Mary Daniel: Ìjọba Eko ní ẹbi obìnrin náà ni àwọn fàá lé lọ́wọ́, tí wọn kò sì gbẹ́sẹ̀ lé N25m owó ìranwọ́ rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Lagos State Government
Ijọba ipinlẹ Eko ti kede pe irọ to jinna sootọ ni iroyin kan to gba ori ayelujara kan pe wọn ti fa Mary Daniel, obinrin ẹlẹsẹ kan to n ta omi loju popo, le ọlọpaa lọwọ.
Ni irọlẹ Ọjọru ni iroyin kan gbalẹ pe obinrin ẹlẹsẹ kan naa, tawọn eeyan seto ikowojọ fun laipẹ yii, tijọba Eko si siju aanu wo, ni irọ wa ninu ọrọ rẹ, ti wọn si ti fa le ọlọpaa lọwọ.
Iroyin naa ni Mary pa irọ pe oun ko ni baba ati iya laye, ti wọn si ti jalaisi ninu ijamba ọkọ ti ẹsẹ rẹ ti da amọ ti wọn sawari rẹ pe baba rẹ wa laye.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Obìnrin ẹlẹ́sẹ̀ kan tó ń kirí omi rí àánú gbà lọ́wọ́ ìjọba Eko
- Yekeen Ajileye, ọ̀gá mi nínú iṣẹ́ tíátà ṣẹ̀ mí, ó ṣẹ ẹlẹ́dàá mi - Abija
- Olórùka ti gba òrùka, n kò sí lórí àtẹ mọ́, ẹ má sanwó láti fẹ́ mi - Oluwo figbeta
- To bá ń gbé l‘Eko, wo ohun tó ṣe láti bọ́ lọ́wọ́ olè àti ọ̀daràn - Amẹ́ríkà
- Gbogbo abiyamọ aye ẹ gba wá, wọ́n ti fẹ́ tú Baba Ijesha silẹ - Iyabo Ojo figbe ta
- Mo nífẹ̀ẹ́ ọkọ mi si lẹ́yìn ikú rẹ̀ ju ojú ayé rẹ̀ lọ - Florence Ajimobi
- Nǹkán yan, wọ́n ń ṣe ìkówójọ fún Olorì Damilola láti fi gba ilé l‘Eko
- Ìwàásù Baba Adeboye ló sọ mí di Kristẹni - Funke Etti
- Wo oore tí Ramadan n ṣe fún àwọn ẹlẹ́sìn mìíràn tó n gbà á
- Ìdí tí mo fi bú sẹ́kún nílé aṣòfin àgbà rèé - Smart Adeyemi
Bakan naa ni ahesọ iroyin naa ni kii se inu ijamba ọkọ ni ẹsẹ Mary ti ge bikose pe wọn bi mọ bẹẹ ni lati igba to ti de ile aye.
Wọn tun ni awọn eeyan kan to seranwọ fun Mary lati gbe ọrọ rẹ de ori ayelujara ti n dunkooko mọ pe awọn fk gba ipin awọn ninu miliọnu mẹẹdọgbọn naira ti awọn alaanu ko jọ fun bii owo iranwọ.

Oríṣun àwòrán, Screen Shot
Ọna lati fi idi ootọ ọrọ mulẹ lo mu ki BBC Yoruba pe ijọba ipinlẹ Eko lati mọ boya lootọ ni awọn ahesọ ọrọ to n lọ lori ayelujara naa.
Nigba to n tako awọn ahesọ iroyin yii, Kọmisana feto iroyin nipinlẹ Eko, Ọgbẹni Gbenga Omotoso salaye pe ko si ootọ kankan ninu iroyin to n lọ lori ayelujara nipa obinrin naa.
Omotoso ni ijọba Eko tẹwọgba Mary ni ọjọ Kẹtala osu Kẹrin ọdun 2021 lasiko ti ariwo rẹ gba ori ayelujara, ti awọn eeyan si ti ko miliọnu mẹtala naira jọ fun bii owo iranwọ.
O ni lọwọ lọwọ bayii, owo tawọn eeyan fi se Mary laanu ti le ni miliọnu mẹẹdọgbọn naira lasiko to de ọdọ ijọba ipinlẹ Eko.
"Ijọba Eko gba itọju Mary, ta si ri pe aabo to peye wa fun.Ni Ọjọru la wa gbe igbimọ kan kalẹ ninu eyi ti awọn ọlọpaa wa pẹlu ileesẹ to n seto idẹrun araalu.

Oríṣun àwòrán, Lagos State Government
Bakan naa la pe ẹgbẹ awọn ọmọ bibi ẹya Igala to n gbe nilu Eko, nibi ti Mary ti wa, ta si fa obinrin ẹlẹsẹ kan naa le wọn lọwọ fun itọju.
A ko fẹ ki obinrin naa bọ sọwọ awọn gbajuẹ to le fẹ gba owo to ri kojọ lọwọ rẹ ni a se gbe igbesẹ yii."
Kọmisana feto iroyin nipinlẹ Eko fikun pe, wọn ti pasẹ fun awọn ẹya Igala naa lati ri daju pe wọn lo owo ọhun lati gba ilegbe fun obinrin ẹlẹsẹ kan naa.
Bakan naa ni Ijọba Eko tun pasẹ pe ki wọn si tun si ibudo itaja igbalode ti Mary nifẹ lati si fun gẹgẹ bii okoowo to fẹ dawọle ati isẹ oojọ.
"A tun sọ fun awọn araalu obinrin naa pe ilu Eko la fẹ ki Mary maa gbe, ko si dokowo si nitori ilu Eko lo ti ri gbogbo owo to ri kojọ naa.
Eyi si fidi rẹ mulẹ pe Eko jẹ ibi ti eeyan ti n se oriire nitori pe o tun jẹ ilu to ko tonile talejo mọra."
Ijọba Eko wa kede pe Mary Daniels ko si ni agọ ọlọpaa fun iwadi kankan tabi pe asiri tu pe o parọ, bẹẹ ni wọn ko maa sewadi rẹ nitori pe baba rẹ wa nile aye.
Bawo ni itan Mary Daniel se jẹ losu diẹ sẹyin:
Bẹẹ ba gbagbe, laipẹ yii ni ori ayelujara kun fun iroyin obinrin naa, ti ọpọ eeyan si n da owo jọ fun lati saanu rẹ.
Arabinrin to ge lẹsẹ naa ṣalaye, nigba t'awọn oniroyin n f'ọrọ waa lẹnu wo nigba ti iroyin rẹ jade pe, salaye pe inu ijamba mọto to gbẹmi gbogbo awọn ero inu ọkọ naa, loun ti padanu ẹsẹ oun kan.
O ni inu ijamba mọto yii kan naa lawọn obi oun mejeji ku si.
Nigba ti fọto rẹ nibi to ti n kiri omi pure water ni Osodi nilu Eko, bọ sigboro aye lọsẹ diẹ sẹyin, ọpọlọpọ ẹlẹyinju aanu ni Naijiria ati loke okun ni wọn dide iranwọ fun.
O ṣalaye ninu iforowerọ kan pe ọmọ orukan loun ati pe oun loun n da gbe bukata ọmọ kan ti oun bi ati iya agba oun.
O tun figbakan mu ẹnu le iroyin nipa bi nnkan ṣe le koko fun oun, to fi di wi pe oun ni lati fi ileewe silẹ bọ si igboro lati ta omi inu ike, ki oun ati ọmọ pẹlu iya agba oun lee jẹun.
Laipẹ yii si ni wọn ṣe ẹyẹ ọjọ ibi fun arabinrin naa pẹlu oniruru aworan, akara oyinbo ati bẹẹ bẹẹ lọ.














