, eyi to waye nile rẹ niluu Ibadan.

Aya Ajimobi ni oun ti gbaradi ni kete tawọn kuro lori aga aleefa, lati ni iriri ikorira ati iwa ọdalẹ lati ọdọ awọn eeyan.

Ṣugbọn aya gomina ana ipinlẹ Oyo sọ pe, n ṣe lawọn eeyan n gbe oun gẹgẹ, ti wọn si n fi ifẹ han si oun nibi kibi ti oun ba lọ, lẹyin ti awọn kuro nipo tan.

"Awọn eeyan n fi ifẹ han si mi, eleyi to ya mi lẹnu, mo dupẹ lọwọ Ọlọrun fun eyi.

Florence Ajimobi

Oríṣun àwòrán, florenceajimobi/Instagram

N ṣe lọpọlọpọ eeyan duro gidigba lẹyin mi, n ko pe gẹgẹ bii eeyan nitori mo maa n ṣe aṣiṣe.

O ṣeeṣe ki n ti ṣe aṣiṣe nigba ti mo fi jẹ aya gomina ipinlẹ Oyo, sugbọn mo fẹ ki ẹ mọ pe n ko mọọ mọ ṣe awọn aṣiṣe ti mo ba ti ṣe nigba naa.

Ati pe ko si ẹni to pe nitori eeyan ni gbogbo wa," Ajimobi lo sọ bẹẹ.

Mo nífẹ̀ẹ́ ọkọ mi si lẹ́yìn ikú rẹ̀ ju ìgbà ayé rẹ̀ lọ

Nigba to n sọ nipa ọkọ rẹ to di oloogbe ni bii oṣu mẹwa sẹyin, aya Ajimobi ni oun tun wa nífẹẹ Abiola Ajimobi si lẹyin to ti ku, ju igba aye rẹ lọ.

O ni oun ko mọ iyi ọpọlọpọ ohun ti Ajimobi n ṣe gẹgẹbi olori ile nigba aye rẹ amọ asiko yii gan an loun ṣẹṣẹ mọ riri gbogbo ohun ti to n ṣe nigba aye rẹ.

Àkọlé fídíò, aaaaaaaaaaaaaaa

"Mo si máa n sọ fawọn ọmọ mi pe akinkanju ọkunrin ni baba wọn.

Ko tii pe ọdun kan ti Iku mu ọkọ mi lọ, ṣugbọn n ṣe ni mo n ṣafẹri rẹ ni gbogbo igba.

Mo n sọ nipa ẹni ti mo ba gbe fun ogoji ọdun, ti ko figba kan ṣaroye ri. Mi o gbọ ko ṣe aroye ri,'' aya gomina ipinlẹ Oyo tẹlẹ ṣalaye.

O ni Ajimobi n gbe gbogbo ẹru idile awọn lai ṣaroye fun ẹnikan.

Aya Ajimobi ni ko rọrun lati jẹ ọmọkunrin ni tootọọ. "Ti mo ba tun ayé wa, mo si maa fẹ lati wa ni obinrin lẹẹkan sii.

Àkọlé fídíò, Budo Ikoko water problem: Ìyàwó wa ti sá lọ kúrò ní Asa nítorí àìsí omi- Alhaji Sunmonu

Mo si tun maa fẹ lati jẹ aya Ajimobi ni iye igba ti a ba jọ pada wa si ayé nitori kò sí ọkunrin bii Ajimobi.

Oninu rere ni Ajimobi, olootọọ eeyan si ni, n ko le gbagbe rẹ laelae," aya gomina ipinlẹ Oyo tẹlẹ lo sọ bẹẹ.